Oko oloyun: Àwọn agbébọn pa gbajúgbajà apòògùn ìbílẹ̀, Àláájì Fàtáì ọkọ olóyún

Oríṣun àwòrán, others
Gbajugbaja, oniṣegun ibilẹ, Alhaji Fatai Yusuf ti ọpọ mọ si ọkọ oloyun lawọn eeyan kan yinbọn pa ni irọlẹ Ọjọbọ ni ipinlẹ Ọyọ.
Gẹgẹbi iroyin ṣe sọ, opopona Eruwa si Igboọra lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Ọyọ.
- Iná ńla sọ ní ọjà pákó Mushin Amu l'Eko! Lọ́wọ́lọ́wọ́ kò tíì sí àbáyọ
- Yaba Left: Àṣírí tú! #7000 sí #10000 ni owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún bẹẹdi ní ilé àwọn aláìsàn ọpọlọ
- Ó kéré tán ọkùnrin 15 ló ń bá mi lòpọ̀ lójúmọ́, mo sì ti ní egbò lójú ara - Adeola tí wọn fi sòwò ẹrú
- Mo kàn fẹ́ fi ọmọ tó sọnù gba owó lọ́wọ́ Sọtitobire ni - Afurasí
- Ẹ̀yin obìnrin tẹ́ẹ fẹ́ wá bímọ ní America, ọ̀nà ti tì pa látònì! - Trump
- Ṣé Coronavirus leè tẹ̀lé ọjà Chinco wọ Nàìjíríà? Ìdáhún àtàwọn ìbéèrè míì
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Gbenga Fadeyi to fi idi rẹ mulẹ fun BBC news Yoruba ṣalaye pe lootọ ni awọn aṣekupani pa Alhaji Fatai Ọkọ Oloyun ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori rẹ.
'Aṣẹ ti wa lati ọdọ kọmiṣọna ọlọpaa pe ki ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa, SCID bẹrẹ iwadi lori rẹ lati mọ bi iku rẹ ṣe jẹ'.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko tii lee sọ ni pato boya igbenipa ni iku rẹ ni abi nnkan miran. Ayafi nigba ti wọn ba pari iwadii.
Gbajugbaja oniṣegun ibilẹ ni Alhaji Fatai Ọkọoloyun ti o jẹ ilu mọọka pẹlu awọn ọkan-o-jọkan ogun ibilẹ rẹ eleyi ti o gbajugbja.
Alahaji ọkọ oloyun wa lara awọn eekan to mu iṣegun ibilẹ tọ ọna igbalode lọ nipa ṣiṣe ogun ibilẹ si igo gẹgẹ bii olomi ati ni koro bi awọn ogun oyinbo.
Titi di bi a ṣe n sọrọ yii ko tii si ẹni lee sọ bi iku rẹ ṣe jẹ.















