Ondo Kidnap: Afurasí ní òun kàn fẹ́ fi ọmọ tó sọnù gba owó lọ́wọ́ Sọtitobire

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ ti ni ki ọkùnrin kan, Chibuzor Eleke tí ó sọ wí pé ọwọ òun ni ọmọ tí wọn jì gbé ní ilé ìjọsìn Sotitobire ni ilu Àkúré.
Wọn ni ko wa lọ ṣere ni ọgba ẹwọn titi di Ọjọ Kọkanlelogun, Osu Keji, ọdun 2020.
Eyi ko sẹyin bi ọwọ àwọn olopaa ti tẹ afurasii yii tí wọn sì ti gbé lọ sí ilé ẹjọ́ lónìí.
Nígbà tí o ń ṣàlàyé fún ikọ asoju BBC News Yoruba, Alukoro àjọ Olopaa, Femi Joseph, sọ wí pé, ìlú Portharcourt ni ọwọ tí tẹ Chibuzor nígbà tí ò n bèèrè fún owó tí ó tó ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800k) lọ́wọ́ òbí ọmọ náà.
Bakan naa lo tún fi atejise ranse sì Oga Olopaa kan naa pe, lai si owo, ọmọ náà kò ní jáde.
Agbẹjọrọ afurasii naa, Isaac Adubazi sọ pe ọkunrin naa kan n wa atije ni ati ọna lati gba ọwọ lọwọ iyawo Sọtitobire ki ọwọ palaba rẹ to segi.
O fikun un wi pe ọsẹ to kọja naa ni wọn mu afurasi miran ti awọn mejeeji jẹ ọrẹ, ti oun naa sọ wi pe ọmọ naa wa ni ọwọ oun ki ọlọpaa to gba a mu ni ilu Port Harcourt.Báyìí, Adajo Mayomi Olanipekun ilé ẹjọ́ Magiisirate Kẹta kọ lati gba beeli rẹ, tí o si ni kí o sì lọ ṣeré lọgba ẹ̀wọ̀n fún ìgbà díè.
Ti a ko ba gbagbe, Arabinrin Olawole to jẹ́ iyá Gold Kolawole lo gbe ọmọ rẹ̀ lọ si sọọsi awọn ọmọde nile ijọsin wọn lẹ́yin ọ̀pọ̀lọpọ ọ̀rọ̀ latọdọ àwọn olukọ ọmọde ninu ijọ náà pe ki iya Gold maa gbé ọmọ rẹ̀ wá si ilé ijọsin ọmọ wẹwẹ.
Lẹ́yin ti o pada lọ si ilé ijọsin láti lọ wo ọmọ rẹ̀ ló ri i pé ọmọ náà ko si nibẹ̀ mọ.
Gẹ́gẹ́ bí ìyá ọmọ náà ṣe sọ, nígba ti ọmọ sọnú, o ni oludásìlẹ̀ ijọ náà Alufa Babatunde rọ àwọn láti lọ sinmi silé ki wọn si ma fi ọ̀rọ̀ náà lọ ọlọpàá.
Lẹ́yìn gbogbo ìgbìyànju ti ọmọ náà kò si jẹ́ rírí, Arabinrin Kolawole ni olùdásilẹ̀ ijọ náà ko gbe igbésẹ̀ kan to ṣe koko, èyí ló fàá ti òun fi ke gbajare sita ti Deji Akure si fi pa a láṣẹ̀ pé ki awọn wa bura.
Arabinrin Modupe Kolawole ni àwọn aṣọna to wa lẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ náà àti igbakeji oludari lo lọ sibẹ ṣùgbọ́n oludasilẹ ijọ ko dasi ọ̀rọ̀ náà.















