Isabel dos Santos: Obìnrin tó lówó jùlọ ní Africa 'ja orílẹ̀-èdè rẹ̀, Angola lólè' fi kó ọ̀rọ̀ jọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, BBC Panorama
- Role, Team
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Awọn iwe akọsilẹ kan ti aṣiri rẹ tu sita ti ṣafihan bi obinrin to l'owo julọ nilẹ Africa ṣe ko ọ̀rọ̀ rẹ jọ nipa lilo orilẹ-ede rẹ fun anfaani ara tiẹ, ati nipa iwa ibajẹ.
Isabel dos Santos anfaani si awọn idokowo to jọ oju nigbese bi i ilẹ, eporbi, okuta iyebiye(diamond) ati eto ibaraẹni sọrọ, lasiko ti baba rẹ fi jẹ aarẹ Angola. Orilẹ-ede Angola wa ni Gusu ilẹ Africa, o si kun fun awọn nkan alumọọni.
Awọn iwe akọsilẹ naa fi bi wọn ṣe fi aaye gba oun ati ọkọ rẹ lati ra awọn dukia ijọba to jẹ olowo iyebiye l'ọnna to mu ifurasi dani.
Arabinrin Dos Santos sọ pe irọ patapata ni awọn ẹsun ti wọn fi kan oun, ati wi pe ọtẹ oṣelu ti ijọba orilẹ-ede Angola n ṣe ni.
Orilẹ-ede UK ni ọmọ aarẹ nigba kan ri ọhun n gbe, to si ni ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye ni aarin gbungun ilu London.
Lọwọlọwọ, awọn alaṣẹ orilẹ-ede Angola ti n wadii rẹ fun iwa ibajẹ, wọn si ti gbẹsẹ le awọn dukia rẹ to wa ni orilẹ-ede naa.
Ọpọ awọn iwe naa ni ajọ to n daabo bo awọn to n tani lolobo ni Africa; Platform to Protect Whistle-blowers in Africa.
Wọn si ṣe ajọpin awọn iwe naa pẹlu ẹgbẹ awọn akọroyin to n ṣewadi abẹnu l'agbaye.


Okoowo eporọbi
Ọkan lara awọn okoowo to ṣe to mu ifurasi dani ni ti epo to ṣe nipasẹ ẹka ileeṣẹ eporọbi orilẹ-ede Angola, Sonangol.
Arabinrin Dos Santos ni wọn fi jẹ alamojuto ileeṣẹ Sonangol l'ọdun 2016, ni aṣẹ baba rẹ, Jose Eduardo dos Santos, to lo ọdun mejidinlogoji nipo aarẹ.
Ṣugbọn ẹni to gba ipo aarẹ lẹyin ti baba rẹ fẹhinti lọdun 2017 yọ Arabinrin Dos Santos kuro ni ipo naa.
Awọn iwe akọsilẹ aṣiri wọn tu sita fihan pe bi Santos ṣe n fi ipo naa silẹ, lo buwọlu sisan miliọnu mejidinlọgọta Dọla ($58m) fun ileeṣẹ ọrọ rẹ kan nilu Dubai, Matter Business Solutions.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ Matter ṣe awọn akanṣe iṣẹ kan fun Sonangol, ko fi bẹ si akọsilẹ pe o yẹ ki o gba to owo ti wọn buwọlu fun un.
Awọn agbẹjọro Dos Santos sọ pe gbogbo owo ti wọn san fun ileeṣẹ Matter lo ba ofin mu, ati pe kii ṣe igba ti wọn le e kuro nipo lo buwọlu u.

Okoowo okuta iyebiye 'diamond'
Ọkọ Arabinrin Dos Santos, Sindika Dokolo, fi ọwọ si iwe adehun ẹlẹnikan ni ọdun 2012 pẹlu ileeṣẹ orilẹ-ede Angola, Sodiam, to n pese 'diamond'.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O yẹ ki ọkọ rẹ ati ileeṣẹ naa o pin owo idokoowo ti wọn ṣe ni ileeṣẹ to n ṣe ẹṣọ ara ni Switzerland, De Grisogono dọgba-dọgba ni, ṣugbọn, ileeṣẹ ijọba lo ko owo to pọju silẹ.
Iwe akọsilẹ naa si fihan pe niṣe ni Sodiam ya gbogbo owo to lo ni banki aladani kan, ti Arabinrin Dos Santos ti jẹ oludokowo to tobi julọ.
Bravo da Rosa, to jẹ ọga agba tuntun fun Sodiam sọ fun Panorama pe awọn eniyan Angola ko ri owo kankan botiwu ko kere mọ lara okoowo naa.
"Nigba ti ao ba fi san gbese naa tan, Sodiam yoo padanu owo to le ni igba miliọnu Dọla ($200m).

Okoowo ilẹ
Aṣiri tun tu pe Arabinrin Dos Santos ra ilẹ kan to wa ni eti okun Luanda l'oṣu Kẹsan, ọdun 2017, o si san asansilẹ owo kekere.
Ọpọlọpọ awọn eniyan lo si di alainilelori nigba ti wọn le wọn kuro lori ilẹ naa ti wsn fẹ ẹ fi kọ ilu tuntun Futungo.
Yatọ si eyi, mọlẹbi bi ẹẹdẹgbẹta ni wọn tun le kuro nibi ti ilẹ naa ṣan de lẹyin ti Dos Santos tun bẹrẹ iṣẹ miran.
Ni bayii, 'tosi ibi ti wọn n da igbẹ si ni awọn mọlẹbi naa n gbe, ti igbẹ si maa n ṣan wọ ile wọn ti riru okun ba pọ.

Okoowo l'ẹka ibaraẹnisọrọ
Obinrin olowo tabua yii tun jẹ eere pupọ ni ẹka ibaraẹnisọrọ ni Angola.
Ìdá mẹẹdọgbọn ni ìpín rẹ ni ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ alagbeka to tobi ju ni Angola, Unitel.
O tilẹ lo anfaani naa lati mu ki Unitel o ya ileeṣẹ tuntun kan to da silẹ ni ọtalelọọdunrun miliọnu Pọhun, yatọ si biliọnu kan Dọla ti ileeṣẹ naa ti san fun un.
Orukọ ileeṣẹ naa, Unitel International Holdings, mu ifurasi dani, nitori pe ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu Unitel, Arabinrin Dos Santos lo si ni i.
Awọn iwe akọsilẹ naa fihan bi Ms Dos Santos ṣe buwọlu iwe owo yiya gẹgẹ bi ẹni to yawo, ati ẹni to ya wọn ni owo, ti ko si yẹ ko ri bẹ ẹ.
Arabinrin Dos Santos ati awọn agbẹjọro rẹ sọ pe gbogbo awọn to yẹ ko fi ọwọ si owo yiya naa lo mọ si i.
Ati pe awọn ya owo naa lati fi daabo bo Unitel lọwọ bi owo ṣe n ṣe ṣege-ṣege.

Who is Isabel dos Santos?
- Santos Oun ni ọmọbinrin agba fun aarẹ tẹlẹ ni Angola, Jose Eduarso dos Santos
- Ọkọ rẹ, Sindika Dokolo jẹ ọmọ orilẹ-ede Congo, o si jẹ oniṣowo
- Educated in UK, where she currently lives Orilẹ-ede UK lo ti kawe, ibẹ naa si lo n gbe lọwọlọwọ
- Oun ni iroyin sọ pe o jẹ obinrin to lowo julọ ni ilẹ Africa pẹlu biliọnu meji Dọla
- O ni ipin idokowo ni ẹka eporọbi, banki, ati awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ, pupọ eyi to wa ni Angola ati Portugal.
Orisun: Forbes magazine ati awọn miran















