Northern Ireland LGBT: Wọ́n ti buwọ́ lu Ìgbéyàwó ọkùnrin s'ọ́kùnrin, obìnrin s'óbìnrin ní Northern Ireland

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ti sọ igbeyawo ọkunrin si ọkunrin, ati obinrin si obinrin di nkan ti ofin ni orilẹ-ede Northern Ireland fi aaye gba.
Lati ọjọ Aje, ọkunrin atọkunrin, obinrin atobinrin to n fẹ ara wọn yoo le fi orukọ silẹ fun igbeyawo, eyi to tumọ si pe eto igbeyawo akọkọ yo waye l'oṣu Keji, ni ọsẹ ayajọ ololufẹ.
Fun awọn to ti ṣe igbeyawo larin ara wọn, igbeyawo wọn ti di nkan ti ofin fi ọwọ si bayii ni Northern Ireland.
Ṣugbọn ṣa, awọn to ti kọkọ fi orukọ silẹ gẹgẹ bi ololufẹ lasan lai si igbeyawo ko ni i le yii pada si igbeyawo labẹ ofin.
- Harry àti Meghan kò ní lo orúkọ oyè wọn mọ́, wọn kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí owó ilú mọ́ ní UK
- Kínla! Ṣé olùkọ́ fásitì OAU míràn tún ti kó sí gbaga ìbálòpọ̀-fún-máàkì ni?
- Òyìnbó ẹni ọdún 46 wá ṣe mọ̀'mí n mọ̀ ọ́ ní Kano pẹ̀lú Isah olólùfẹ́ rẹ̀
- Ààfá mẹ́ta réwọ̀n hé nípa ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ òjijì fún obìnrin kan pẹ́lù 36 mílíọ̀nù náìrà
Aṣofin to fi ọwọ si atunṣe ofin ọhun, Ọgbẹni Conor McGinn sọ fun BBC News Northern Ireland pe "gbogbo ẹni to ba mọ riri igbeaye to dọgba, ifẹ ati bibọwọ fun'ra ẹni ni yoo ṣajọyọ loni".
Aṣofin: "Ọjọ to dara ni fun orilẹ-ede Northern Ireland, ọjọ to ṣe pataki ni fun ẹtọ awọn araalu jakejado erekusu yii,
Ati ọjọ idunnu fun awọn to n rinrinajo ifẹ pẹlu eniyan bii ti wọn, nitori pe wọn le fi orukọ silẹ bayii fun igbeyawo."

Oríṣun àwòrán, HOLLY AND LIME PHOTOGRAPHY
Bakan naa ni Patrick Corrigan, ti ajọ Amnesty International sọ pe "ọjọ manigbagbe ni fun igbeaye to dọgba ati ẹtọ ọmọniyan ni Northern Ireland"
Ọdun 2014 ni wọn ti faaye gba iru igbeyawo yii ni England, Scotland ati Wales, ṣugbọn Stormont ko fi aaye gba wọn.
Ileeṣẹ ijọba to n mojuto igbeyawo ni Nothern Ireland si ti ṣetan lati bẹrẹ iwadii ati ijroro lori ojuṣe awọn ileejọsin ninu igbeyawo naa.
















