ECO Currency: Orílẹ̀èdè mẹ́fà bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ Ivory Coast

Oríṣun àwòrán, AFP
Orilẹede Naijira atawọn orilẹede marun un mii ti wọn jọ wa labẹ ajọ ọrẹdẹgbẹ ECOWAS ti bu ẹnu atẹ lu bi orilẹede Ivory Coast ṣe gbe igbesẹ lati yi orukọ owo ilẹ wọn lati CFA si eco.
Gẹg bi ileeṣẹ iroyin AFP ṣe jabọ, Eco yii gẹlẹ ni orukọ tuntun ti ajọ ECOWAS yan lọdun to kọja ti wọn ṣe ilana eto silẹ lati da owo kan ṣoṣo silẹ fun awọn orilẹede to wa ni ajọ naa ti wọn si gbero lati pe e ni "eco".
Lẹyin ipade awọn orilẹede ẹkun Iwọ Oorun Afirika fun eto isuna kan naa - Naijiria, Guinea, Sierra Leone, Ghana, Liberia ati Gambia to waye lọjọbọ sọ pe ko yẹ ki orilẹede Ivory Coast gbe igbesẹ naa.
Ipade yii waye laarin wọn ati awọn Minisita eto isuna, awn gomina ile ifowopamọ giga ju lọ lẹkun Iwọ Oorun Afirika.
Wọn ti wa pe fun ipade pataki laarin awọn adari orilẹede ẹkun Iwọ Oorun Afirika mẹẹdogun lati jokoo fọrọ jomi toro ọrọ naa.
Siṣe ayipada owo CFA franc ko wa "ni ibamu pẹlu ipinu awọn alaṣẹ ijọba ajọ ECOWAS lati yan eco fun orukọ owo kan ṣoṣo", ileeṣẹ iroyin Bloomberg ni ohun ti awọn orilẹede naa sọ niyii.
Lọwọlọwọ, orilẹede mẹjọ lẹkun Iwọ Oorun Afirika ati Aarin gbungbun Afirika ti ọpọlọpọ wọn gbominira kuro lọwọ ilẹ Faranse lo n lo owo CFA Franc.
Wọn si ti n bu ẹnu atẹ lu owo naa tipẹ pe owo aye atijọ ti igba ijọba amunisin ni CFA. Nitori naa loṣu to kọja, aarẹ Ivory Coast Alassane Ouattara kede pe wọn yoo yi orukọ owo CFA Franc si "eco" ti wọn yoo si maa na a mọ euro.
Pẹlu igbesẹ ti ajọ ECOWAS naa ti baba gbe lori owona kan naa ti orukọ rẹ tun n jẹ "eco", bi ko ba si iforikori, eyi yoo da nkan mii silẹ o.
Lẹgbẹ kan, owo Naira ti wọn maa n foju wo bi eyi to ga ju, ko tii ye daju bayii boya ile ifowopamọ to ga ju lọ lorilẹede Naijira yoo yọnda didari owo naira fun awọn alaṣẹ eto ẹnawo Iwọ Oorun Afirika.













