Naira Marley: Ẹ̀kọ́ rèé fáwọn Marlians tó pa iléẹ̀kọ́ tì, tí wọn ń fa ṣòkòtò sílẹ̀ kiri

Oríṣun àwòrán, NAira Marley/ instagram
Azeez Fasola ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley lo jẹ ilu mọọka olorin taka sufe ti ọpọ eeyan n gbokiki rẹ.
Marley, ẹni ti Twitter kede lọdun 2019 pe oun ni awọn eeyan wadi rẹ julọ, la gbọ pe ọpọ eeyan, paapa awọn ọdọ n fi se awokọse.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀yin gómìnà, ẹ bá wa bi Buhari pé kí ló ń bàá lẹ́rù lórí Amotekun - Aráàlú
- Fasola ló jẹ̀bi ìdákúrekú iná ọba - ọmọ Nàìjíríà fárígá lórí òkùnkùn biribiri
- Sotitobire: Adájọ́ dá Pásítọ̀ Alfa Babatunde padà s'ẹ́wọ̀n fún ọjọ́ mọ́kàndílógún
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ọta ìbọn ogun Biafra ṣì wà lọ́rùn mi lẹ́yìn àádọ́ta ọdún tí ogun parí - Umar
Awọn ọdọ naa, ti wọn maa n hu ọpọ iwa ti Naira Marley n hu, ni kii fa sokoto wọn soke, ti awọn eeyan yoo si maa ri pata ti wọn wọ si abẹ sokoto naa.
Awọn miran ninu wọn si lo ti pa ile iwe ti bayii nitori pe wọn jẹ ololufẹ Naira Marley, ti wọn si ro pe akọrin naa ko ka iwe rara.
Koda, awọn ololufẹ Marley miran maa n mu igbo lati se atilẹyin fun asaaju wọn, ti wọn ni ijọba n gbogun ti pe o n mu igbo lojutaye.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Naira Marley
Sugbọn fun iyalẹnu ọpọ eeyan, akọsilẹ itan igbesi aye Naira Marley fihan pe kii se alakọpati ẹkọ tori pe, o kawe gba oye imọ ijinlẹ ni fasiti, gẹgẹ bi iroyin isalẹ yii ti fihan wa.
Itan igbe aye Naira Marley:
- Azeez Fasola ni orukọ abisọ rẹ, ti wọn si bi si agbegbe Agege nipinlẹ Eko
- Ọdun mọkanla ni Marley wa to fi lọ silu London, to si n gbe ni agbegbe Peckham, to wa ni guusu ilu London
- Ileewe Porlock Hall lo ti bẹrẹ iwe kika, ko to rekọja si ileẹkọ Walworth nibi to ti gba iwe ẹri oniwe mẹwa.
- Lẹyin eyi lo wa tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ nile ẹkọ giga Peckam Academy nibi to ti kẹkọ jade pẹlu oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ nipa ofin to rọ mọ okoowo.
- Ọdun 2014 ni Naira Marley sawari pe oun ni ẹbun fun orin kikọ, to si gbe awo orin akọkọ sita eyi to pe akori rẹ ni "Marry Juana."
- Lẹyin igba naa lo ti gbe ọpọ awọn awo orin sita eyi to to mẹwa niye.
- Marley ni iyawo meji ati ọmọ mẹrin.
Pẹlu awọn igbiyanju Naira Marley lati mu se ohun to yẹ, to si la ipa fun ara rẹ ni idi orin kikọ, ko yẹ ki ọdọ kankan, to ba fẹ fi akọrin naa se awokọse pinnu, lati pa ileewe ti.

Oríṣun àwòrán, NAira Marley/ instagram
Bakan naa lo yẹ ki awọn ọdọ to pe ara wọn ni ololufẹ Naira Marley jawọ ninu awọn iwa kan, eyi to mu ki ọpọ eeyan maa fi oju abuku wo wọn, ki wọn si maa huwa ọmọluwabi ninu iwa, ise ati ọrọ ẹnu wọn.
Okóòwò àgbo tí Toyin Abraham gbé sílẹ̀, Lizzy Anjorin ti bẹ̀rẹ̀ tiẹ̀!

Oríṣun àwòrán, @Toyin_Abraham, @lizzyanjorin_original
Gbajugbaja oṣere Yollywood, Lizzy Anjorin tun ti ṣagbejade ọja rẹ tuntuntun yatọ fun ja aṣọ tita.
Lafikun aṣọ tita, agbo tita loriṣiriṣi ni Lizzy ti ko sori atẹ rẹ loju opo ayelujara bayii ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ si ti n na ika kare si i.
- Lizzy Anjorin: Mi ò bẹ Toyin o! Ẹ̀yin olólùfẹ́ mi àti ẹbí ni mo bẹ̀
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
- Mi ò fẹ́ dá sí ìjà Toyin ati Lizzy! - Madam Saje
- Odunlade fijó bẹ́ẹ, Lizzy padà sọ́dún 2012, Toyin Abraham tọ̀ lẹ́ẹ̀mẹwàá
- Díẹ̀ lára àwọn òṣèré Nollywood ti wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó lẹ́ẹ̀kejì
Ẹwẹ, laipẹ yii ni akẹgbẹ rẹ ninu agbo oṣere kan naa, Toyin Abraham ṣẹṣẹ kede pe oun ti yọ ọwọ ninu ọja agbo tita fun awọn idi kọọkan to ni ṣe pẹlu awọn alajọṣiṣẹ pọ rẹ bo tilẹ jẹ pe o ṣi n ta awọn pẹ pẹ pẹ lẹgbẹ kan.

Oríṣun àwòrán, @Toyin_Abraham

Oríṣun àwòrán, Toyin_abraham
Eyi ko tii to ọsẹ kan rara ti Lizzy Anjorin fi gbe ikede tirẹ sita gẹgẹ bi o ṣe maa n polowo ọja rẹ pẹlu fidio, aworan ati akọle ọja to fi mọ oniruuru agbo to ko le igba.
Lara awọn agbo ibilẹ Yoruba naa to darukọ ni Fodan, Tẹ ẹ kanlẹ, Fọ ọ ko mọ, O n ya bọ, Gbe'dan ro ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, lizzyanjorin_original
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bi ẹ ko ba gbagbe, lọdun to kọja ni ija nla kan bẹ silẹ laarin Lizzy ati Toyin eyi to bẹrẹ latari pe Toyin bimọ, Lizzy kọ lati ki i ku ewu ọmọ tori o ni kii ba oun naa yọ.
Ija yii fẹ loju to bẹẹ ti awọn agbaagba oṣere atawọn ẹlẹgbẹ wọn ni lati da si ọrọ naa ko to di pe o fa nilẹ.
Ko pẹ rẹ ni Toyin Abraham kede pe agbo tita ni ọna owo ti oun yan laayo to si n polowo rẹ lakọ lakọ ṣugbọn ko ju bii o'su













