Fuel Price: Ìjọba ń gbèrò láti máa pèsè gáàsì CNG fún ọkọ̀

Ijọba apapọ n gbero lati sọ jala epo bẹntiro di naira mẹtadinlọgọrun-un lati naira marunlelogoje to wa bayii pẹlu ipese afẹfẹ gaasi CNG tawọn ọkọ yoo maa lo gẹgẹ bi epo.
Minisita keji fun ile iṣẹ epo rọbi, Timipre Sylva to fọrọ yii lede l'Ọjọbọ ṣalaye pe afẹfẹ gaasi CNG le gba ipo bentiro ati disu.
Sylva sọ pe ipese gaasi CNG ko nilo ki ijọba ṣẹṣẹ fi owo sori rẹ bi epo bentiro ki araalu le lagbara lati ra a.
- Òkùnkùn biribiri ní Nàíjíríà bí ẹ̀rọ amúnáwá àpapọ̀ ṣe dẹnukọlẹ̀ lónìí
- Sotitobire: Alfa Babatunde yóò fojú ba iléẹjọ́ lónìí lórí ọmọ tó di àwátì ní ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀
- Wo bí àṣeyọrí iṣẹ́ abẹ ṣe wáyé lórí àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀
- Pásítọ̀ Kérúbù rẹ́wọ̀n he ní UK torí ó fi ‘ìwẹ̀ mímọ́’ bá ọmọdébìnrin mẹ́fà lòpọ̀, ṣẹ́yún fún wọn
- Gbogbo ọba alayé, tó fi mọ́ Ọọ̀ni àná, Sijuwade ló mọ̀ pé mo fẹ́ jẹ Mayegun - Wasiu Ayinde
- Èèyàn mẹ́sàn-án kú nínú ọkọ̀ akérò tó jóná lójú ọ̀nà Ore sí Ijebu Ode
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
O fikun ọrọ rẹ pe ipese afẹfẹ gaasi CNG dinwo ju epo bẹntiro lọ lai fi owo kankan kun un lati apo ijọba.
Minisita o ṣe pataki fun ijọba lati wa nnkan ṣe si owo ribiribi ti ijọba n na lati rii pe awọn ọmọ Naijiria lagbara lati ra epo bẹntiro.
Sylva ṣalaye pe Eleduwa fi afẹfẹ gaasi lọpọ yanturu jinki Naijiria eleyi ti ọpọ rẹ ṣofo danu.
Minisita tun ṣalaye pe o yẹ ki ile aṣofin agba l'Abuja le buwọlu aba lori epo rọbi(PIB) ni Naijiria ko too di oṣu karun un ọdun yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ṣalaye pe ọpọ anfaani lo wa ninu aba naa fun araalu ti o ba di ofin tan.












