Wasiu Ayinde: Èmi àti Aláàfin sọ fún Gani Adams nípa oyè Mayegun, a kò jà rárá
Gbajugbaja olorin fuji, Wasiu Ayinde to ṣẹṣẹ jẹ oye mayegun Ilẹ Yoruba ti sọ fun BBC Yoruba pe, oye naa kii ṣe lati buga, ṣugbọn o jẹ lati tun ilẹ Yoruba ṣe.
Oluomo ṣalaye pe iṣẹ oun akọkọ gẹgẹ bii Mayegun ni lati ri pe alaafia jọba nilẹ Yoruba.
"Lati kekere ni mo ti n sapa lati ri pe Naijiria tẹsiwaju, bẹrẹ lati adugbo ti mo n gbe titi de ilẹ okeere, idi niyẹn ti mo ṣe n ba awọn oloṣelu ṣepọ, mo n bawọn sọrọ, wọn si n tẹti si imọran mi."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò jẹ Mayegun láti bùgá, mo wá tún ilẹ̀ Yorùbá ṣe ni - Wasiu Ayinde
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ìyàwó gómìnà tọ́jọ́ orí rẹ̀ kéré jù ní Nàìjíríà rèé, ohun tóo lè fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀
- Ìyàtọ̀ wo ló wà láàrin Amotekun àtàwọn àjọ aláábò mìíràn
- Obasanjo, Makinde ṣèpàdé bòńkẹ́lẹ́ lórí ìhà tí ìjọba àpapọ̀ kọ sí Amotekun
Lori ọrọ ikọ Amotekun to ti di ariwo lẹyin ti ijọba apapọ ni ko ba ofin mu, o sọ pe ko sẹni to mọ ọmọ pọn bi ọlọmọ, fun idi naa, ko si eewọ ninu ka ṣọra ẹni, ṣugbọn ki ijọba fi oju ṣunukun wo ọrọ ọhun.