Operation Amotekun: Ẹgbẹ́ kan rọ Tinubu, láti sọ èrò rẹ lórí ọ̀rọ̀ Amọtẹkun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu
Lẹyin ti ọpọ eekan nilẹ Yoruba ti sọrọ akin lati gbaruku ti eto ẹṣọ Amọtẹkun tawọn gomina ipinlẹ Yoruba ṣe ifilọlẹ rẹ, ẹgbẹ kan to n jẹ 'Save Lagos Group' ti ke pe Asiwaju Bola Tinubu pe ki oun naa sọ ero rẹ faye gbọ.
Lootọọ Tinubu ko tii fi ero rẹ han lori ikọ Amọtẹkun ti awọn gomina mẹfẹẹfa ilẹ Yoruba ṣe ifilọlẹ rẹ lọjọ kẹsan oṣu yii niluu Ibadan.
Koda ẹgbẹ naa labẹ oludari rẹ, Ọgbẹni Adeniyi Sulaiman fun Tinubu ni wakati mẹrinlelogun lati sọ ero rẹ lori eto Amọtẹkun.
- Digbí ni mo wà lẹ́yìn Amotekun, máà ṣèrànwọ́ mílíọ̀nú èèyàn fun - Nnamdi Kanu
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó ní òun ló jí ọmọ gbé láti parọ́ mọ́ pásítọ̀ ìjọ Sotitobire
- 'Ẹ yé pè wá ní NEPA mọ́ tí ẹ bá fẹ́ ká fún yín ní iná, DisCos ni wá'
- Imam tó fẹ́ ọkùnrin míì níyàwó forí kó ìjìyà òfin
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- O leè má mọ̀ bóyá o ní àrùn HIV/AIDS o! Wo àwárí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ yìí
Ọgbẹni Sulaiman rọ Tinubu pe ko gbọdọ ṣojo lati sọrọ bo tilẹ jẹ pe o n gbero lati dupo aarẹ orilẹede Naijiria.
Oludasilẹ ẹgbẹ 'Save Lagos Group' ni isọkusọ lasan ni ẹgbẹ awọn darandaran, Miyetti Allah Kautal Hore n sọ lẹyin ti sọ pe eto Amọtẹkun le dena ki ọmọ Yoruba jẹ aarẹ ninu ibo gbogbogbo ọdun 2023.
O ni alagagebe ni ijọba apapọ pẹlu bi o ti tako eto Amọtẹkun nigba ti o faye gba ọlọpaa Shariah, Hisbah nipinlẹ to le ni mẹwaa lapa ariwa orilẹede Naijiria.
Wọn ni "eto aabo to mọyan lori nilẹ Yoruba san ju erongba ẹnikan lati dije fun ipo aarẹ lọ".
Ẹwẹ, agbẹjọro kan to fi ilu Eko sẹbugbe, Ọgbẹni Malcolm Omirhobo, ti gbe ijọba lọ si ileejọ lori bi o ti tako eto ẹsọ alaabo Amọtẹkun.
O rọ ileẹjọ lati kede pe ijọba apapọ n ṣegbe lẹyin ẹnikan lẹyin to faye gba iru ẹṣọ alaabo bi Amọtẹkun lapa ariwa.
Awọn ọtọkulu bi Ọjọgbọn Wole Soyinka, eekan ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Debanjo; agbẹjọro agba ati ajafẹtọ, Femi Falana, Oloye Olu Falae, ati Aarẹ Ọnakakanfo, Iba Gani Adams atawọn mii ni wọn ti sọrọ lati gbaruku ti eto Amọtẹkun.













