HIV/AIDS: Ìdá ogun nínú ọgọ́rùn ún ni kò mọ̀ pé àwọn ní àrùn
Wo iye Mílíọ̀nù èèyàn tí àìsàn aṣekupani HIV n ba finra.
Tẹlẹ ọgọrọ eniyan lo n ku lati ara aisan HIV/AIDs yii ṣugbọn pẹlu iṣẹ takuntakun awọn onimọ iṣegun oyinbo, ayipada ti de.
Ẹwẹ, lati ọdun 2004, iku naa ti dinku si ida marunlelaadọta bayii.
Dokita kan lo kuku ṣawari orukọ ti wọn bẹrẹ si ni pe e.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii ri abẹrẹ ajẹsara fun itọju aisan yii loni gedegbe, oogun wa digbi ti awọn eeyan ti fi n gbe pẹlu rẹ bayii.
Sibẹ naa, ìdá ogun ninu ọgọrun eniyan ni ko mọ pe wọn ni arun yii.
Adura ṣaa ni pe ki ẹni to ni i ri iwosan ki ẹni ti ko ni i si lanfani ati gbe ni alafia.