Báyìí ni mo ṣe gbẹ̀san lára ọ̀rẹ́kùnrin mi tó kó HIV ràn mí

Diane Reeve

Oríṣun àwòrán, Alyssa Vincent Photography

Àkọlé àwòrán, Diane Reeve today

Diane Reeve ko mọ pe oun tun le ni ololufẹ mọ lẹyin ti igbeyawo ọlọdun mejidinlogun rẹ tuka.

Sugbọn nigba to pe ẹni aadọta ọdun, o pade ololufẹ mi i, Philippe Padieu - o jẹ ẹni to ni ọrẹbinrin to pọ, oun naa lo si fun un ni aarun HIV.

Ori ẹrọ ayelujara la ti pade. O jẹ ọmọ orilẹede France, o si tun dun un wo l'ọkunrin.

Igba ti a kọkọ pade, a pade nile ounjẹ igbalode kan. Gbogbo ọrọ to si n sọ l'ọjọ naa lo dun mọ mi ninu.

Ọjọ naa gan an ni mo ti yofẹ fun un, mo si gbagbọ pe oun naa ko mi jẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

O sọ nkan pupọ fun mi nipa ara rẹ. Bayii la ṣe bẹrẹ irinajo ifẹ wa.

Philippe n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ nla kan gẹgẹ bi olugbani nimọran lori eto aabo, ṣugbọn wọn da a duro lẹnu iṣẹ lẹyin ọdun kan ti a bẹrẹ si ni fẹra wa.

Bo ṣe n wa iṣẹ mi i, mo rọ ọ lati maa ranmi lọwọ nileewe ti mo da silẹ.

Lasiko to fi n kọ awọn akẹkọọ mi, a maa n ṣere jade lẹyin iṣẹ, ao si jọ sun mọju. A ti jọ damọran pe a fẹ fẹra wa, nitori naa la ṣe maa n rira ni ẹẹmẹta tabi ẹẹmẹrin l'ọsẹ.

Inu mi maa n dun, inu ti ẹ naa si dun. Ibasepọ wa dan mọran, a si jọ wa pọ fun ọdun mẹẹrin ataabọ.

Lọjọ ti ọmọ mi obinrin n ṣegbeyawo l'ọdun 2006, ni Philippe deede pe mi pe ara oun ko ya, oun ko si ni le wa fun apejẹ lẹyin ayẹyẹ igbeyawo naa.

Mo ṣakiyesi pe kii ṣe ẹrọ ibaraẹnisọrọ ile rẹ lo fi pe mi, eyi si mu ki ara fu mi. Inu bi mi, nitori pe apejẹ naa ṣe pataki si mi pupọ.

Diane and her daughter

Oríṣun àwòrán, Diane Reeve

Emi nikan ni mo da lọ sile, mo si pinnu lati ya wo Philippe ti ara rẹ ko ya.

Mo ri i pe wọn ko tan ina ile rẹ, ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ko si si ni ita. O dun mi pupọ debi i pe mo sun ẹkun, laipẹ ẹkun naa di ibinu.

Emi ni mo n san owo sori ẹrọ ibanisọrọ rẹ, nitorina mo lo anfaani naa lati yẹ awọn to n pe e wo. Ibẹ ni aṣiri ti tu si mi lọwọ pe emi nikan kọ lo n fẹ.

Àkọlé fídíò, Yomi Fabiyi ló ni ki òun àti ìyàwó rẹ̀ yàgò fún ra wọn

Wakati kan ataabọ gbako ni mo fi duro de e, ki n to ri ọkọ ayẹkẹlẹ rẹ lọọkan.

Bo ṣe ri ọkọ ayọkẹlẹ mi, lo bẹrẹ si ni wa ọkọ rẹ salọ. Ara ti fu u pe aṣiri rẹ ti tu si mi lọwọ. Bi emi naa ṣe tẹle niyẹn. A wa ọkọ fun igba pipẹ ko to o duro.

Mo si sọ ọ kan l'oju pe oun ṣe agbere. Nise lo pariwo mọ mi, o si fẹ ẹ ba ọkọ mi jẹ

Diane Reeve

Oríṣun àwòrán, Alyssa Vincent Photography

Àkọlé àwòrán, Diane àti Philippe fẹ́ràn ara wọn púpọ̀

Ọjọ ti a fi ara wa silẹ jẹ ọjọ Abamẹta, mo si lọ fun ayẹwo l'ọjọ Aje to tẹle nibi ti wọn ti sọ fun mi pe mo ni aarun to n ba agọ ara jẹ ti wọn n pe ni Human Papiloma Virus, HPV.

Mi o ni iru aarun bẹ ẹ ri, l'oju ẹsẹ ni mo si ti mọ pe oun lo ko o ran mi.

Ẹru ba mi pupọ, mo si ro o pe boya ki n sọ fun awọn obinrin mi i to n ba ni ibalopọ.

Mo bẹrẹ si ni pe wọn lọkọọkan. Obinrin mẹsan ni mo ba sọrọ.

Awọn kan bu mi, awọn kan si gbọ imọran mi pe ki wọn dẹkun nini ibalopọ pẹlu rẹ, ati pe ki wọn lọ fun ayẹwo.

Diane and Philippe in Vegas

Oríṣun àwòrán, Diane Reeve

Obinrin kan tun wa ti mo pada ba sọrọ. Oun ati Philippe ti n fẹra wọn fun bi i ọdun kan ataabọ. Mo sọ gbogbo nkan to ti ṣẹlẹ si mi fun un - titi dori bi emi ati ẹ ṣe jọ n kọ ile kan, ati bi ao ṣe gbe papọ, ko to o di pe a tuka.

Mo sọ ti aarun ti mo ni fun un bakan naa. O tẹti si mi, ṣugbọn mo sọ fun pe 'oun lo ni ara rẹ o, ko ṣe e to ba ṣe wu.''

Igba ti ọkan lara wọn lọ fun ayẹwo ni ayẹwo fi han pe o ni kokoro aarun HIV.

Lẹyin oṣu mẹta ni ileewosan mi i na pe mi pe ki n wa fun ayẹwo. Igbayi lo to o ye mi pe gbogbo awọn apẹrẹ ti mo n ri lati bi oṣu melo kan, ati bi ara mi kii ṣe fi gbogbo igba ya jẹ apẹrẹ aarun HIV.

Mo lọ fun ayẹwo. Esi ti maa gbọ ni pe mo ti ni aarun AIDS.

Haa, inu mi bajẹ pupọ. Mo sọkun, mo si ro pe maa ku.

Diane and Philippe

Oríṣun àwòrán, Diane Reeve

Mo sọ fun ọkan lara awọn obinrin naa to ni aarun yii, o si sọ fun mi pe nise ni Philippe pariwo mọ oun nigba to n bi i pe o fun oun ni aarun HIV.

O lo sọ pe ''boya eniyan ni aarun HIV tabi ko ni, iku kan naa ni yoo pani. Fi mi silẹ, ko lọ maa ṣaye rẹ.''

Awa mejeeji fura pe oun lo ko aarun naa ran wa. A si pinnu lati fi ọrọ naa to awọn ọlọpa leti.

Philippe and Diane

Oríṣun àwòrán, Diane Reeve

A fẹ ki wọn o da a duro, ko maa ba a tun ko aarun naa ran awọn obinrin miran.

A fẹ ẹ mọ boya lootọ lo ni aarun naa, a si fẹ ẹ ms nkan ti a le ṣe lati fi opin si bo ṣe n pa awọn obinrin lẹkun.

Awọn ọlọpa ba wa kẹdun, wọn si farabalẹ gbọ ọrọ wa. Sugbọn wọn sọ pe awa mejeeji nikan ko le fidi ẹjọ naa mulẹ, ayafi ti obinrin bi i mẹrin tabi maarun ba ṣetan lati jẹri ni wọn to o le ṣi agbẹjọro agbegbe naa lati wo ọrọ wọn.

Isẹ tun bẹrẹ ni pẹrẹhu. Pẹlu iranlọwọ ọkan lara awọn ti mo ti kọkọ ba sọrọ, ti oun naa ti ṣayẹwo to si ni aarun HIV, to bẹrẹ si ni ṣọ ọkọ ayọkẹlẹ ti gbogbo awọn obinrin to n wa Philippe wa n gbe e wa. Eyi rọrun nitori pe adugbo kan naa l'oun ati obinrin yii n gbe.

Ey na wa ni ọpọlọpọ wahala, nitori pe obinrin ọtọọtọ lo n gbe wa sile lojoojumọ.

Nọmba ara ọkọ ayọkẹlẹ wọn lasi fi wadi orukọ ati ibi ti wọn n gbe.

Awa obinrin mẹtala la ri pe a ni aarun naa.

Àkọlé fídíò, 'Bí aya bá kọ ọkọ rẹ̀ silẹ̀, kó wà láì lọ́kọ̀'

Inu mi bajẹ nitori pe ọpọ lara wọn lo ti n fẹ Philippe ki emi ati ẹ to o pade. Eyi to tumọ si pe awọn obinrin ti ko niye ni yoo ti ko aarun naa lara rẹ.

O nira diẹ lati mọ boya o ni aarun naa, tabi igba to ti ni. Sugbọn pẹlu iranlọwọ pe emi ni mo n san owo ileewosan rẹ, o rọrun fun mi lati wo akọsilẹ awọn oun to ti gba itọju fun nileewosan.

Asiri pada tu pe o ti ni aarun naa ki emi ati ẹ to o pade. Ninu awa obinrin mẹtala ti a ri ara wa ko jọ, awa maarun pere la gba lati jẹri tako o nile ẹjọ. Awọn kan jawọ nitori idojuti to le jẹyọ ti awọn eniyan ba mọ pe wọn ni aarun naa.

Ọdun 2009 ni igbẹjọ bẹrẹ. Philippe kọkọ parọ pe emi ni mo ko ran oun, sugbọn a pada ri obinrin kan to sọ fun wa pe ọdun 1997 ni Philippe ti ko aarun naa ran oun. Bakan naa ni ayẹwo ẹjẹ gbogbo wa fihan pe orisun kan naa (Philippe) ni kokoro aarun naa gba wọ ara wa.

Ara wa fu mi pe ọjọ ti pẹ to ti mọọmọ n ko aarun naa ran awọn obinrin.

Àkọlé fídíò, Àwa obìnrin tó ń lépa afòjúsùn máa n ba ọkùnrin lẹ́rù ni -Toyin Lawani

Ko rọrun lati dariji, nitori o ti jẹ ko ṣoro fun mi lati fi inu tan ẹnikẹni.

Lootọ mo ti gba kadara, a ti pe mo ti pade ọkunrin mi i to nifẹ mi, to si mọ nipa aarun mi. Igba keji ti a jọ jade ni mo ti sọ fun, o si jẹ ko ye mi pe, aarun HIV lo pa aburo oun kan.

Ẹwọn ọdun marundinlaadọta ni wọn ju Philippe si, lẹyin ti ile ẹjọ ri i pe o jẹbi ẹsun mẹfa to niiṣe pẹlu lilo ohun ija oloro - àtọ̀ ọmọkunrin rẹ lati ṣe iṣẹ ibi.