NEPA: Ọ̀gá DisCos rọ ọmọ Nàìjíríà kí wọ́n yé pè iléeṣé tó ń p'íná ní NEPA mọ́

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹ ye pe wa ni NEPA mọ bi ẹ ba fẹ ina ọba, DisCos ni orukọ ile iṣẹ wa.
Alakoso ẹgbẹ awọn ile iṣẹ to n pin ina ọba, Sunday Oduntan lo sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo lori ẹro amohunmaworan.
O ni tawọn ọmọ Naijiria ba tẹsiwaju lati maa pe ile iṣẹ awọn(DisCos) ni NEPA, a jẹ wi pe wọn ko tii fẹ ina ọba niyẹn.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó ní òun ló jí ọmọ gbé láti parọ́ mọ́ pásítọ̀ ìjọ Sotitobire
- Ẹ̀yin Marlians, ṣẹ mọ̀ pé Naira Marley kìí ṣe aláàbọ̀ ẹ̀kọ́, ó kàwé jáde ní fásitì?
- Ẹ̀yin gómìnà, ẹ bá wa bi Buhari pé kí ló ń bàá lẹ́rù lórí Amotekun - Aráàlú
- Fasola ló jẹ̀bi ìdákúrekú iná ọba - ọmọ Nàìjíríà fárígá lórí òkùnkùn biribiri
- Digbí ni mo wà lẹ́yìn Amotekun, máà ṣèrànwọ́ mílíọ̀nú èèyàn fun - Nnamdi Kanu
- Ọta ìbọn ogun Biafra ṣì wà lọ́rùn mi lẹ́yìn àádọ́ta ọdún tí ogun parí - Umar
''Niwọn igba ti ẹ ba si n pe wa ni NEPA, o fihan pe ẹ ko mọ pe ọpọn ti sun lori ọrọ ina mọnamọna ni Naijiria niyẹn,'' Oduntan lo woye bẹẹ.
Ọgbẹni Oduntan ni o tun fihan pe awọn eeyan ko fẹ ayipada ti wọn ba si n pe ile iṣẹ DisCos ni NEPA, ati pe wọn ko fẹ ipese ina mọnamọna ti wọn si n pe awọn NEPA.
O ṣalaye siwaju sii pe ile iṣẹ NEPA lo kọkọ wa ko too di PHCN, ṣugbọn o ti di DisCos bayii bo tilẹ jẹ pe ijo ''DisCos'' kọ lawọn n jo nibẹ.
Ọgbẹni Oduntan omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọọ, ile iṣẹ NEPA ati PHCN ti ohun igbagbe ni Naijiria, DisCos lo wa lode bayii.
O tun sọrọ lori afikun owo ina wi pe igbesẹ ṣe pataki nitori ida marunlelaadọrun un eroja tawọn n lo, oke okun lawọn ti koo wa.












