Risikat Azeez: Aya gómìnà tún fẹ́ gba sọ́ọ́bù, ra ọjà fún obìnrin olójú búlúù

Oríṣun àwòrán, @Mohammed Jagunma ati Gold Abdulrafiu
Ojo oriire si n rọ siwaju fun idile Risikat Oloju Buluu ati ọkọ rẹ, Abdulwasiu pẹlu awọn ọmọ wọn.
Idi ni pe aya gomina ipinlẹ Kwara, Olufolake Abdulrazaq, to ti tẹwọgba ọrọ wọn lati ilẹ ko tii jawọ nibẹ, to si tun n se wsn loore siwaju lọ.
Nibayii, lẹyin ayẹyẹ yigi ti wọn so lọjọ Satide, aya gomina ti gba ile fun wọn lati maa gbe lọtọ yatọ si ile mọlẹbi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
- Àwọn ọ̀daràn tó jí ìbejì ọmọ Akeugbagold kó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lòníì
- Àjọ ECOWAS yan Aàrẹ Ghana, Nana Akufo-Addo gẹgẹ bíi aàrẹ tuntun
- Àrà mánigbàgbé tí Baba Legba dá lágbo tíátà rèé
- Ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn NUJ ìpínlẹ Oyo bà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó lọ ìpàdé tí Femi Fani Kayode pè ní Ibadan wí
- Fìdíhẹẹ́ ní Banji Akintoye nínú YWC, lílọ ni yóò lọ - Tola Adeniyi
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, akọwe iroyin si aya gomina, Yinka Adeniyi sisọ loju rẹ fawọn akọroyin pe, lati ipasẹ ẹgbẹ alaanu ti aya Abdulrazak da silẹ, ni eyi ti see se.

Oríṣun àwòrán, Arewa_ilorin_pple
Ẹgbẹ alaanu naa, to pe ni Ajike Support Grouplo gba ile filaati oniyara meji fun idile naa laarin igboro ilu Ilorin.
O fikun pe ọjọ Ẹti to kọja ni wọn fun tọkọtaya naa ni kọkọrọ ile naa, nigba to ku ọla ti wọn yoo so yigi.
Bakan naa lo ni adugbo tawọn ẹbi ọhun fẹ ni wọn gba ile naa si fun wọn.
Awọn eto ti aya gomina ni fun Risikat ati ọkọ rẹ wa nipele ipele, a tun fẹ gba sọọbu fun obinrin oloju buluu naa lati maa ta oogun to kọ isẹ rẹ.
A lero lati san owo ile ati owo sọọbu rẹ papọ ni, amọ a gbọ pe ẹlomiran ti gba sọọbu ta fẹ sanwo rẹ naa, idi ree ta fi sanwo ile nikan, ta si ni ki obinrin naa lọ wa sọọbu miran."
Akọwe iroyin aya gomina tẹsiwaju pe lẹyin eyi ni wọn yoo gba iwe asẹ lati maa ta oogun fun obinrin naa, ti wọn yoo si ra oogun kun inu sọọbu rẹ fun tita.
- A kò sí lára àwọn tó ń ṣèwọ́de tako èlé owó epo àti iná ọba - NLC
- Jàńdùkú olóṣèlú gbàkóso ilé aṣòfin l‘Ondo
- Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan
- Eruku ìjà sọ lálá lórí ayelujára láàrin Oyedepo àti Daddy Freeze
- Ọmọ Nàíjíríà kó N6m jọ lórí ayélujára fún Erica tí wọn lé ní BB Naija
- Mo fòpin sí àjẹbánu lórí owó ìrànwọ́ epo àti iná ọba, ní èlé ṣe wáyé - Buhari
A wa n ki Risikat ati ọkọ rẹ pe wọn ku oriire ayọ igbeyawo, Ọlọrun yoo se wọn ni ọrẹ ara wọn.
Risikat olójú búlù dí aya Wasiu ní ìlànà Islam, tẹbí tará péjú síbẹ̀

Oríṣun àwòrán, @Mohammed Jagunma ati Gold Abdulrafiu
Loni, ọjọ Satide, ọjọ karun un, oṣu kẹsan an ni Baba Kausara àti Iya Kausara di ara kan naa bii lọkọlaya ninu ẹsin Islam ni Ilorin ni ipinlẹ Kwara.
Se ẹ ranti ọrọ Risikat ati Wasiu ọkọ rẹ nitori oju bulu aya ati ọmọ rẹ meji?
Iroyin ni Ilorin Emirate Dev. Progressive Union lo ṣagbatẹru Nikkah naa laarọ yii.
Ni ọkọ ba ti mọ oju aya tan,
Ki gbogbo alarina yẹba lo ku.

Oríṣun àwòrán, @Mohammed Jagunma ati Gold Abdulrafiu
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá dènà ọkùnrin tó fẹ́ pa ara rẹ̀ nítorí ọmọbìnrin Buhari
- Àwọn ọmọ Naijiria ṣèdárò gbajúgbajù agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tó dolóògbè
- Ó ń bọ̀ lọ́nà! Odunlade Adekola, Femi Adebayo, Jenifa ṣi aṣọ lójú àwọn fíìmù tuntun tẹ́ẹ ti ń retí
- Ẹ̀rọ CCTV tú àsírí ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá bá ọmọ ọdún mọ́kànlá lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, @Mohammed Jagunma ati Gold Abdulrafiu
Lawọn Aafa nlanla ba kuku so yigi Iya Kausara ati Baba Kausara o
Ni awọn alarinna ba ṣetan ati yẹba fun tọkọ taya.

Oríṣun àwòrán, @Mohammed Jagunma ati Gold Abdulrafiu
Eyi lo tun fidi imọran awọn agba Yoruba mulẹ pe iwọnba leeyan n da si ọrọ lọkọlaya mọ nitori....

Oríṣun àwòrán, @Mohammed Jagunma ati Gold Abdulrafiu
Abi ẹ o riṣẹ Olorun bi?
Ero peju sibẹ lati ba Risikat ati Wasiu yọ ni Ilọrin ni ipinlẹ Kwara ni aarin gbungbun Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @Mohammed Jagunma ati Gold Abdulrafiu
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ọba Ilorin ló pàṣẹ pé kí ń padà sọ́dọ̀ ọkọ mi - Risikat olójú búlúù
Ilé wa ni mo ṣì wà, èmi kò tíì padà sọ́dọ̀ Bàbá Kaosara
Arabinrin Risikat Azeez ti ọpọ eeyan mọ si oloju buluu, naa ti fesi lori awọn ohun ti ọkọ rẹ ba BBC Yoruba sọ l‘Ọ́jọbọ.
Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin pe ọkọ Risikat Abdulwasiu Azeez ni oun ati aya oun ti pada sọdọ ara awọn, ti awọn si ti jọ n se mukẹẹkẹ.
Sugbọn ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu wa ni aarọ ọjọ Ẹti, Risikat ni oun ati baba Kaosara dijọ ya fọto papọ ni, ile awọn si ni oun si wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kére o! Nàíjíríà tún ń wọnú ọrọ̀ ajé tó dagun lọ lẹ́ẹ̀kejì - Ìjọba àpapọ̀ laago ìkìlọ̀
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé oṣù ojú ọ̀run táwọn Mùsùlùmí ń lò ti wà saájú Ànọ́bì?
- Ẹ ṣí ilé ìwé padà ní Áfíríkà torí ọjọ́ iwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yín - WHO, UNICEF
- Bí ìyàwó rẹ bá lóyún tàbí bímọ ní ìpínlẹ̀ Oyo, wo bí o ti ṣe lé gba ìsinmi ìtọ́mọ (Paternity leave)
- Ẹ̀bùn #500,000 wà fún ẹni tọ bá ba wa rí afurasí ikú Akinyẹle tó sọnù- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- 'Ẹ̀pa ò bóró mọ́! Òkú ọmọ ọdún mẹ́ta tó kó sí kàǹga ní Ipaja ni wọ́n yọ'
"Rara o, wọn so yigi o, ile wa ni mo wa. Ohun ti mo kan ri nibẹ ni pe aya gomina Kwara ran awọn eeyan wa pe awọn fẹ ka pari aawọ to wa laarin wa, ka si maa sọrọ sira wa.
O tan o, nnkan ti wọn wa fun niyẹn.
Risikat fikun pe, nigba to ya ni wọn tun ni ki eeyan kan wa wọn oun ati ọkọ oun, ti yoo ba awọn ran asọ wa, ti onitọun si gbe ankoo naa wa ni ọjọ keji.
"Nigba to di Ọjọru, ni wọn ni ka ko asọ wa dani, ti wọn si ni ki wọn se oju mi loge fun mi nibudo ẹkọsẹ asaraloge ti mo ti n kọsẹ.
Ati ibẹ ni ọga mi ti gbe mi lọ si ile ijọba, a debẹ, ni wọn ba n ya fọto fun wa, ohun ta ri naa nuu."
Risikat fikun pe lootọ ni aya gomina n sọ pe ki awọn mejeeji pari ija, ki awọn si maa sọrọ si ara awọn, ti wọn si ya fọto fun awọn.
Nigba ti BBC Yoruba bi iya Kaosara leere pe se lootọ lo ti n lọ sun sile ọkọ rẹ gẹgẹ bi ọkọ rẹ ti sọ fun wa, o dahun pe:
"Mo fi Ọlọrun Ọba bura, ko si ohun to jọọ, ile wa ni mo wa, n ko si lọ sile ọdọ rẹ"
Lori ipalẹmọ lati tun yigi so, Risikat ni ọba Ilọrin ti ran awọn eeyan wa lati ba awọn pari ija, to si ni wọn ti n pari rẹ lọwọ.
"A ko tii mu ọjọ iyawo, amọ wọn saa fẹ se, ki wa ni mo fẹ se? Ọba Ilọrin sọ pe ohun ti oun yoo se niyẹn, oun gbẹsẹ le."
Amọ nigba taa bii pe ki lo fẹ ki wọn seto, ko to pada sọdọ ọkọ rẹ, Risikat ni ti wọn ba pari ija tan laarin awọn mejeeji, ko sẹni ti yoo ya si ọdọ awọn mọ.
"Ko sẹni to sọrọ lori ọrọ isẹ mi mọ, mo si fẹ ki wọn mojuto ọrọ ile iwe awọn ọmọ mi, isẹ temi naa, bẹẹ ni skọ mi gan ko ni isẹ to duro re."

Oríṣun àwòrán, Arewa_ilorin_pple
Tá bá fi rí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ si, èmi àti aya mi yóò tún yìgì so - Ọkọ Risikat olójú búlúù
Arakunrin Abdulwasiu Ọlọmọyọyọ, tii se ọkọ Risikatu Azeez, arabinrin oloju buluu nilu Ilorin, ti fi idunnu ati ayọ rẹ han fun awọn ọmọ naijiria lori aayan ti wọn ko lati jẹ ki ija to wa laarin oun ati iyawo rẹ pari.
Bakan naa ni Abdulwasiu, ti ọpọ eeyan tun mọ si baba Kaosara tun dupẹ pupọ lọwọ ileesẹ iroyin BBC Yoruba fun atilẹyin wa lori ọrọ naa ati ibi taa ba de, eyi to ni apẹrẹ rere.
Ọkọ Risikat oloju buluu naa ko sai tun se sadankata si aya gomina ipinlẹ Kwara, fun iranwọ to n se lati ri pe idile oun pada toro pẹlu itọju to n se fun wọn.
Amọ sa, Abdulwasiu wa fidi rẹ mulẹ pe laipẹ laijinna, oun ati iyawo oun yoo tun tun yigi so, ti idile oun yoo si pada duro re.

Oríṣun àwòrán, Arewa_ilorin_pple
Mo fẹ ki Ọlọrun fun wa ni ọmọ oloju buluu si lẹyin yigi - Ọkọ oloju buluu
Saaju la ti mu wa fun yin pe Abdul Wasiu ti sọ fun ileeṣẹ BBC Yoruba pe ni nibayi, ija ti pari laarin oun ati iyawo rẹ.
''Inu mi dun pupọ. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun ati awọn ọmọ Naijiria fun aduroti wọn''
O ṣalaye pe lọdọ Risikatu loun ti kuro laarọ yii ati pe ko ni pẹ ti awọn yoo fi tun ṣe yigi pada''
Laipẹ yii ni awọn eeyan n beere boya awọn mejeeji yoo pari ija laarin ara wọn.
Koda iyawo Gomina ipinlẹ Kwara sọ wipe, oun yoo gbiyanju lati pari ija laarin awọn mejeeji.
Ninu ohun ta ri gbọ lẹnu Baba Kaosara bakan naa o sọ pe, iyawo Gomina lo ba awọn pari ija naa ,ti o si tun ṣatọkun bi wọn ti ṣe jijọ ya aworan papọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
- Wo bí o ṣe le fi orúkọ sílẹ̀ fún ìgbani ṣíṣẹ́ ológun Nàìjíríà tó bẹ̀rẹ̀
- Ọmọdé 5 àti àgbà 40 bómi òkun lọ, 37 mórí bọ́ lásìkò tí ẹ́ńgínì ọkọ̀ ojú omi gbiná
- Wo ibùdó arẹwà tí ọ̀pọ̀ èrò ń ya lọ ní Abuja
- Obìnrin kan dèrò ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó fi ọ̀bẹ rẹ́ ọmọ rẹ̀ lọ́rùn
- Adamu Adamu, Minista ètò ẹ̀kọ́ ti fi òfin àátẹ̀lẹ́ síta kí àwọn ilé ìwé lè wọlé
- Makinde ti sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí asekúpani Akinyele sálo mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ ní àhámọ́
- Olólùfẹ́ mi ṣèèsì fi ọkọ́ gbá mi sí gọ́tà, mo rò pé ọlọ́jọ́ dé ni - Iya Osogbo
Nigba ti BBC Yoruba bi Abdulwasiu pe ki ni yoo sẹlẹ lẹyin ti wọn ba tun yigi se, ti aya rẹ si tun bi ọmọ oloju bulu, baba Kaosara dahun pe ọmọ oloju gan ni oun n tọrọ lọwọ Ọlọrun bayii.
"Inu mi yoo dun pupọ ta ba tun bi ọmọ ti oju rẹ yoo bulu, koda, ki ni mo fẹ fi ọmọ olju funfun se mọ, mo tiẹ n gbadura pe gbogbo ọmọ ti Ọlọrun yoo ba fun mi siwaju, ki wọn jẹ oloju bulu."
Iṣẹ lo wa ku bayi, ẹ saanu mi
Abdulwasiu ti wa kesi awọn ọmọ Naijiria lati ṣe iranwọ fun ohun ni[pa ọna iṣẹ lati le fi tọju mọlẹbi rẹ.
O sọ pe ko si iṣẹ kankan lọwọ oun bayii, toun si n beere iranwọ lọdọ awọn araalu lati se atọna bi oun yoo se ri isẹ.


















