BBNaija 2020: Terry Waya ní torí ìfẹ́ tí Erica ní sọ́mọ òun ló fi ní ọ̀pọ̀ ìṣòro

Yàtọ̀ sí owó ti àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kó jọ fún Erica nítorí pé wọ́n lé e kúrò nilé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà, bàbá Kiddwaya náà ti ṣe ilérí tuntun.
Terry Waya tó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká olówó, lásìkò tó n sọ̀rọ̀ lórí ayélujára instagram pẹlú olóyè Dele Momodu, sàlàyé nipa ètó tó ni nílẹ̀ fún Erica, tiwọ́n le kúrò nílé lọ́lọ́ ọjọ Aiku.
Nínú fọ́nran náà ni Terrywaya ti sàlàyé pé, gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ si Erica nínú ilé kò ṣẹ̀yìn ìfẹ́ to ni sí ọmọ òun Kiddwaya, nítori náà, ó yẹ kó ni ìpin nínú owó ẹlẹ́gbọ̀n àgbà.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló le è mú kí agbábọ́ọ̀lù subú, kó sì kú lásìkò ìfẹsẹ̀wọ̀nsẹ̀?
- Ọlọ́pàá rí òkú ọ̀gá àgbà iléèṣẹ́ ńlá kan tí wọn ń wá, lójú omi l‘Eko
- A gbé òfin 1960 jáde, màálù tó bá jẹ oko àgbẹ̀, tí olówo rẹ̀ kò sanwó, títà ni - Buhari
- Ìjọba fẹ́ kọ́lé 300,000, pẹ̀lú ìrànwọ́ fún àgbẹ̀ 4m láti mú àdínkù bá ìṣẹ́ - Osinbajo
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Coronavirus ti fa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní ìpínlẹ̀ Eko, Kano, Rivers àti Abuja- NBS
- Àwọn èrò yarí lórí sísan owó àyẹwò covid-19 bí bàálù ilẹ̀ òkèèrè ti ba s'Abuja lẹyìn oṣù márùn ún
Nítorí ìdí èyí, Terrywaya ní bi ọmọ òun bá gbégbá orókè nínú idíjẹ to n lọ lọ́wọ́ yìí, òun yóò ri dájú pé ìdajì nínú rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Erica, nígbà ti èyí tó kù yóò padà lọ sí ilé àwọn aláìní.

Oríṣun àwòrán, BB Naija
Ó sàlàyé pé, ọmọ to ṣe e mú yangan ní Erica, tó si lè dúró tí ni lásìkò ìṣòro àti pé, gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ si nínú ilé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà, ọ̀pọ̀ wa nítorí Kiddwaya ni.
Kíní àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ?
Gẹ́gẹ́ bi ìṣe àwọn ọmọ Naijiria, àwọ́n kan pé ara wọ́n ní Ellites (àwọn yìí ló wà fún Erica ) nígbà ti àwọn kan pe àra wọ́n ni Icon (àwọn ti Laycon), àwọn ẹ̀ka méjèèjì yìí ti ń gba ọ̀rọ̀ náà bí ẹni gbagbá ọtí.
Onírúurú ọ̀rọ̀ lón tí n lọ lórí ǹkan ti bàbá Kiddwaya sọ. Bí àwọn kan ṣe ń sọ pé, ọrọ ọmọ ni bàbá Kiddwaya ń ṣe, ni àwọn míràn sọ pé, ọgban àti lu àwọn ọmọ Nàìjíríà ni jìbìtì ni.
Wọ́n ni kò si àníàní, Laycon lo ni owó tó wà níle ẹgbọ́n àgbà, àti pé ki Terrywaya lọ wá owó tirẹ̀ síwájú, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé olówó ni bàbá òun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ètò ìkówó jọ ti wọ́n ń ṣe fún Erica ṣì n lọ lọ́wọ́ títi di àsìkò yìí.
Bobrisky gbé N1m fún Erica torí ẹnu tó ń kùn-ún

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹ́yìn awuwuye tó tẹ̀lé bí Erica ṣe hùwà sí Laycon nínú ilé ẹlégbọ́n àgbà lẹ́yìn páti alẹ́ ọjọ́ Satide.
Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ni ìdájọ́ to yẹ ni láti le Erica kúrò nínú ilé.
Sùgbọ́n lẹ́yìn ti ẹlẹ́gbọ̀n àgbà ṣe ìdájọ rẹ̀ tán tó sì fọ́wọ́ òsì júwé ilé fún Erica ní àwọn ọmọ Naijira bá ń sọ èrò tí wọ́n lóri ọ̀rọ̀ náà lórí ayélujára.
Bí àwọn gbájugbajà òsèré ṣe ń sọ ti wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó jẹ́ ilúmọ̀ọ̀ká láwùjọ àti àwọn ọmọ Naijira míràn náà ń sọ bí o ṣe yẹ kí o rí.
- Wo ìdí tí wọ́n ṣe lé Erica dànù kúrò nílé BBNaija l'ọ́sẹ̀ yìí
- Kí ló ṣe Ibrahim Chatta tó fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Ọlọ́pàá wú òkú obìrin tó ń múra ìgbéyàwó lọ́wọ́ tí 'gate-man' rẹ̀ ṣekúpa
- "A fẹ́ yọ ààrẹ ẹgbẹ́ Yorùbá YCE nípò torí àwọn ìwà tí kò bójúmu"
- Wo àànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Ẹ fura o, Boko Haram ti pàgọ́ sí Abuja, yóò ṣe ìkọlù láìpẹ́ - Iléèṣẹ́ Aṣọ́bodè lọgun
Lára àwọn tó fi èrò wọ́n sórí ayélujára ni
Gbájúgbajà ọkùnrin to máa ń múra bi obìnrin Olarewaju Idris Okunneye ti gbogbo ènìyǹ mọ̀ si Bobrisky tó fi ìpè síta pé ki wọ́n bá òun fi nọ́mbà ìfówopamọ́ rẹ̀ ranṣẹ́ nítori òun fẹ́ ta lọ́rẹ. mílíọ̀nù kan Naírà.
Ó ní tí a bá fi ọwọ́ ìtún bamọ wi, o di dandan ki a fi ọwọ́ òsì fàá mọ́ra nítori náà òun fẹ́ fún ni mílíọ̀nù kan náírà.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Bakan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Naijira lórí àtẹjíṣẹ́ twitter sọ pé àwọn yóò ṣe àkójọpọ̀ ọgọ́rùn mílíọ̀nù náírà láti fi ràn lọ́wọ́.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ bi a ṣe n kó ìròyìn yìí jọ àwọn ènìyàn ti ṣe àgbékalẹ̀ mílíọ̀nù mẹ́fà náírà.

Oríṣun àwòrán, Others
Ìyẹn nìkan kọ́ oo, bí ẹlẹkún ṣe ń sunku bẹ́ẹ̀ ni aláyọ̀ ń yọ, ẹyi lo dífa fún ọmọ binrin kan tó wa ẹkún mu bi omi nítori pe wọ́n le Erica kúrò nile ẹgbọ́n agbà
Ẹkún gidi ni ọmọbìnrin yìí ń sun lẹ́yìn ti wọ́n le Erica kúrò nilé ẹlẹgbọ̀n àgbà
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Nínú fọ́nran náà ni ọmọbinrin kan ti n sùnkun tó sì bẹ̀rẹ̀ sí n'ṣépè fún Laycon.
Sùgban ọ̀pọ̀ ni ko gbà pé Laycon ló jẹ̀bi nínú ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ni gbogbo ìkìlọ̀ ti Erica ti gba jẹ́ èyi ti kò bá má wáye, tó ba jẹ́ pé kò ni ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Kiddwaya ni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4

Oríṣun àwòrán, BBNaija/ Instagram
Ó jọ́ bi ẹni pé nǹkan o ṣẹnu ire fún Erica nínú ilé BB Naija láti alẹ ọjọ́ Sátidé.
Gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ló si ti n bẹnu àtẹ lu ìwà tó wu.
Kíló ṣẹlẹ̀ gan tí Erica fi tú bí ejò táa gé nírù?
Lásìkò ti patí alẹ́ ọjọ́ Satíde n lọ lọ́wọ́, ni inú ti bẹ̀rẹ̀ si ni bi Erica nítorí bi Nengi ṣe ń jó pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ̀ Kidwaya.
Erica wa kesi Nengi pé ti o ba nífẹ̀ Kiddwaya, ore-ọ̀fẹ́ wà fún láti sọ ni àsìkò yìí nítori pé, bi ó ṣe ń ṣe ni àyíka rẹ̀, kò tẹ́ òun lọ́rùn rárá.
- Tinubu, yé é sọ̀rọ̀ abẹ́lẹ̀, bọ́ sí gbangba láti bèèrè àtúntò Nàíjíríà lọ́dọ̀ Buhari - Afẹnifẹrẹ
- Wo àwọn ìlànà tuntun ti o gbọdọ tẹlèé rèé ki ó to le wọkọ̀ òfurufú lọ sókè òkun
- Ẹ̀rọ CCTV tú àsírí ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá bá ọmọ ọdún mọ́kànlá lòpọ̀
- Toyin Abraham pé 40, wo ohun márùn ún tó mú dá yàtọ̀ láàrín ogójì ọdún
Nengi fún Erica lésì pé, kìí ṣe pé Kiddwaya fi bẹ́ẹ̀ wu òun lọ́mọ́kùnrin, sùgbọ́n kìí ṣe inú ilé BB Naija ni òun ti ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ Kiddwaya, àti pé àwọn ti mọra tipẹ́.
Ní kéte ti pati pari, ti olúkúlùkù sì n jíròrò lọ́wọ́ nínú ilé ìdána, ni Erica ba tún ta mọ Laycon, bẹ́ẹ̀ lo ń pariwo fòò pé, ó maa n parọ fún Ebuka pé òun máa ń gbìyànjú láti fẹnukò òun lẹ́nu ní ẹ̀ẹ̀meeji ọ̀tọ̀ọ̀tọ.
Gbogbo bi Kiddwaya àti Trikytee ṣe gbìyànjú tó lati pẹtù si, Erica ò gbọ́ rárá.

Oríṣun àwòrán, Others
Erica ń kígbe pé, Laycon ko si lára ẹni to wu òun rárá, òun ko sì fi ìgbà kankan gbìyànjú lati fẹnu kòó lẹ́nu ri.
Kò si irú èébu ti ko bu Laycon tan, o tún pe e ni "Skinny drum Stick" èyi to tumọ si ki wọ́n pe ènìyàn ni kọ̀ngọ́ ìlù.
Kò tán síbẹ̀ óò, nígbà ti Erica tún de yàrá ti wọ́n ti yà sọ́tọ̀ fún àwọn olórí ilé, ó tún kọjú mọ́ Prince, nítorí pé ó ń gbìyànjú láti pẹ̀tù síi lọ́kàn.
Ó sọ fún Prince náà pé, àṣìṣe gbáà ni fún òun láti yan àn gẹ́gẹ́ bi ìgbákeji olórí ilé.
O ní ẹ̀tọ́ rẹ̀ ni gẹ́gẹ́ bi ìgbákejì òun láti dúro ni apá ibi ti òun tò si lásìkò ti òun bá Laycon jà.
Ìbéèrè ni pé, ṣe kìí ṣe àṣemọ Erica rèé ti wọ́n o fi júwe ilé fún kúrò nílé BB Naija.
BB Naija 2020: Erica ní òbùrẹwà, kìkìdá egungun ní Leycon, òun sì fẹ́ pa á

Oríṣun àwòrán, BB Naija
Orisirisi ara lo ti n waye nile BB Naija bayii, eyi to n ya ọpọ eeyan lẹnu.
Lasiko ariya alaalẹ Satide to tun waye lana ati asiko ounjẹ ni aarọ ọjọ isinmi oni, ara miran tun ti sẹlẹ.
Ni aarọ ọjọ isinmi ni awọn ololufẹ meji to gbajumọ bii isana ẹlẹẹta ninu ile naa, Vee ati Neo, tun ti da ara miran tuntun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Tinubu, yé é sọ̀rọ̀ abẹ́lẹ̀, bọ́ sí gbangba láti bèèrè àtúntò Nàíjíríà lọ́dọ̀ Buhari - Afẹnifẹrẹ
- Wo àànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Wo àwọn ìlànà tuntun ti o gbọdọ tẹlèé rèé ki ó to le wọkọ̀ òfurufú lọ sókè òkun
- Ìdí ti mo fi da sọ́ọ̀sì rú lásìkò ìgbéyàwó ìyáwó mi tó ló fẹ́ ọkọ míran- Osadebe
- Àwòráń ọdún Ashura àwọn ẹlẹ́sìn Shiite tí ọ̀pọ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lórí ayélujára
- Risikat olójú búlù dí aya Wasiu ní ìlànà Islam, tẹbí tará péjú síbẹ̀
- Ó ń bọ̀ lọ́nà! Odunlade Adekola, Femi Adebayo, Jenifa ṣi aṣọ lójú àwọn fíìmù tuntun tẹ́ẹ ti ń retí
- Ìdí ti mo fi da sọ́ọ̀sì rú lásìkò ìgbéyàwó ìyáwó mi tó ló fẹ́ ọkọ míran- Osadebe
Niwaju gbogbo awọn olugbe BB Naijia si ni Neo, ẹni ti ifẹ Vee n pa bii ọti, ti kede pe o di dandan ki oun fun ọmọbinrin naa loyun, ki awọn to setan ninu ile naa.
Gẹgẹ bo se wi, "Chai, mo gbọdọ fun ọ loyun.", ti gbogbo awọn eeyan to wa nibẹ si ku silẹ fun ẹrin arintakiti.

Oríṣun àwòrán, BB Naija
Neo, wa sọ fun Nengi, Kiddwaya, Trikytee ati Vee bi inu oun se dun to lati bawọn kopa ninu eto BB Naija tọdun yii.
"Inu mi dun lati pade wọn ọrẹ tuntun lori eto yii, ti agbega si ba igbe aye mi, bakan naa ni mo di gbajumọ lawujọ."
Amọ sa, Neo, tii se ẹya Urhobo wa n fi ika hanu pe o seese ki oun sọ awọn ọrẹ oun naa nu, to fi mọ ololufẹ oun, Vee, ti wọn ba le oun lọ sile lonii.
Lalẹ oni si laa mọ ẹni ti yoo jade kuro ninu ile ẹlẹkọ agba.
Wayi o, inu buruku ti bi Erica ninu ile BB Naija to si sọ kobakungbe ọrọ si akẹẹgbẹ rẹ, Laycon, ẹni to se apejuwe bii oburẹwa ẹda.

Oríṣun àwòrán, Erica Leycon Instagram
Erica, tii se olori ile lọwọ lọwọ ni ihuwasi rẹ yii ya awọn akẹẹgbẹ rẹ to wa ninu ile naa lẹnu, paapaa lori ojo eebu ati abuku to n rọ sori Laycon.
Lemọ lemọ si ni Erica, to han pe o ti mu ọti yo, n sọ pe oponu ati oburẹwa to jẹ kikida egungun , ti ko mu agbega kankan ba inu ile naa ni Leycon.
Ọrọ yii ti n mu awuyewuye dani lori ayelujara, ti ọpọ eeyan si koro oju si ihuwasi Erica naa, lẹyin ariya alẹ ọjọ Satide.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Erica lo n binu lori bi ọpọ eeyan se gba pe oun fi ẹnu ko Leycon lẹnu, to si lọ ba ọmọkunrin naa pe ko mu ẹri to ba ni wa lati fi idi rẹ mulẹ pe awọn fi ẹnu konu.
Ọrọ yii si lo bii ninu to bẹẹ, to fi ni oun lee pa Leycon, nitori isẹlẹ to n ja nilẹ naa.















