Ifetedo FC: Ọ̀rẹ́ olóògbé ní Damilola kò sàìsàn, ó ń gbá bọ́ọ̀lu lọ́wọ́ ló kú

Oríṣun àwòrán, @bridgeradio987
Ọmọ ẹgbẹ agbábọ́ọ̀lù kan ni ìpińlẹ̀ Osun ti wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ni Damilola, ló dédé subu lulẹ̀, tó sì kú ni àsìkò tó wà lórí pápá ni àgbègbè Ido ni ìpínlẹ̀ náà.
Gẹ́gẹ́ bi àwọn ti ọ̀rọ̀ náà sójú wọ́n ṣe sọ, wọ́n lo n gbá bọ́ọ̀lù fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀, Premier Football Club, Ofetedo lọ́wọ́, ló bá subú.
Ìròyìn sọ pé ni kété ti ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ti gbé ọmọkurin òun lọ si ilé ìwòsàn aládani kan fún ìtọ́jú.
"ilé ìwòsàn náà kò gbà á, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún rù ú lọ si LAUTECH, ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ fún wọ́n pé, ó ti jẹ́ Ọlọrún nípè.
Ipele ifẹsẹwọnsẹ keji lo ti fẹ́ gbá bọ́ọ̀lu wòmí n gbá a-sí -ọ, amọ se lo kan sùbu, ti kò sì dìde mọ́.
"Kò fi àmì kankan hàn pé ó ṣe àìsàn rárá. Gbogbo ìgbà ló máa n gbá bọ̀ọ́lu fún ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù rẹ̀," gẹ́gẹ́ bi ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe sọ.
Wọ́n ti sin olóògbé náà nilu Ido Osun lọ́jọ́ ìṣẹ́gun.
Akiyesi Pataki: Àwòrán tí a lo tẹ́lẹ̀ to je ti egbe agbaboolu Knight FC kò ní í ṣe pẹ̀lú ìròyìn yìí.













