Baba Legba: Foluke Daramola ní òun kò ní gbàgbé àdúrà òwúrọ̀ tó máa ń gbà fún òun

Gomina ẹgbẹ TAMPAN ni ipinlẹ Ogun, Owolabi Ajasa ti ṣapejuwe Baba Lẹgba to di oloogbe, gẹgẹ bi baba awọn oṣere nigba aye rẹ to ko awọn eniyan mora.
Ajasa ni, baba ni Baba Lẹgba jẹ fun wọn nigba to wa laye, to si tun jẹ awokọṣe iwa ọmọluwabi laarin wọn, to si ma n gba wọn nimọran.
O ni bi o tilẹ jẹ pe oloogbe naa kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣere TAMPAN nigba aye rẹ, to jẹ wi pe ọmọ ẹgbẹ ANTP ni, sibẹ o sunmọ gbogbo awọn oṣere.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Tí mo bá kú lónìí, Pásítọ̀ Ibiyeomie ló pa mi - Daddy Freeze kébòòsí
- Àwọn afurasí lórí ẹ̀ṣùn jíjí ìbejì Akeugbagold gbé yọnú sílé ẹjọ́ láì ní agbẹjọ́rò
- Mo kábàámọ̀ pé ń kò bẹ Baba Legba wò, nígbà tó pè mí - Foluke Daramola
- Aṣòfin méje yarí mọ́ Akeredolu lọ́wọ́ torí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí kò pín fún wọn
- Aya gómìnà Kwara gba ilé fún Risikat olójú búlúù àti ọkọ rẹ̀
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
- Àjọ ECOWAS yan Aàrẹ Ghana, Nana Akufo-Addo gẹgẹ bíi aàrẹ tuntun
"Gbogbo ohun ti a ba fẹ, lo maa n ṣe fun wa nigba to wa laye, a si ṣe ojuṣe wa fun nigba to dubulẹ aisan, ki o to di wi pe o doloogbe.

Oríṣun àwòrán, Others
Aisan to rọmọ ọjọ ogbo lo ṣe Baba legba to fi papoda, amọ, ede aiyede to ṣẹlẹ laarin ẹgbẹ TAMPAN ati ANTP, lo mu ka maṣe pe oloogbe naa si iṣẹ pẹlu aisan to ṣe wọn."
Owolabi Ajasa fikun pe aisan Baba legba tun peleke si ni ọdun to kọja, sugbọn oun maa n pe oloogbe naa si iṣẹ.
Ninu ọrọ tirẹ, gbajugbaja oṣere Yoruba, Foluke Daramọla Salako ṣe apejuwe Baba Lẹgba gẹgẹ bi ẹni to ni imọ ati oye nipa oṣere, to si kun fun ọgbọn.

Oríṣun àwòrán, Others
Foluke Daramọla ni ohun manigbagbe ti oloogbe naa ṣe fun oun ni adura to maa n gba fun oun ni araarọ, to ba ti pe oun lori aago.
"Itoju ti ẹgbẹ TAMPAN n ṣe fun awọn agbalagba to wa ninu ẹgbẹ oṣere lo mu mi mọ Baba Lẹgba.
Amọ, ọdun to kọja ni aisan asetọ taa mọ si prostate mu, eyi to ṣekupa nitori ọjọ ogbo rẹ."
Bakan naa lo pe oun yoo ṣe idaro Baba Legba nitori ipa ribiribi to n ko ninu fiimu nigba aye rẹ.
Mo kábàámọ̀ pé ń kò bẹ Baba Legba wò, nígbà tó pè mí - Foluke Daramola
Ilumọọka osere tiata lobinrin, Foluke Daramola Salako ti n gbarata lori iku to mu agba ọjẹ osere tiata miran, Alhaji Yekeen Omobolanle lọ.
Ọjọ Aje ni iroyin iku agba ọjẹ ninu isẹ tiata naa gbalẹ kan, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Baba Legba.

Oríṣun àwòrán, Others
Nigba to n kẹdun iku to mu akikanju osere naalọ, Foluke sọ loju opo Instagram rẹ pe kii dun mọ oun ninu lati ri ki awọn agba osere maa jade laye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Aṣòfin méje yarí mọ́ Akeredolu lọ́wọ́ torí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí kò pín fún wọn
- Aya gómìnà Kwara gba ilé fún Risikat olójú búlúù àti ọkọ rẹ̀
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
- Àwọn ọ̀daràn tó jí ìbejì ọmọ Akeugbagold kó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lòníì
- Àjọ ECOWAS yan Aàrẹ Ghana, Nana Akufo-Addo gẹgẹ bíi aàrẹ tuntun
- Àrà mánigbàgbé tí Baba Legba dá lágbo tíátà rèé
Foluke to ni lootọ ni baba naa dagba, ti oun si ba sọrọ lọsẹ to kọja sugbọn ọwọ mi di pupọ nile ounjẹ ti oun da silẹ lati bẹ ẹ wo.
"Ọwọ mi di lati lọ bẹ ẹ wo gẹgẹ bi mo se maa n se nitori o sọ fun mi pe oju ọjọ taa wa yii tutu fun oun.

Oríṣun àwòrán, Others
O dun mi pe n ko le ni anfaani lati juwọ si pe o digbose ko to gbẹmi mi, o si se ni laanu pe a padanu rẹ."
Foluke fikun pe "mo da ara mi lẹbi pe n ko lọ bẹ Baba Legba wo nigba to pe mi, ams sa, o dara, Sun re o, Baba."
Wọn ti sin oloogbe naa nilana ẹsin Musulumi lọjọ Aje.
Àrà mánigbàgbé tí Baba Legba dá lágbo tíátà rèé
Ikudoro, iku ti sika, iku ti mu gbajumọ agba ọjẹ ninu isẹ tiata miran lọ.
Oluwa rẹ ni Alhaji Yekeen Omobolanle ti ọpọ eeyan mọ si Baba Lẹgba.
Baba Lẹgba lo maa n sere awada pẹlu baba Sala laye ọjọsi, ki agba to de.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Fìdíhẹẹ́ ní Banji Akintoye nínú YWC, lílọ ni yóò lọ - Tola Adeniyi
- A kò sí lára àwọn tó ń ṣèwọ́de tako èlé owó epo àti iná ọba - NLC
- Jàńdùkú olóṣèlú gbàkóso ilé aṣòfin l‘Ondo
- Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan
- Eruku ìjà sọ lálá lórí ayelujára láàrin Oyedepo àti Daddy Freeze
- Ọmọ Nàíjíríà kó N6m jọ lórí ayélujára fún Erica tí wọn lé ní BB Naija
- Mo fòpin sí àjẹbánu lórí owó ìrànwọ́ epo àti iná ọba, ní èlé ṣe wáyé - Buhari
Agba ọjẹ osere tiata naa lo jade laye nile rẹ to wa nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun nirọlẹ ọjọ Aiku.
Nigba to n fidi isẹlẹ iku oloogbe naa mulẹ fun BBC Yoruba, gbajumọ osere tiata miran, Ebun Oloyede, ti ọpọ eeyan mọ si Olaiya Igwe ni lootọ ni baba naa ti lọ.
Irọlẹ oni ọjọ Aje si ni wọn yoo fi iyoku ara Baba Legba fun ilẹ nile rẹ nilu Abeokuta nilana ẹsin Musulumi.

Oríṣun àwòrán, Others
Ọdun 1974 ni Baba Legba dara pọ mọ ikọ osere tiata Awada kerikeri labẹ akoso Moses Olaiya, taa mọ si Baba Sala.
Nigba miran, Baba Legba tun maa n ba awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu isẹ tiata sere itage, awọn bii Bolaji Amusan taa mọ si Mr Latin ati Segun Ogungbe.
Gẹgẹ bi ọmọ Baba Sala to kede iku oloogbe naa loju opo Facebook rẹ, Adejumọ Boisala Emmanuel ti wi, Baba Lẹgba maa n se babalawo ninu ere tabi ọlọpaa.
Sugbọn o ni lọpọ igba, alawada ni oloogbe naa ati baba Sala saba maa n se ninu ere.
Adejumọ fikun pe Sunday Omobolanle ni baba naa n jẹ tẹlẹ, ko to lọ si Mecca, to si yi orukọ rẹ pada si Yekeen.
O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa safẹfẹ rere.














