Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan

Àkọlé fídíò, Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan

Ọmọ ọdun mẹwa ati akẹkọọ kilaasi kẹta nile iwe alakọbẹrẹ ni Temitope Akinnusi nigba ti isẹlẹ kan waye eyi to mu oju osi rẹ lọ lọdun 2003.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Temitopẹ ni awọn adigunjale to wa sile awọn lasiko ti baba oun ko si nile lo sokunfa ijamba naa.

O ni wọn fẹ fi tipa ba iya oun lopọ, ti oun si tako wọn, ni wọn ba fi idi ibọn fọ oun loju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkunrin naa, ni oun koju ọpọ ipenija nile iwe lati ọdọ akẹẹgbẹ oun amọ eyi ko di oun lọwọ lati kawe jade titi de ile ẹkọ fasiti.

Amọ idẹyẹsi naa ko tun jẹ ko fi iwe ẹri fasiti rẹ sisẹ lawọn ileesẹ nlanla nitori ọpọ wọn lo taku pe awọn ko le gba oloju kan sẹnu isẹ.

Lọwọ lọwọ bayii, Temitope Akinnusi wa lara awọn akọsẹmọsẹ ati gbajumọ ayaworan nipinlẹ Ondo pẹlu oju kan soso to ni.

O wa n parọwa sawọn eeyan to ni ipenija kan abi omiran lati mase ro ara wọn pin nitori bi ẹmi ba si wa, ireti n bẹ.