Ibrahim Chatta: Ó gba àwọn òṣèré tíátà nímọ̀ràn láti máa ṣaájò ẹgbẹ́ wọn

Ibrahim Chatta

Oríṣun àwòrán, ibrahimchatta_lordthespis

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ilumọọka osere tiata, Ibrahim Chatta ti dupẹ lọwọ gbogbo awn eeyan to se aajo rẹ lori aworan to gbe soju opo Instagram rẹ lọjọ Abamẹta.

Ninu aworan naa ni Chatta ti wa lori ibusun, ti wọn n fa omi ati oogun si lara.

Ọpọ eeyan lo ro pe o n se aisan lo se wa nile iwosan lai mọ pe ere sinima lasan ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba to n fesi lori aworan naa, ati bi ọpọ eeyan se fi ifẹ han si, Chatta ni aworan naa lo fara jọ owe to ni " Ẹ́ jẹ́ ka diju, ka se bi ẹni to ku, ka wo ẹni ti yoo sunkun ẹni."

O wa dupẹ pupọ lọwọ awọn ololufẹ rẹ ti wọn pe, tabi gbadura fun nigba ti wọn ri aworan hun, o ni awọn naa ko ni se aisan.

Bimbọ Oshin n toju Ibrahim Chatta nile iwosan

Oríṣun àwòrán, bimbooshin

Bakan naa lo fi ohun ransẹ si awọn akẹẹgbẹ rẹ ti wọn dijọ n sisẹ tiata pe ki wọn maa sugba akẹẹgbẹ wọn to ba gbe iru aworan bayii sita, ki wn si wadii boya ere ni ọrọ naa abi otitọ.

Agba osere tiata naa ni "Ti onitiata yoo fi ku, ere lasan ni wọn yoo ro pe o n se."

Ki lo gbe Ibrahim Chatta dele iwosan?

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe isẹlẹ aramanda to n waye lori ayelujara lọwọ lọwọ bayii ni ti aworan kan ti gbajugbaja osere tiata, Ibrahim Chatta fi soju opo Twitter rẹ.

Idi si ree ti ọpọ ọmọ Naijiria fi ń beere pe ki lo ṣe agba oṣere Ibrahim Chatta, to fi dùbúlẹ̀ lóri ìbùsùn nilé ìwòsàn.

Nollywood Yoruba: Kíló ṣe Ibrahim Chatta to fi dèrò ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Chatta/Instagram

Nínú àwòràn tó gbé sójú opo instagram rẹ lọjọ Abamẹta, a ri ti ó sùn si orí ibùsùn, tí wọ́n si fa gbogbo oníruuru ọkun àti omi síi lára, gẹgẹ bi wọn se maa n se fawọn alaisan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ibrahim Chatta, to maa n se ere adẹrinposonu nigba miran, lo kọ akọle kan sabẹ aworan naa, to ni "Stay Safe".

Eyi si lo tumọ si pe ẹ maa gbe ni ailewu.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Irísí agba osere tiata naa jọ ti ẹni to ṣe àìsàn sùgbọ́n ọrọ ti awọn akẹẹgbẹ kan kọ sabẹ aworan ọhun mu ifura dani.

Idi ni pe, bi àwọn kan ṣe n ki pe Ọlọ́run yoo fun ara rẹ lokun, ni awọn míràn ń fi àwòràn náà dápárá, eyi to mu ifura lọwọ pe abi inu ere itage lo ti ya aworan naa.

Ibrahim ni inu oun dun pe awọn ololufẹ oun pe oun lati mọ ohun to n sẹlẹ, to fi mọ aafin Oyo, to si n bu awọn akẹẹgbẹ rẹ ti ko wa ẹyin rẹ wo lati mọ boya ootọ lo wa lori akete aisan abi bẹẹ kọ.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Chatta ni "Ẹ́ jẹ́ ka maa wẹyin ara wa wo lati mọ ohun to n sẹlẹ nitori ti onitiata yoo ba fi ku, ere lasan ni wọn yoo ro pe o n se."

O wa gbadura pe, gbogbo ẹni to fi adura ransẹ si oun, titi to fi de aafin Oyo lọdọ Alaafin, aye gbogbo wọn ko ni bajẹ.

Gbajumọ osere naa ni lẹyin ti oun fi aworan naa sori ayelujara ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ oun ku, tawọn eeyan ko si le kan si oun, eyi to mu ki ibẹru gba ọkan wọn.

O wa sisọ loju rẹ pe, inu ere tiata ni oun ti ya fọto naa nile iwosan, ko ko ko si ni ara oun le.

Yollywood: Toyin Abraham ṣe àjọ̀dún ogójì ọdún, èyí láwọn mánigbàgbé ìrìnàjò ayé rẹ

toyin abraham

Oríṣun àwòrán, Instagram/toyin abraham

Gbajugbaja oṣere sinima Yoruba, Toyin Abraham ti ṣe ọjọ ibi ogoji ọdun laye.

Ninu ọrọ kan to fi sita loju opo twitter rẹ @toyin_abraham1 kede pe ogoji ọdun ohun pe oun o si yọnu.

Toyin Abraham wa lara awọn eekan elere sinima taraye n wari fun julọ lori ayelujara.

Ilu Auchi ni wọn ti bi Toyin Abraham ni ogoji ọdun sẹyin ṣugbọn ilu Ibadan lo ti lo ibẹrẹ aye rẹ.

O lọ si ileewe gbogboniṣe poly ipinlẹ Ọṣun to wa nilu Iree ki o to kọri si ileewe gbogboniṣe Polytechnic Ibadan

Eyi ni ohun marun un to duro laaye ọtọ laarin ogoji ọdun ti Toyin Abraham ti pe laye

toyin abraham

Oríṣun àwòrán, Instagram/toyin abraham

Ọdun 2003 lo bẹrẹ iṣẹ sinima

Ọdun 2003 lo bẹrẹ iṣẹ sinima lasiko ti Bukky Wright lọ ya iṣẹ sinima kan nilu Ibadan.

Lati igba naa wa lo ti di alekun-alekun fun un lagbo awọn oṣere sinima titi kan eyi to gbe jade gbẹyin, Elevator Bab.

Oniruuru ami ẹyẹ lo si ti gba pẹlu titi kan ami ẹyẹ awọn elere sinima agbelewo ni Afirika iyẹn, AMVCA lọdun 2019.

toyin abraham

Oríṣun àwòrán, others

'Mo lee ku tori Goodluck Jonathan.'

Nitori pe o jẹ gbajugbaja oṣere, ọpọ igba lawọn oloṣelu ti pe Toyin Abraham pe ko wa fi epo ati ata si ipejọpọ ipolongo idibo wọn.

Ninu ọkan lara ipe ipejọpọ bẹẹ ti wọn pee fun lasiko ipolongo ibo fun Goodluck Jonathan to fẹ dije fun ipo aarẹ lẹẹkeji lọdun 2015 ni Toyin ti sọ pe oun lee ku nitori ẹgbẹ oṣelu PDP.

Eleyii fa ọpọlọpọ awuyewuye ati ariwo nigba naa. Toyin pada wa tuuba fun awọn ololufẹ rẹto si rọ wọn pe ki wọn maa ṣe ta ẹjọ silẹ nitori oloṣelu kankan.

Toyin Abraham ati Adeniyi Johnson

Oríṣun àwòrán, others

Igbeyawo rẹ akọkọ foriṣanpọn

Ni ọdun 2013 ni Toyin kọkọ ṣe igbeyawo. Oṣere ẹgbẹ rẹ, Adeniyi Johnson to pade lọdun 2012 lo fẹ.

Igbeyawo naa la ọpọlọpọ iji kọja to jẹ pe bi wọn ṣe n ja ni wọn n pari rẹ ki o to di pe wọn kuku ja ajatuka lẹyin lẹyin ọdun diẹ, iyẹn lọdun 2017.

toyin abraham

Oríṣun àwòrán, Instagram/toyin abraham

Toyin yi orukọ pada

Ni igba to wọ agbo ere sinima, Toyin Aimakhu ni gbogbo eeyan mọ ọmọge Alakada si.

Amọṣa nigba to di ọdun 2016 ni iroyin jade pe Toyin fẹ yi orukọ rẹ pada.

Toyin funra rẹ lo wa kede pe oun ti pa orukọ da kuro ni Toyin Aimakhu bayii ohun ti di Toyin Abraham.

Nigba ti wọn bii pe ki lo fa idi eyi, ohun ti Toyin Abraham sọ ni pe 'ipinnu gbogbo ẹbi oun ni eyi, nitorina Toyin Abraham loun fẹ ki wọn maa pe oun" lati igba naa lọ.

toyin abraham ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/toyin abraham

Toyin ṣe igbeyawo lẹẹkeji.

Lẹyin to kọ ọkọ akọkọ silẹ, Toyin simi fun igba diẹ ki o to tun mu orin ifẹ bọnu.

Lọtẹ yii ẹwẹ, oṣere ẹgbẹ rẹ naa lo tun fẹ.

Ọgbẹni Kọlawọle Ajeyẹmi ni o fẹ ni Oṣu kẹjọ ọdun 2019 lẹyin ti Toyin funrarẹ sọ ọ ninu ifọrọwerọ kan pe ọdun 2017 lawọn pade

Awọn mejeeji si ti n tamige ifẹ lati igba yii wa ti eleduwa si ti fi ọmọ ọkunrin, Ire, ta wọn lọrẹ.

Allwell

Oríṣun àwòrán, @allwell

Ṣaaju lọsẹ yii ni Ademola Allwell naa ti sọrọ lori ọjọ ibi rẹ pe:

Ìdí tí mo fi ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí 35 lọ́dọọdún rèé- Allwell Ademola

Gbajugbaja oṣere to tun n kọrin ni Allwell Ademola ni ọpọ eeyan n sọrọ lori ayelujara latari ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlogoji lọdọọdun.

Lati bii ọdun mẹrin sẹyin lo ti n ṣe ayẹyẹ ọdun yii laipaarọ iye ọjọ ori rẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin kan ni ilu Eko ni Allwell ti ṣalaye pe ko si ohun to buru ninu pe oun n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlogoji lọdọọdun.

Allwell ni oun kan n se oun to n mu oun dabi ọdọ sii lọdọọdun ni ati pe iyẹn ko sọ pe ẹni ọdun marundinlogoji ṣi ni oun rara.

O fi imoore han si Olorun pe oun ṣi wa laye lasiko ajakalẹ arun Covid 19 yii.

O ni eyi ko sọ pe ọdun ohun ko yi pada ati pe o yẹ ki awọn eeyan mọ pe awada lati mu inu ara oun dun lo n jẹ ki oun ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun naa nigba gbogbo.

Àkọlé fídíò, Mr Macaroni sọ nípa eré tí Fraky freaky, Sugar Daddy, You are doing well, freaky spicy fẹ́

Oṣere Allwell Ademola ni oun gbadura pe ọkan awọn oṣere ẹgbẹ oun a tubọ balẹ.

Ati pe ki Olorun mu inu oun dun sii ṣaaju ayẹyẹ ọjọ ibi oun lọdun to m bọ.

Allwell Ademola

Oríṣun àwòrán, @All well

Bí ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood lọ́sẹ̀ yìí rèé

Bi ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood Lọ́sẹ̀ yìí rèé

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Eyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn fótò ti Funke Akindele Bello ló láti fi sọ fún àwọn ọmọ Naijiara pé òun tún n pada bọ̀

Nollywood Round Up: Bí ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood lọ́sẹ̀ yìí rèé

Oníruuru àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lo ti wáye láàrín ọ̀ṣẹ̀ yiìí lágbo òṣèré Nollywood.

Nollywood Round Up: Bi ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood Lọ́sẹ̀ yìí rèé

Oríṣun àwòrán, oTHERS

Àkọlé àwòrán, Ọ̀kan lára àwọn fóto àwòtúnwo tó fisíta rèé fun ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀.

Funke Akindele-Bello gbe nkan mẹta ṣe lẹẹkanṣoṣo

Ní ilé gbájúgbàja òṣèré Funke Akindele Bello ti gbogbo ènìyàn mọ sí "Jennifa" ohun mẹtalọkan lo jẹyọ níbẹ̀.

Bí ó ṣe n ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ibi ló n ṣe ajọdun igbéyawo bákan náà lo tún fi yé àwọn ọlólùfẹ́ rẹ pe wọn kú afojusọ́nà, sinima agbélewo rẹ̀ túntun to n bọ.

Nollywood Round Up: Bi ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood Lọ́sẹ̀ yìí rèé

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Fótó ìgbéyàwó yii ni Funke kọ́ka gbésíta ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí.

Iròyìn tó tó wa léti ni pé, gbájúgbajà òṣèré náà ń pinu láti tún gbé atunṣe eré míràn jáde lára ọ̀kan lárá èyí to ṣe tẹ́lẹ to fi di ìlúmọ̀ọ́ká.

Bi ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood Lọ́sẹ̀ yìí rèé

Oríṣun àwòrán, MO_Adebimpe/instagram

Àkọlé àwòrán, Tọkọtaya ori ayelujara

Lateef Adedimeji àti Adebimoe Oyebade

Lọ́sẹ̀ yìí bákan náà àwọn tọ́kọtiyawó orí ayéluujara tí wọ́n dá awuyewuye silẹ́ lọ́jọsi lórí asọ igbéyawo ti wọ́n wọ̀ papọ tún ti gbe òmíràn yọ.

Gẹ́gẹ́ bi ìṣe wọ́n àwọn méjèèjì tún wọ ànkoo bii tọkọtiyàwò ti wọ́n sí fọ́n fóto wọ́n ka sórí ayelujara bi ina wẹ́dà.

Àkọlé fídíò, Wo bí Sunday Orimola ṣe gba ikú ẹranko kú ní Ifon ni Ondo lórí ọ̀nà àtijẹ

Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria lo tún ti wa n bere bayii pé, ṣe tọkọtaya ni awọn méjeeji lootọ ni?

Sùgbọ́n gẹ́gẹ́ bi ǹkan ti ọgbẹ̀ni Adedimeji sọ, ó ni gbígba àdúra ni ńkan ti àwọn ènìyàn ń rí tori ìpólówó ọja ni àwọn ń se.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'
Bi ó ṣe lọ lágbo àwọn òṣèré Yollywood Lọ́sẹ̀ yìí rèé

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, awọn gbajgbaja osere naa ree

Lágbo òṣèré bákan náà nínú ọ̀sẹ yiìí ni àwọn àwọn àgbáríjọ àwọn oṣerẹ agbálewò ti kìí ṣe ti Yoruba níkan ti ko àrawọn jọ.

Wọ́n sì ni ki gbogbo ènìyàn maa fójú sónà láti mọ idí abaájọ ńkan ti àwọn fẹ́ ṣe.

Àkọlé fídíò, Nollywood stars: Àwọn èèkàn òṣèré sinimá ní Nàìjíríà jẹ́wọ́ ara wọn lórí fífi ohùn àmì

Gẹ́gẹ́ bi Yomi Fabiyi to jẹ ọ̀kan gbòógi lara awọn òṣere Nollywood Yoruba ṣe sọ, ó ni láìpẹ́ yii àwọn yoo ṣe àtẹjáde àti èrèdí ti àwọn fi darapọ̀ síta ninu fọto.

Àwọn to péjọ náà ni:

OGE OKOYE

MUTIU ADEPOJU

YEMI sOLADE

ARALOLA OLAMUYIWA

Àkọlé fídíò, Jude Chukwuka: Wọ́n yóò fi ojú ọlọgbọ́n wo akúrí tó bá sọ ojúlówó èdè Yorùbá

Awọn miran ni:

SAHEED MUHAMMED (FUNKY MALLAM)

YOMI FABIYI

KEMI AFOLABI ADESIPE

Àkọlé fídíò, Natalia Mufuta ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ

STEPHEN UGOCHUKWU (RUGGEDMAN)

MURPHY AFOLABI

FOLUKE DARAMOLA

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase