AAUA latest news: Kìí ṣe àkókò yìí ló yẹ kí Akeredolu dín owó ilé ìwé kù, ìbò ló ń fẹ̀ - òbí àti Akẹ́kọ́ọ̀ AAUA

Oríṣun àwòrán, AAUN News Forum
- Author, Olumide Owaduge
- Role, BBC Yoruba, Lagos
Awọn obi kan ati akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin, AAUA, to wa ni Akungba-Akoko ni ipinlẹ Ondo ti bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ naa lẹyin to ṣadinku iye owo ile iwe ọhun.
Awọn obi ati akẹkọọ ọhun ni kii ṣe pe ijọba, labẹ iṣakoso gomina Oluwarotimi Akeredolu, fẹran ara ilu lo jẹ ko din owo ile iwe naa ku, bi ko ṣe ọgbọn alumọkọrọyi lati jẹ ki awọn eeyan dibo fun un fun saa keji.
Inu atẹjade kan to fi ṣowọ si awọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ ni ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe oun ti ṣadinku si iye owo ile iwe naa lẹyin ti ọrọ aje dẹnu kọlẹ nitori ọwọja ajakalẹ arun Coronavirus.
Ṣugbọn awọn eeyan ti fesi pe eto oṣẹlu ni gbogbo rẹ jẹ, ati pe ko si iyatọ kan gboogi laarin iye owo ti wọn n ṣo tẹlẹ ati eyii ti wọn yọ kuro ninu rẹ.
Arabinrin Olayinka Olatunji to jẹ obi sọ fun BBC pe "Ko si obi to fẹ ki ọmọ oun maa jiya lai lọ si ileewe, ṣugbọn iye owo ile iwe ti wọn n san ni AAUA yẹn ti pọ ju."
Ni ti iye ti ijọba yọ kuro ninu owo ile ọhun arabinrin naa ni "Ko si iyatọ ninu iye ti ijọba yọ kuro ninu owo ile iwe naa ati iye ti wọn n san tẹlẹ.
- Ipò kíní ré sórí ìpínlẹ̀ Plateau! Èèyàn 296 ló forí kó Covid -19 ní Nàìjíríà lọ́jọ́bọ
- Wo ojú àwọn afurasí tó fipá bá Uwaila, akẹ́kọ̀ọ́ Uniben sùn tí wọ́n tún pa á sínúu ṣọ́ọ̀ṣì
- Kìí ṣe torí ìbèérè ni mo ṣe bẹ́ Fani-Kayode, àwọn akẹẹgbẹ́ mi ló kó mi láyà jẹ - Eyo Charles
- Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ tí ìrìnàjò bàálù sílẹ̀ òkèèrè yóò bẹ̀rẹ̀ padà síwájú
O tẹsiwaju pe "Kii ṣe pe Akeredolu fẹran ara ilu to bẹẹ lo jẹ ko din owo ile iwe wọn ku, ṣugbọn o jẹ nitori pe o n fẹ ki wọn dibo gbe oun wọle sipo gomina lẹẹkeji ni."
Grace Akinbiyi to jẹ akẹkọọ ni fasiti naa sọ fun BBC pe ijọba ko tilẹ ṣadinku iye owo ti wọn n san ni ẹka ẹkọ oun.

Oríṣun àwòrán, AAUA
Akinbiyi ni "ko si iyatọ laarin iye owo ti a n sọ tẹlẹ si iye ti wọn ni wọn yọ kuro, fun apẹrẹ, ₦150,000 ni awọn akẹkọọ imọ ofin n san tẹlẹ, iye kan naa ni wọn ṣi maa san bayii, ki wa ni iyatọ to wa nibẹ?"
O tẹsiwaju pe ti ijọba ba fẹ ṣadinku iye owo ile iwe ni tootọ, ko yẹ ki adinkun naa din ni ida aadọta.
Akẹkọọ ọhun pari ọrọ rẹ pe oun ko ni igbagbọ ninu gomina Akeredolu nitori akoko to din owo ile iwe ọhun bo si asiko ti eto idibo sunmọ etile.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni ijọba ipinlẹ Ondo kede adinku owo ile iwe naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun naira.
Gbogbo akititayan ileeṣẹ BBC lati ba ijọba sọrọ lori awuyewuye adinku owo ile iwe ọhun lo ja si pabo.
Ọdun 2018 ni ijọba Akeredolu ṣafikun iye owo ile iwe naa, eyii to fa awuyewuye ti awọn akẹkọọ naa si gunle iwọde pe ki ijọba da owo ile iwe naa pada si iye to wa tẹlẹ.
Ṣugbọn lẹyin gbogbo iwọde ọhun, ijọba kọ lati ṣe ohun ti wọn n fẹ.














