Chief Kanran: Ilé jóná, ọkọ̀ mẹ́rin pòórá, inú ṣọ́ọ̀ṣì ni mò ń sún láì nílé lórí

Chief Kanran

Oríṣun àwòrán, others

Gbajugbaja osere tiata kan, Segun Remi, ti ọpọ eeyan mọ si Chief Kanran ti kesi araye pe nnkan n ṣe oun.

Kanran, ẹni to ke gbajare bẹẹ lori eto redio kan nilu Ibadan, lo n ṣe omije loju poroporo lasiko eto naa.

Kanran, to maa n ṣe bii olowo ati Oloye ninu sinima, lo salaye fun awọn ololufẹ rẹ lori eto naa pe o ti to ọdun meje bayii, ti laluri aye ti de ba oun.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Kanran ni "ile mi lo kọkọ jona lati oke delẹ pẹlu gbogbo dukia ti mo fi ọpọ ọdun ṣíṣẹ fun, ti iyawo ati awọn ọmọ si sa fun mi."

O fikun pe, ọpọlọpọ isoro yii ni ko jẹ kawọn eeyan rí oun ninu sinima mọ nitori ohun gbogbo to dagun fun oun.

Chief Kanran

Oríṣun àwòrán, others

"Alaanu dide fún mi lasiko naa, bii Mama Esther Ajayi ati Oloye Bola Tinubu, ti wọn dide iranlọwọ fun mi, eyi to kọja ero temi gan funra mi."

" Amọ nigba to di ọdun meji ṣẹyin, gbogbo studio mi ta ti n ya fiimu tun jona."

Kanran, tii ṣe gbajumọ ọmọ ìjọ Kerubu ati Serafu ni lọwọ lọwọ bayii, lati bii ọdun kan aabọ, inu ṣọọṣi ni oun n sun, ti oun ko si lowo lọwọ lati haya ilegbe.

O fikun pe" atijẹ, atimu ti di ọ̀ràn fun mi, ti n ko si ru, bi mo ṣe sanra síbẹ̀ naa ni mo sanra. "

Ko tan síbẹ̀ ó, Kanran tẹsiwaju pe gbogbo ọkọ ayọkẹlẹ bii mẹrin ti oun ni lo ti dẹnu kọlẹ bayii.

" Awọn mọto mẹrin ti mo ní, ninu eyi taa ti ri Sienna, Pathfinder, ko si ikankan mọ. Eyi to bajẹ bajẹ, nigba ti mo ta omiran jẹun.

Àkọlé fídíò, 'Ní ìjọ wa, ọtí mímú la fi ń pe ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀'

Segun Remi ni ọpọlọpọ eeyan kii fẹ saanu fawọn gbajumọ oṣere tiata lai jẹ pe wọn saisan, amọ o wa n bẹbẹ pẹlu omije pe ki awọn eeyan saanu oun, ki oun le bọ ninu ajaga naa.

"Ẹyin eeyan wa nile, ko yẹ ki n wa laye asan, ẹ ran mi lọwọ, ki isẹ mi dìde, ẹ ma jẹ ki n ku sinu ipo òsì yii, ẹ dakun ẹ ran mi lọwọ."

Àkọlé fídíò, 'ìjà ṣẹlẹ̀ láàrín èmi àti ọ̀gá mi ní Lebanon tórí mi ò lè dá N300K padà'