NURTW: Àwọn òṣìṣẹ́ Task Force àtàwọn awakọ̀ Danfo kọlu ara wọn l'Ogun, ọ̀rọ̀ di bóòlọ, o yàgò

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic
Awọn awakọ Danfo kan loju ọna marosẹ Eko si Abeouta daṣẹ silẹ lọsan Ọjọru eyii to fa ọpọ idamu fun awọn arinrinajo loju ọna naa.
Iroyin ni awọn oṣiṣẹ igbimọ amuṣeya to n ri si igbokegbodo oju popo ni ipinlẹ Eko, Task Force, ya bo agbegbe Abule-Egba ati Ijaiye lati ṣiṣẹ wọn, ṣugbọn awọn janduku doju ija kọ awọn osise ọhun pẹlu awọn ohun ija oloro.
Wọn ni awọn oṣiṣẹ task Force yinbọn fun ọkan lara awọn janduku ọhun ti wọn jẹ awakọ, eyii to da wahala silẹ.
- Ọlọ́pàá Funso ló fi ààyè sílẹ̀ fún mi láti sá kúrò ní àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Mokola - Sunday Shodipe
- 'A ní àrídájú, a rí àwọn ẹgbẹ́ ISIS pẹ̀lú àlùpùpù olówó ńlá, ọmọ Yoruba ẹ funra -Gani Adams
- Báwo ni obìnrin ṣe ń ní ìtura ìbálòpọ̀? Wo àbọ̀ tí ọmọba kan, obìnrin àkọ́kọ́ tó ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ gbé jáde
- Wọ́n ti yìnbọn pa afurasí apaàyàn tó ń ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun
Ija naa pọ to bẹẹ ti awọn ero ọkọ atawọn onisowo to wa lagbegbe naa ṣa asala fun ẹmi wọn.
Alaga igbimọ amuṣẹya ọhun, Yinka Egbeyemi ṣo fun ileeṣẹ iroyin abẹle kan pe, ootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ oun ko yinbọn pa ẹnikẹni lara awọn janduku naa.

Oríṣun àwòrán, @blingofnigeria
O ni "Awọn janduku kan ko ara wọn jọ ninu ọkọ akero, wọn si kọlu awọn oṣiṣẹ wa, awa naa si kọlu wọn."
"A ti fi panpẹ ofin mu awọn janduku ọhun, wọn si ti wa ni ahamọ wa."
Iṣẹlẹ naa mu ki ogunlọgọ awọn eeyan to yẹ ko wọ ọkọ fẹsẹ rin lẹyin ti awọn Danfo kọṣẹ lẹyin iṣẹlẹ naa.
Ọkan lara awọn eeyan naa, Lanre Obabiyi sọ fun awọn akọroyin pe, ẹru ba oun nigba ti oun gbọ iro ibọn ti oun si sa lọ foripamọ ninu banki kan to wa lagbgbe ọhun.
O ni oun fẹsẹ rin lati Abule-Taylor lọ si Salolo, ni Meiran.
Ẹlomiran to ba awọn akọroyin sọro Esther Bajulaye ni "Mo ti n fẹsẹ rin lati Abule Egba, mo dẹ ṣi n lọ si Tollgate, ko rọrun rara."













