MaguEFCC: Omale ni orúkọ tí Magu ń lò. àṣírí míì tú síta

Ibrahim Magu

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Igbimọ ti aarẹ Buhari gbekalẹ fun iṣewadii gbigba awọn owo ilu ti wọn lu ni ponpo pada (PCARA) ti fẹsun kan pe orukọ pasitọ ni alaga ajọ EFCC ti wọn jawe lọ sinmi fun fi na awọn owo ti wọn lọ ẹsun rẹ mọ ọ lẹsẹ loke okun.

Nibayii, Magu n koju ijẹjọ niwaju igbimọ kan ti Amofin Ayo Salami to jẹ adajọ ileẹjọ nigba kan ri kotẹmilọrun n dari.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ko fi ọwọ mimọ ṣe eto isuna awọn owo ti ajọ naa ri gba pada lọwọ awọn eeyan.

Ẹwẹ, o jade ninu abọ igbimọ PCARA to n bojuwo owo ijọba ti ajọ EFCC ri gba pada pe laarin oṣu karun ọdun 2015 si oṣu karun ọdun 2020, orukọ Emmanuel Omale to jẹ Pasitọ ijọ kan, Hand of God Prophetic Ministry ni Magu fi n ko owo jẹ.

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣe pàtàkì kí obìnrin gbádùn ìbálòpọ̀ nítorí...'

Iroyin jẹ jade pe aṣiri lilo orukọ Omale lu jade lasiko ti ẹka to n lo ọgbn ori fi ṣewadii awọn igbesẹ ajọ EFCC n ṣe iwadii wọn.

Gẹgẹ bi iroyin to jade ṣe sọ ọ, pasitọ naa ra ilẹ to to miliọnu 573 naira ni Dubai lorukọ Magu.

Wọn royin pe pasitọ ọhun rinrinajo lọ si Dubai pẹlu Ibrahim Magu ti wọn si lo orukọ rẹ lati fi ra ilẹ fun Magu ni Dubai.

"Gẹgẹ bi pasitọ ti ko gbajugbaja, iroyin fi han pe iye owo ti wọn wọ sinu asuwọn owo rẹ to N573,228,040.41".

Igbimọ PCARA fẹsun kan pe Magu ko fọwọsowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ tọrọ kan ni ilu London lati tete bẹrẹ ilana idajọ rẹ.

Bakan naa, kii ṣe ẹsun owo ti wọn lọ mọ ọ lẹsẹ nikan, wọn tun fi ẹsun kan Magu pe o mọọ mọ ma pese aridaju ti wọn nilo lati ṣe ẹjọ minisita fọr epo rọbi nigba kan ri, Diezani Madueke.

Alakoso ajọ EFCC tuntun de!

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede alakoso tuntun fun ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nilẹ wa, EFCC.

Oluwa rẹ ni Mohammed Umar, tii se oludari tẹlẹ fun eto akoso isẹ ajọ EFCC, amọ nibayii, oun ni olori patapata fun ajọ ọhun.

Atẹjade kan ti Ọmọwe Umar Jibrilu Gwandu, tii se igbakeji osisẹ alarena, nileesẹ agbẹjọro agba ati Minisita feto idajọ ilẹ wa fọwọ si lo kede iyansipo tuntun naa.

Bakan naa ni atẹjade ọhun tun kede pe, aarẹ orilẹede yii, Muhammadu Buhari ti fọwọ si pe ki adele alaga tẹlẹ fun ajọ EFCC, Ibrahim Magu lọ rọọkun nile na.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Aje ni iroyin tan kalẹ pe ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti gbe Magu, ti wọn si n fi ọrọ wa lẹnu wo.

Igba akọkọ si ree ti awọn alasẹ yoo fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin pẹlu atẹjade.

Ìhà wo gan-an ni ìjọba Nàìjíríà kọ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Ibarahim Magu?

Ibrahim Magu

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Lati ọjọ Aje ti alaga ajọ EFCC ti wọn ṣẹṣẹ gba iṣẹ lọwọ rẹ, Ibrahim Magu, ti farahan niwaju igbimọ oluwadii, ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n fẹ mọ igbesẹ ijọba lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Ọjọ Iṣẹgun si ni ijọba kede iyọnipo rẹ

Awọn onimọ kan ni Naijiria ti ẹ sọ pe , ti iwadii ba fi fidirẹmulẹ pe lootọ ni alaga ajọ EFCC, ti wsn ṣkṣẹ gba iṣẹ lọwọ rẹ, Ibrahim Magu, ba fi jẹ ootọ, pe yoo ta ẹrẹ si awọn aṣeyọri ti ijọba sọ pe oun ti ṣe lori igbagun ti iwa ibajẹ.

Aarẹ Muhammadu Buhari lo gbe igbimọ naa kalẹ lati wadii awọn ẹsun iwa ibajẹ, ati afojudi ti wọn fi kan an.

Igbimọ naa, ti Aarẹ nigba kan fun ile ẹjọ kotẹmilọrun, Ayo Salami, jẹ alaga, ranṣẹ pe Magu lati wa a sọ tẹnu rẹ nipa awọn ẹsun naa.

Ṣugbọn nkan ti o si n jẹ kayeefi si awọn ọmọ Naijiria ni pe, Aarẹ Buhari, tabi ijọba apapọ ko ti i sọ nkankan lori ọrọ Magu.

Eyi to si mu ki ọpọ o maa beere pe iha wo gan an ni ijọba Naijiria kọ si ọrọ naa.

Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe ọkan pataki ni igbogun ti iwa ibajẹ, ninu ilana iṣejọba Buhari.

Bakan naa lo jẹ pe ijọba Aarẹ Buhari naa lo yan Magu si ipo.

Ọpọlọpọ awuyewuye lo si waye lori iyansipo rẹ lati ibẹrẹ pẹpẹ. Koda, ile aṣofin agba Naijiria kọ lati bu ọwọ lu iyansipo rẹ lẹẹmeji ọtọọtọ.

Eyi ti ko ṣẹyin awọn ẹsun kan ti ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS fi kan an niwaju awọn aṣofin.

Ṣugbọn, Buhari papa yan an sipo.

Lati igba to si tun ti wa ni ipo naa, ni awọn ẹsun iwa ibajẹ ti n jẹyọ lori boṣe n dari ajọ EFCC.

Diezani, Fayose, Uzor Kalu àti awọn míì wa lára àwọn ẹjọ́ tó làmìlaaka ti EFCC ṣe lásìkò Magu

Ariṣe ni arika, arika ni baba iregun.

Oriṣiiriṣii ni awọn eeyan n ka lasiko yii nipa awọn iṣẹ maleegbagbe ti Ibrahim Magu ṣe lasiko to fi tukọ ajọ EFCC to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria.

BBC Yoruba ṣe akojọpọ diẹ lara awọn ẹsun iwa ibajẹ ti ajọ EFCC ṣagbatẹru rẹ lati igba ti Ibrahim Magu jẹ alaga ajọ naa.

EFCC fẹsun jiji owo ilu lọ silẹ okeere kan Diezani Alison-Madueke:

Ara awọn gbajugbaja ẹjọ ti ajọ EFCC ṣe lasiko ti Ibrahim Magu jẹ adele alaga ajọ naa ni ẹjọ minisita epo rọbi tẹlẹ, Diezani Alison-Madueke.

Ẹsun kiko owu ilu lọ si ilẹ okeere ni wọn fi kan Alison-Madueke pẹlu awọn eeyan mii lọdun 2018.

Owo to to aadọjọ miliọnu le mẹta owo dọla ($153m) ni EFCC fẹsun kan minisita epo rọbi tẹlẹ pe o ji ko

Wọn ni o ko owo yii sa lọ ṣaaju idibo gbogboogbo ọdun 2015.

Koda, ajọ EFCC tun gbẹsẹ le ile awo dami ẹnikan to jẹ ti Alison-Madueke to wa niluu Eko.

Ile yii ni wọn pada jọwọ fun ipinlẹ Eko lati maa lo fun ibudo iyasọtọ.

Ẹsun iṣowo ilu kumọkumọ ti EFCC fi kan Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose

Ọkan lara awọn ẹsun iwa ibajẹ ni ijọba ni ti ajọ EFCC ṣagbatẹru nigba ti Ibrahim Magu fi jẹ adele alaga ajọ ni ẹjọ Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ. Ayo Fayose.

EFCC fi ẹsun iṣowo ilu to le ni biliọnu kan naira (N1.2b) kumọkumọ kan Gomina ana ipinlẹ Ekiti.

EFCC fẹsun kan Fayose ati ẹnikan pe wọn gbe iye owo naa jade lọna aitọ lati fi ṣe ipolongo ibo gomina.

EFCC fẹsun jiji owo ilu kan Gomina Abia tẹlẹ Orji Uzor Kalu

Ẹjọ miiran ti ajọ EFCC ṣe agbatẹru rẹ lasiko ti Magu fi jẹ alaga ajọ naa ni ẹsun kiko owo bii N7.1bn ilu jẹ ti wọn fi kan Orji Uzor Kalu to jẹ Gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ ri.

Wọn tun fi ẹsun kiko owo ilu lọ si ilẹ okeere kan naa kan Kalu.

Ileẹjọ ti kọkọ dajọ ẹwọn ọdun mejila fun Kalu ti o si dero ẹwọn lẹyin naa.

Ṣugbọn ileẹjọ to julọ ni Naijiria tu idajọ ti ileẹjọ kotẹmilọrun da fun un ka.

Ẹwẹ, Ọgbẹni Kalu ti pada sile aṣofin agba l'Abuja nibi o ti n ṣoju ipinlẹ rẹ gẹgẹ bi sẹnẹtọ.

Àkọlé fídíò, Kemi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí

EFCC fẹsun gbigba N400m lọwọ Sambo Dasuki kan Olisah Metuh:

Ajọ EFCC fi ẹsun kan akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Olisa Metuh pe o gba irinwo miliọnu naira lọwọ oludamọran lori ọrọ aabo, Sambo Dasuki.

Ajọ naa ni Metuh gba owo yii lati fi ṣe iṣẹ ijọba kan ni, ṣugbọn ko ṣe nkan kan lẹyin to gba owo naa tan.

Adajọ Okon Abang sọ pe Metuh jẹbi ẹsun onikoko meje ikowo lọ ilu lọ si ilẹ okeere kan Metuh.

Lẹyin ọ rẹyin, ile ẹjọ dajọ ẹwọn ọdun meje fun akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ.

Ẹ̀ṣùn méje gbòógì tí ìjọba àpapọ̀ fi kan Ibrahim Magu rèé

Ibrahim Magu: Lára ẹ̀ṣùn rẹ̀ ni pé ìjọba àpapọ̀ kò mọ ohun tó ń lọ nípa àjọ EFCC

Ana ode yii ni okiki kan lori ayelujara pe awon osisẹ ile ișẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ti gbe ọga agba ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati lilu owo ilu ni ponpo, EFCC, Ibrahim Magu fun ifọrọwanilẹnuwò.

Saaju ni Aare Muhammadu Buhari ti gbe igbimọ kan dide, eyi ti Ayo Salami jẹ alaga rẹ.

Igbimọ yii wa lati se iwadii awọn ẹsun oniruuru ti wọn ti fi n kan Magu, lati igba to ti gori oye.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ile igbimọ asofin agba kọ lati yan ọga ajọ EFCC gẹgẹ bi ojulowo alaga,.

Wọn ni nitori pe iwadii DSS nigba naa fi han pe, ko yẹ lẹni to le di ipo naa mu.

Lati igba yii ni orisirisi ẹjọ ti n waye lori iṣe si ati ihuwasi rẹ, to fi mọ kikọ olu ile iṣẹ ajọ EFCC naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin sọ pe igbimọ ti Aarẹ yan yii lo pe Magu fun iwadii ninu ile ijọba Aso Rock.

Awọn ẹsun wo ni wọn ka si Ibrahim Magu lọrun.

  • Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ọpọ ẹsun ti wọn ka si Magu lọrun ko sẹyin abajade iwadii agbejọro ijọba apapọ ati ajọ DSS lọ 2016, eyi ti wọn gbe fun ijoko ile igbimọ asofin agba lodun 2017.
  • Ninu abajade naa ni wọn ti fẹsun kan an pé, igbe aye ti ọga ajọ EFCC naa n gbe ju iye owo osu to n gba lọ.
  • Bakan naa ni wọn lo ni ibasepọ to dan mọran pẹlu awọn to n huwa ibajẹ lawujọ, paapaa julọ awon ti wọn si n kowo ilu pamọ lọna aitọ.
Àkọlé fídíò, Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran
  • Ẹsun miran tun ni pe, Magu n dari owo ti won ba gba lọwọ awọn to n huwa ajẹbanu sibo miran.
  • Wọn fẹsun kan an pe, Magu a maa ṣe arifin si awọn to juu lọ lẹnu iṣẹ.

Iroyin sọ pe, saaju ni Malami ti fi ẹjọ Magu sun Aarẹ Buhari pe, kii jẹ ki ile iṣẹ oun to jẹ ile iṣẹ to n bojuto ajọ EFCC mọ nkankan nipa ohun to n lọ nibẹ.

Paapaa julọ nipa awọn ile ti wọn ba gba lọwọ awọn to lu owo ilu ni ponpo.

Ibrahim Magu

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Malami ni ile iṣẹ oun ko mọ iye ile, owo tabi nkan ini ti won gba lọwọ awọn alajẹbanu oloṣelu, bakan naa ni o rọ Aarẹ pe o ti to ki Magu lọ rọkun nile.

O ti fẹẹ to ọdun marun-un bayii ti Magu ti jẹ adele alaga ajọ EFCC.

Ninu ọrọ rẹ, agbẹjọro ọga agba ajọ EFCC, Oluwatoyin Ojaomo, ninu ifọrọwerọ kan salaye pe nipa idi ti ajọ DSS fi n wa onibara rẹ.

O ni wọn n fọrọ wa onibara oun lẹnuwo nitori awọn kudiẹkudiẹ to wa ninu awọn owo ti ajọ naa gba lọwọ awọn ti wọn mu, iyatọ wa lara iye ti o kede ati iye to wọ apo ìjọba.

O ni owo ti o wọ apo ijọba pọ ju owo ti wọn kede lọ.

Bi aje gbogbo ẹsun yii ba wa si mọ Ibrahim Magu lori, o tumọ si pe, ijọba ti bọs'ọja bayii lati wa elomiran ti yoo rọpo rẹ gẹgẹ bi alaga ajọ EFCC.

Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ pé kí alága EFCC, Ibrahim Magu lọ rọọ́kún nílé

Ijọba apapọ orilẹ-ede yii ti pasẹ pe Ibrahim Magu lọ rọọkun nile na gẹgẹ bii alaga ajọ EFCC.

Eekan kan nile ijọba Aso Rock nilu Abuja, ti ko fẹ fara han sita lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC lọsan ọjọ Isẹgun.

Ibrahim Magu lo ti kọkọ yọju siwaju igbimọ oluwadii kan ti ileesẹ aarẹ gbe kalẹ lọjọ Aje lati tanna wadi awọn ẹsun aidaa ti wọn fi kan-an.

Igbimọ naa, ti Adajọ-fẹyinti Ayo Salami ko sodi lo ransẹ pe Magu lati gbọ tẹnu rẹ lori awọn ọrọ kan to nii se pẹlu awọn alasẹ ajọ EFCC.

Bakan naa, awọn eekan ilu kan ni Naijiria ti fidi rẹ mulẹ pe ahamọ awọn agbofinro ni Magu sun mọjumọ ọjọ Isẹgun.

Idi ni pe wọn ko lee pari iwadii wọn ni ọjọ Aje.