Ọba mẹ́wàá tí wọ́n ti lé kúrò nípò: Alaafin, Ọlọ́wọ̀, Elérúwà , Awujalẹ àti ...

Awọn Oba

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Àkójọpọ̀ mẹ́wàá lára àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n lé kúrò ní ipò Ọba.

Ọjọ ti pẹ ti wọn ti máa n rọ ọba loye nilẹ Yoruba.

Oriṣiriṣi ìdí si ló máa n fà ki wọn rọ Kabiesi loye, diẹ nibẹ ni ọ̀tẹ̀, ogun, iwakiwa, ati bẹẹ bẹẹ lọ, lo maa n mu ki wọn o rọ ọba loye.

Nitori naa, ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn ọba ilẹ Yoruba ti wọn rọ loye.

1) Akire ti ilu Ikire:

Ọba yii, Olatunde Falabi, la o fi si de, nitori pe wọn ṣẹṣẹ rọ ọ loye ni.

Awuyewuye lori ẹni ti ipo ọba kan ni Ikire ti bẹrẹ lati ọdun 1993 nigba ti Ọba Falabi gori itẹ.

Eyi to mu ki ọkan lara awọn to n du ipo ọba ọhun, Ọmọba Tajudeen Olarewaju, lati idile Aketula pe ẹjọ lodi si ọba tuntun to ṣẹṣẹ gori itẹ lọjọ naa lọhun.

Akire ti Ikire

Oríṣun àwòrán, @Olatunde

Àkọlé àwòrán, Àkójọpọ̀ mẹ́wàá lára àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n lé kúrò ní ipò Ọba.

Wọn fa ẹjọ naa titi to fi de ile ẹjọ to gaju ni Naijiria lọdun 2014, ti ile ẹjọ ọhun si ṣedajọ pe kii ṣe Falabi ni oye naa tọ si, bikoṣe Olarewaju.

Lẹyin idajọ naa ni ijọba ipinlẹ Osun gbiyanju lati yọ Ọba Falabi lori itẹ.

Ni eyi to mu ki oun ati awọn agbẹjọro rẹ gba ile ẹjọ giga ipinlẹ lọ, pe idajọ ile ẹjọ to ga ju naa ko sọ pe ki oun kuro lori oye.

Ile ẹjọ giga ipinlẹ lo pada rọ ọ loye bayii, lọjọ Keji, oṣu Keje, ọdun 2020.

2) Eleruwa ti Eruwa - Ọba Adebayo Adegbola:

Ọdun 2011 ni ile ẹjọ rọ Ọba Adegbola loye.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti Ọba naa gbe ẹjọ lọ lẹyin idajọ ile ẹjọ giga to sọ pe idajọ to gbe Ọba Adegbola wọle lọdun 2011 kìí ṣe eyi to tọna rara.

Adajọ naa sọ pe ori àpèrè naa ko tọ sii.

Adajo Oladipo Abimbola ni ọna alùmọkọ́rọ́yí ni Ọba yii gba de ipo naa.

Awọn kan lara awọn ti wọn jọ du oye lo gbe e lọ sile ẹjọ.

Ọdun 1998 ni Ọgbẹni Adegbola de ori oye, lẹyin ti Ọba a Bolanle Olaniyan kú lọdun 1994.

Lasiko idajọ to yọ Eleruwa nipo, Adájọ ni gbogbo igbesẹ, láti ori yíyan ọmọ oye to fi mọ bi ìjọba ṣe gbe ọ̀pá àṣẹ fún un ko tọ̀na rara.

Eleruwa

Oríṣun àwòrán, @Eleruwa

Àkọlé àwòrán, Àkójọpọ̀ mẹ́wàá lára àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n lé kúrò ní ipò Ọba.

3) Déjì ìlú Akurẹ - Ọba Oluwadamilare Adesina:

Osupa Kẹta Ko jọ ẹ̀sín, ko jọ itiju ni Ọba Oluwadamilare Adesina fi kuro lori oye.

Ọdun 2010 ni ijọba ipinlẹ Ondo lábẹ́ Gomina Segun Mimiko yọ ọba naa nipo lẹyin to lu iyawo rẹ ni ìlùkulù.

Ijọba sapejuwe iwa to hu gẹgẹ bi nkan itiju, idojuti, to si tun tako awọn amuyẹ ti ofin ipinlẹ naa la kalẹ fun awọn ọba ati ijoye.

Deji Akure

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Àkójọpọ̀ mẹ́wàá lára àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n lé kúrò ní ipò Ọba.

4) Olupoti ìlú Ipoti- Ekiti - Ọba Oladele Ayeni:

Lẹyin ọdun mẹẹdọgbọn ti Ọba Isaiah Oladele Ayé I ti wa nipo ni wọn to o rọ loye.

Ọdun 1987 lo jẹ ọba, sugbọn wọn le e kuro lori itẹ lọdun 2012 nitori pe "wọn ṣèèṣì yàn án sípò ọba ni".

5) Ọlọ́wọ̀ ti ìlú Ọ̀wọ̀ - Olateru Olagbegi Keji:

Ọdun 1941 ni Ọba yii gun ori ìtẹ́.

Sugbọn ọdún 1966 ni awọn ara ilu Ọwọ kọ ẹyin si Ọba wọn yii, ti wọn si le e kuro niluu.

Eyi ko sẹyin bi rogbodiyan kan ṣe waye lọdun naa, ti ẹmi ati dukia awọn eniyan si sọnù.

Olateru Olagbegi

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Àkójọpọ̀ mẹ́wàá lára àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n lé kúrò ní ipò Ọba.

Oloṣelu ni Ọba Olateru, Koda, iroyin sọ pe ninu ààfin rẹ ni wọn ti da ẹgbẹ oṣelu Action Group ti Obafemi Awolowo silẹ.

Ọrọ oṣelu lo fa rogbodiyan to waye nilu Ọwọ nigba naa.

Àkọlé fídíò, Oríṣí ìjìyà ní àwọn bíi Gómìnà El Rufai àti Fayemi ń bèèrè f'àwọn afipábánilòpọ̀

Sugbọn o, wọn tun pada yan Ọba Olateru pada sori itẹ lọdun 1993, lẹyin ọdun mẹtadinlọgbọn.

Eyi ko sẹyin iku Ọba Ogunoye to gba ipo rẹ.

O si jọba fun ọdun marun un si, ko to o ku lọdun 1998.

6) Awùjàlẹ̀ ti Ìjẹ̀bú - Ọba Sikiru Adetona:

Ọdun 1982 ni wọn rọ ọba yii loye lẹyin ti wọn fi ẹsun afojudi, ijọra ẹni loju, ati aibọwọ fun ofin kan an.

Eyi ko sẹyin ija oṣelu to ti waye ri laarin oun ati gomina ipinlẹ Ogun nigba naa, Olabisi Onabanjo.

Oun lo si rọ ọ loye lẹyin ti igbimọ oluwadii sọ pe o jẹbi ẹsun naa.

Sugbọn sa, gomina ológun to pada jẹ lẹyin rẹ, Ọgagun Oladipupo Diya da a pada sipo lọdun 1984.

Awujale
Àkọlé àwòrán, Àkójọpọ̀ mẹ́wàá lára àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n lé kúrò ní ipò Ọba.

7) Ọlọ́fà ti Ọffa - Ọba Wuraola Isioye:

Wọn fi Ọba Isioye jẹ lọdun 1957

Ó si dari ẹkùn Ọffa fun ọdun meji ko to o di pe ijọba ẹkùn nla ni Ariwa Naijiria yọ ọ loye.

Eyi ko sẹyin bi ìjọba ṣe tẹwọ gba idasilẹ ijọba ibilẹ Ọffa, ti wọn si fagile Ilorin Alkali to wa nilẹ tẹlẹ.

Eyi lo mu ki Saurduna igba naa le e kuro niluu lọ si agbegbe kan laarin ilu Ogbomọṣọ ati ipinlẹ Kogi.

Ibẹ lo gbe titi di ọdun 1964 to pada silu Ọffa. Wọn da a pada sipo, o si jẹ di ọdun 1969 to kú.

Àkọlé fídíò, Yetunde Bakare dárà lórí ètò Ṣé o láyà, ẹ ràn án lọ́wọ́ nínú ìbéèrè tó ṣì

8) Alase ìlú Rẹmọ - Ọba Oyebajo:

Ọdọ ni ọba yii nigba to jẹ. O wa lori ipo laarin ọdun 1811 si 1915.

Ijọba awọn oyinbo aláwọ̀ funfun lo rọ ọ loye, nitori pe o n fi ẹtọ awọn ijoye rẹ meji pataki (Lisa ati Losi ilu Rẹmọ) lara ajẹmọnu ti ijọba n fun wọn dùn wọn.

Awọn ijoye naa fi ẹsun ikowojẹ ati awọn ẹsun iwa ibajẹ kan an, eyi to mu ki ijọba rọ ọ loye, to si tun ju si ẹ̀wọ̀n nilu Ìjẹ̀bú Òde, ati awọn meji miran.

Wọn fi silẹ lẹyin oṣu mẹfa, o si pada tẹdo si Sagamu.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

9) Aláàfin ìlú Ọyọ - Ọba Adeyemi Adediran Keji

Ọ̀tẹ̀ oṣelu lo fa bi wọn ṣe rọ baba to bi Alaafin ìlú Ọyọ to wa nipo bayii, (Ọba Lamidi Adeyemi Kẹta) Ọba Adediran Adeyemi nipo.

Eyi ko sẹyin bi o ṣe satilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu NCNC to jẹ ti Oloye Nnamdi Azikiwe, dipo Action Group ti Obafemi Awolowo da silẹ.

Alaafin naa

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Àkójọpọ̀ mẹ́wàá lára àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n lé kúrò ní ipò Ọba.

Ati paapaa nitori ija to wa laarin oun ati Olori egbe oselu Action Group nigba naa, Bode Thomas.

Wọn le Ọba Adediran kuro nilu Ọyọ ninu osu Keje, ọdun 1955.

O si lọ fi ìlú Eko ṣe ibugbe, nibi to ti gbé pẹlu Alhaji N.B Soule, to jẹ ọkan pataki ninu ẹgbẹ oṣelu NCNC.

Àkọlé fídíò, Báwo ni èèyàn ṣe le mọ pé òun ti ní àrùn Coronavirus?

10) Osemawe ti ìlú Ondo - Ọba Adekolurejo Jimosun Keji:

Ọba naa jẹ laarin ọdun 1918 si 1925 ti wọn le e kuro nilu lọ si Ilé-Ifẹ̀.

Ìlú Ilé-Ifẹ̀ lo gbé to fi kú.

Ìtàn sọ pe lasiko ti Ọba yii wa ni ipo, ni wọn da ile ẹ̀kọ́ girama akọkọ nilu Ondo, Ondo Boys High School, silẹ.

Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀