Chad prisoners death: Ẹlẹ́wọ̀n 44 kú lagbà ẹ̀wọ̀n ní Chad látàárí ooru tó mú púpọ̀

Chad

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Eeyan mẹrinlelogoji

Iwadii lori awọn ẹlẹwọn mẹrinlelogoji to ku si ọgba ẹwọn orilẹ-ede Chad ti pari.

Lorumọju ọjọ naa ni wọn doloogbe ninu ooru to pọ de ida sẹntigireedi mẹrindinlaadọta lọjọ naa.

Awọn agbẹjọro ijọba orilẹ-ede Chad sọ pe awọn eeyan yii jẹ afurasi oniṣẹ ibi Boko haram nigba ti awọn ajafẹtọ ọmọniyan ni irọ ni pe ara ilu lasan to n ṣẹwọn ni wọn jẹ.

Awọn ni ọgba ẹwaọn orilẹ-ede Chad ti kun akunfaya ju ni eyi ti ko dara lasiko ooru ti oorun mu yanyanyii.

Wọn tun ni ọpọ ẹlẹwọn ni ebi n pa ni Chad ti wọn ko si tun ri omi to mọ geere mu.

Adajọ agba lorilẹ-ede Chad, Djimet Arabi ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin AFP pe oun ti gbọ tọtun tosi bi o ṣe yẹ ni ilana ofin.

Ati pe oun ti pe fun iwadii akọtun lati mọ ohun to ṣokunfa iku ẹlẹwọn mẹrinlelogoji naa ni pato.

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Awọn ẹlẹwọn naa ku si olu ilu N'Djamena, awọn olupẹjọ ni awọn eeyan naa wa lara awọn mejidinlọgọta to jẹ afurasi Boko haram.

Agbẹjọro ijọba ni wọn ti si ogoji ninu awọn oku naa ti wọn si ti ko oku mẹrin to ku lọ fun ayẹwo bi o ti yẹ.

Chad

Oríṣun àwòrán, others

Ṣaaju ni wọn ti fun Aarẹ Deby ni oye Field Marshal lasiko isami ọgọta ọdun ominira Chad.

Orílẹ̀-èdè Chad pé ọgọ́ta ọdún, àwọn ara ìlú ń pariwo lábẹ́ Aàrẹ Deby tó gba 'Field Marshal'

Africa Field Marshal: Ṣé ìwọ mọ ìtumọ̀ kí wọ́n fún adarí ní oyè "Field Marshal?"

Ọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ọdun 1960 ni Chad gba iyọnda lọwọ France to n mu wọn sin.

Olootu ijọba nigba naa lo pada di aarẹ akọkọ, iyẹn, Francois Tombalbaye ni asiko ẹni ti ọpọ ija ṣẹlẹ laarin awọn Mususlumi ni ariwa ati awọn Kristiẹni ni guusu.

Idriss Deby

Oríṣun àwòrán, others

Ọwọ lile ni Tombalbaye fi ṣe ijọba rẹ ki wọn to paa lọdun 1975 lati ọwọ awọn ọmọ ogun kan.

Ọdun 1979 ni ogun abẹle ṣẹlẹ to fopin si gbigbe ni irẹpọ awọn eeyan Chad.

Wọn ni epo rọbi ti wọn n ri ni Chad to agba epo biliọnu ẹgbẹrun kan ati aabọ ni eyi ti wọn fi jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede ilẹ Adulawọ to ni epo rọbi julọ.

Awọn Aarẹ to ti jẹ ni Chad sẹyin:

  • Francois Tombalbaye lati 11 - 08- 1960 si 13- 04- 1975
  • Noel Milarew Odinger lati 13- 08- 1975 si 15 -04- 1975
  • Felix Malloum lati 15- 04- 1975 si 23 -03 1979
  • Goukonni Queddei 23 - 03- 1979 si 29- 04- 1979
  • Loi Mohamat Choua lati 29- 04- 1979 si 03- 09 1979
  • Goukouni Queddei lati 03- 09 - 1979 si 07- 06- 1982
  • Hissene Habre lati 07- 06- 1982 si 02 12- 1990
  • Idriss Deby lati 02- 12- 1990 si asiko yii
Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Wo ohun to yẹ ki o mọ nipa awọn adari ilẹ Adulawọ to ti gba 'Field Marshal'ri:

Field Marshal ni oye to tobi julọ ninu iṣẹ ologun to tun kọja ti ọgagun agba.

Ọgagun to ba tayọ, to tun fakọyọ julọ ninu iṣe tabi ninu iṣẹlẹ manigbagbe laelae ti ko wọpọ lo n gbaa.

Lọṣu to kọja ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Chad buwọlu ofin ti yoo sọ aarẹ wọn di oloye to ga julọ ninu iṣẹ ologun ni gbogbo agbaye.

Hussein

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Mohamed Hussein Tantawi ni wọn gba ni igi lẹyin ọgba fun ọpọlọpọ Aarẹ

Ofin naa lo ni pe ki wọn fi oye 'Field Marshal' da ààrẹ ilẹ naa, Idrissa Deby Itno lọla lati ipo ọgagun agba julọ, iyẹn 'General'.

Eyi ti awọn onwoye ohun to n lọ nilẹ naa soọ pe o jẹ ọna lati jẹ ki ààrẹ ọhun wa lori oye pẹ titi sii.

Idrissa Deby kọ ni aarẹ akọkọ ni Afirika ti yoo gbiyanju lati wa lori oye titi pẹ to fi di ọjọ iku rẹ.

Wo diẹ lara awọn Aarẹ ilẹ Adulawọ to ti táa tán sori oye nitori pe wọn di 'Field Marshal':

Ta ni Idi Amin Dada tó jẹ 'Field Marshal' ni Uganda?

Wọn bi Idi Amin ni ọdun 1925, o si darapọ mọ ẹgbẹ ọmọ ogun labẹ iṣejọba ilẹ Gẹẹsi lọdun 1945.

O di aarẹ Uganda lọdun 1971 lẹyin to ditẹ-gbajọba lọwọ aarẹ Milton Obote, o si ṣejọba fun ọdun mẹjọ gbako.

O fun ara rẹ ni oye Field Marshal lọdun 1975 pẹlu ami irawọ marun un leti aṣọ rẹ

Lẹyin ti wahala bẹ silẹ lọdun 1979 lo salọ ṣe atipo ni ilẹ Saudi Arabia to si ku sibẹ lọdun 2003.

Idi Amin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idi Amin Dada lo fun ara rẹ ni oye Field Marshal lọdun 1975 pẹlu ami irawọ marun un leti aṣọ rẹ

Wo ohun to yẹ ki o mọ nipa Mohamed Hussein Tantawi to di 'Field Marshal' ni Egypt:

Tantawi di aarẹ ilẹ Egypt lẹyin iṣubu ijọba Mubarak lọdun 2011, ṣugbọn o gbe ìjọba silẹ lọdun 2012.

O kopa ninu ogun ilẹ Egypt fun nnkan bii aadọta ọdun, papa lọdun 1967 ati 1973 nibi to ti gba oye 'Field Marshal'.

Ọpọ eeyan lo n fi o oju kan naa wo Tantawi ati Aarẹ Hosni Mubarak.

Jean-Bédel Bokassa, Emperror ti orilẹ-ede Central African Republic:

Wọn bi Bokassa loṣu keji, ọdun 1921, o si kawe ni Brazzaville.

Iṣẹ alufaa lo wu u lati ṣe ṣaaju ki awọn obi rẹ to parọwa si i pe ko darapọ mọ isẹ ologun.

Bokassa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jean-Bédel Bokassa ti Central African Republic

Bokassa ni aarẹ Central African Republic, CAR, lati ọdun 1966 si 1976, asiko naa lo sọ ara rẹ di "Emperor" ilẹ ọhun.

Wọn fi ẹsun kan an pe o lọwọ ninu iṣekupani awọn ọmọ ile iwe to to ọgọrun un lasiko iṣejọba rẹ.

O fi igba kan sa kuro ni CAR lọ ṣatipo ni France lọdun 1980, ṣugbọn o pada si CAR nibi ti wọn ti pada ran an lẹwọn igbere.

Field Marshal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O sa kuro ni Cote d'Ivoire ko to tun lọ si orilẹ-ede France

Wọn pada fii silẹ kuro ni ẹwọn gbere lọdun 1993 lẹyin ti o ṣẹwọn.

O jade laye ni oṣu kejila, ọdun 1996 lẹyin ti ọkan rẹ kọ iṣẹ.

lọdun 2003 ni ijọba dariji oku rẹ nigba ti wón n sami ayẹyẹ ominira aadọta ọdun nibẹ.

Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀