Coronavirus: Ewu wo làwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlèra ń kojú ní Nàìjíríà?

Oṣiṣẹ eleto ilera

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣiṣẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo ti kọkọ gun le iyanṣẹlodi lati fẹhonu han lori aini irinṣẹ to to ati lori owo ti wọn n gba,

ṣugbọn awọn to n ṣiṣẹ lawọn ibudo iyasọtọ fun aarun coronavirus n ṣiṣẹ ni ti wọn.

Ẹwẹ, minisita eto ilera, Dokita Osagie Ehanire ti sọ pe ijọba ti yanju ọrọ aṣọ idaabobo(PPE) tawọn oṣiṣẹ eleto ilera maa n wọ lẹnu iṣẹ.

Iru ewu wo gan an ni o le wu awọn awọn oṣiṣẹ eleto ilera lorilẹede Naijiria?

Ẹgbẹ awọn dokita ile ẹkọ iṣegun(NARD) ti kọminu lori bi awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti n ko aarun ti ọpọ si n gba ibẹ ku.

Ẹgbẹ naa ni dokita mẹwaa lo ti ku bayii.

Healthcare workers who've had Covid-19. . Latest available data up to 9 June.

Ajọ eleto ilera lagbaye, WHO ti sọ tẹlẹ pe ọpọ oṣiṣẹ eleto ilera lagbaye lo ti farakasa aarun covid-19.

Ọpọ orillẹede agbaye lo ti kuna lati pese aabo to peye fawọn oṣiṣẹ eleto ilera lẹnu iṣẹ wọn.

Coronavirus ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n to n ri si idagbasoke kaakiri agbaye(CGD) ṣalaye pe o buru jai lawọn orilẹede ti ko rọwọ họri.

Ominu n kọ ọpọ eeyan ni Naijiria tori ọpọ gbagbọ pe ko si ẹni to mọ ohun to ṣẹlẹ dunjudunju lori ajakalẹ aarun covid-19.

Irinṣẹ ati dena covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fun apẹẹrẹ, ọpọ eeyan laagbọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe covid-19 lo pa wọn ṣugbọn ko si ayẹwo fun wọn.

Akọsilẹ fihan pe awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni Naijiria lo lugbadi aarun coronavirus julọ nilẹ Adulawọ yatọ si orilẹede South Africa.

Ṣugbọn idamẹfa awọn to laarun naa ni iroyin n gbe jade, nigba ti ida mọkandinlogun ni awọn eeyan mọ lorilẹede Niger.

Orilẹede Liberia ati Sierra Leone tun lo kan tawọn oṣiṣẹ eleto ilera tun ti ko aarun covid-19 ju.

Ṣugbọn gbogbo awọn orilẹede apa iwọ oorun Afririka yii ni ko ni awọn eeyan to laarun coronavirus to Naijiria.

Ile iwosan ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹka eto ilera ni Naijiria ko ri owo na fun ọjọ pipẹ, loorekoore lawọn oṣiṣẹ maa n gun le iyanṣẹlodi fun ẹkunwo.

Ida mẹrin pere owo eto iṣuna lọdun ni ijọba maa n ya sọtọ fun ẹka ilera ni Naijiria.

Lọdun 2001, awọn orilẹede to jẹ ọmọ ajọ AU ṣeleri lati maa ya idamẹẹdogun owo eto iṣuna sọtọ lọdọọdun fun ẹka eto ilera.

Laipẹ yii ni ijọba orilẹede Naijiria naa ya ida mẹtalelogoji ipin sọtọ fun ẹka eto ilera, papaajulọ nitori ipa ti ajakalẹ aarun covid-19 ni lori ọrọ-aje ati bi ọrọ-aje ebpo rọbi ṣe ri lọja agbaye.

Onimọ nipa eto ilera, Onyeka Onwuegbunam ọmọ Naijiria to n ṣiṣẹ ni Fasiti ilu London sọ pe ''ko si itọju to peye lawọn ile iwosan ijọba nitori ọda owo na.

O ni ile iwosan ko pọ ni Naijiria, awọn eyi to si wa naa, ko dantọ.

Àkọlé fídíò, Port harcourt Bole: Mi kò mọ́ pé bọ̀ọ̀lì títà lè gbé mi dé ipò yìí láyé mi!