Dexamethsone tablets: Báwó ni òògùn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ lára

Oogun dexamethasone

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Dexamethsone tablets: Báwó ni òògùn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ lára
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Kíni à npè ni Dexamethasone, àti pé báwo ni o ṣe ń wo ààrùn covid-19?

Òògun náá jẹ́ èyí ti wọ́n maa n lò fún àìsàn tẹ́lẹ̀ ti o sí ti fìdímúlẹ̀ pé wọ́n n lòó fún àìsàn Covid-19 ni ilé ìwòsàn.

Báwo ni wọ́n ṣe n lòó fún ìtójú

Wọ́n ti dán òògùn náà wò lára àwọn tó ni Covid-19 ní ilẹ gẹ̀ẹ́sì ti ó sì ti dájú pé ó ń dóòlà ẹmi àwọn ènìyàn, èyí sì yi jẹ́ kí wọ́n maa maa lòó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Báwo ló ṣe n ṣiṣẹ́?

Ǹkan tí òògùn náà ń ṣae ni pé ó maa n mú àdinkù bá àwọn ọmoogun tó ń jà nínú ara.

Ààrùn onígbáméjì (Cholera) ó maa dá wàhálà silẹ̀ sínú ẹ̀dọ̀fóró tí ara yóò sì máa gbìyànjú láti báa jà.

Sùgbọ́n nígbà míràn èròjà tó n gbógun tí ààrùn lára yóo ti gbé ẹrù tó jùúlọ, àsìkò yìí ni ààrẹ yóò de si àgọ́ ara, nítorí àsìkò tó yẹ ki ó gbógun ti ààrùn lára, yóò kòjú si ara fún rarẹ láti jà.

Nítori náà dexamethasone ń mu àdínkù bá àwọn ìjàmba ti àwọn òògùn míràn le ṣe fún ara.

Wọ́n sábà máa n lo òògùn tuntun yìí fún àwọn tí wọ́n bá wà nílé ìwòsàn tí wọ́n sì ń lo ẹ̀rọ aṣèranwọ́n èèmí, èyí túmọ̀ sípé àwọn tó wa ní ipò tó léwu.

Sùgbọ́n kò wúlò fún àwọn tí wan bá ti wà ni ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀ọ̀rún, mímú àdínku bá ara sísàn kò wúlò mọ

Òògùn Dexamethasone máá n fa gbogbo kòkòrò tó bá wà nínú àra jáde tí yóò sì fún ara lókun

A kò tíì fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ògùn Dexamethsaone ń ṣiṣẹ́ fún àrùn coronavirus- WHO

Dexamethsaone tablets: Àjọ NCDC ní kò tíì sí ìfìdímúlẹ̀ pé Dexamethsaone ń ṣiṣẹ́ fún coronavirus

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn onimọ sayẹnsi ni Ilẹ Gẹẹsi ti fi lede pe oogun Dexamethasone n ṣiṣẹ koju ajakalẹ arun Coronavirus.

Ajọ to n risi ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti fi lede wi pe awọn to tii fi idi ẹ mulẹ pe oogun Dexamethasaone n ṣiṣẹ fun arun Coronavirus.

Ajọ NCDC lo fi lẹde bẹẹ soju opo ikansiraẹni Twitter won lẹyin ti awọn onimọ sayẹnsi ni Ilẹ Gẹẹsi ti fi lede pe oogun Dexamethasone n ṣiṣẹ koju ajakalẹ arun Coronavirus.

Ninu ọrọ wọn, ajọ NCDC ni awọn ko i tii buwọlu oogun kankan wi pe ohun koju arun Coronavirus ni Naijiria ati wi pe iwadii si n lọ lori oogun Dexamethasaone.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

NCDC fikun un pe awọn yoo fi esi ayẹwo wọn lede lẹyin ti wọn ba ti pari rẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Amọ iwadii awọn onimọ sayẹnsi naa fi lede pe oogun naa ti ko wọn ju, ti o si wọpọ kaakiri n doola ẹmi awọn eniyan to n koju arun Coronavirus.

Bakan naa ni Ajọ Eleto Ilẹra lagbaye, WHO ni awọn ti gba esi ayẹwo oogun Dexamethsaone wọle gẹgẹ bi oogun to n koju arun Coronavirus.