Ìtàn Mánigbàgbé: Ìdílé Mobee, Abass, Aniwura àtàwọn míràn rí owó tabua nínú òwò ẹrú

Ọwọn ti wọn mọ ni ojude ẹbi Mobee

Owo ẹru jẹ oko-owo to gbajumọ yika agbaye ninu eyi ti wọn ti n ko awọn ọmọ adulawọ lọ ta bíi ẹru soke okun.

Aarin ṣaa onka ẹgbẹrun ọdun kẹrindinlogun si ikọkandinlogun (16th-19th century) si ni owo ẹru gbilẹ nilẹ Afirika

Lasiko yii ni wọn si ta adulawọ bii miliọnu mejila soko ẹru loke okun nigba naa.

Yoruba si ni bi iku ile ko ba pa ni, ti ode ko le pa ni, akọsilẹ si fihan pe, awọn ọmọ Adulawọ kan pẹlu idile wọn lo n ta awọn Adulawọ ẹgbẹ wọn fawọn oyinbo alawọ funfun, ti owo ẹru fi gbilẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe ọjọ pẹ ti owo ẹru ti kasẹ nilẹ, sibẹ iyan ogun ọdun tun jo awọn idile to kopa ninu owo ẹru lọwọ,

Paapaa lasiko yii ti ibinu araalu si tun dìde si wọn lẹẹkan si nitori adulawọ kan, George Floyd, ti Ọlọpa kan sekupa ni Amẹrika.

Idi ree ti BBC Yoruba tun ṣe woju wo ẹyin lati ṣe akojọpọ idile marun nilẹ Yoruba, ti wọn kopa ninu owo ẹru ṣíṣe nigba atijọ.

Àkọlé fídíò, Sogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Idile Mobee ni Badagry:

Ilu Badagry, taa tun mọ si Agbadarigi to wa nipinlẹ Eko, jẹ ilu to gbajumọ fun oko-owo ẹru laye ijọhun nitori bo ṣe sunmọ eti okun ti wọn n gba ko awọn ẹru sọda soke okun.

Lara awọn idile to gbajumọ fun owo ẹru sise nigba naa ni idile Ọba Sunbu Mobee,

Idile yii to ni gbọngan nla nilu Badagry ti wọn n ko ọpọlọpọ ẹru pamọ si, ki wọn to ko wọn lọ soke okun.

Lati ilu Oyo, Ibadan, Abeokuta, Osogbo ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni wọn ti n ko ẹru wa fun idile ọba Mobee,

Ti ọja Belekete naa si wa nilu Badagry, ti wọn ti n ta ẹru fun awọn oyinbo ati adulawọ.

Ọwọn ti wọn mọ ni ojude ẹbi Mobee

Ni kete ti awọn oyinbo naa ba si ti ra awọn ẹru yii, ni wọn yoo fi irin gbigbona kọ orukọ wọn siwaju ẹru wọn,

Wọn yoo sọ ẹwọn irin si wọn lọwọ ati ọrun, fun ọjọ pipẹ, ki wọn to ko wọn lọ silu oyinbo.

Koda wọn tun maa n fi agadagodo pa ete mejeeji ẹnu ẹru de mọra wọn, ki wọn ma baa sọrọ si ara wọn,

Gbogbo awọn eroja ìnira ti wọn si n lo fawọn ẹru yii lo wa ninu ibudo ise nnkan isẹnbaye lọjọ si ni iranti owo ẹrú, eyi to wa lagbo ile Mobee nilu Badagry, titi di oni oloni.

Idile Oba Seriki William Abass:

Gbajugbaja olowo ẹru ni Oba Seriki Williams Ifaremilekun Abass tilu Badagry laarin saa onka ọdun kọkandinlogun (19th century).

Ilu Ilaro, tii ṣe ilu abinibi rẹ ni wọn ti ko Seriki Abass ni ẹru lasiko ogun Ẹ̀gbá ati Dahomey, ti wọn si ta a fun Williams, tii ṣe oyinbo olowo ẹru lati Brazil.

Ojude agboole Seriki williams

Abass lọ ṣe ẹrú ni Brazil, nibi to ti gbọ ede oyinbo, to si tun mọọ kọ, mọọ ka, ki wọn to da a pada sile lati wa maa ṣe Alakoso owo ẹrú fun ọga rẹ, Williams nilu Badagry.

Seriki Abass jẹ Oba nilu Badagry, lẹyin ti owo ẹrú dopin amọ o ti lowo, o lọla, to si laami laaka saaju nidi owo ẹrú ṣíṣe,

Bẹẹ ni ibudo kan wa nilu Badagry bayii, ti wọn ya sọtọ bii ìṣe nnkan isẹnbaye lọjọ si, fun iranti ọba Seriki Williams Ifaremilekun Abass.

Efunsetan Aniwura

Oríṣun àwòrán, others

Idile Efunsetan Aniwura:

Idile Obìnrin takuntakun miran nidi kata-kara owo ẹru ni idile Oloye Efunsetan Aniwura, tii ṣe Iyalode keji nilẹ Ibadan.

Idi owo ẹrú si ni akọni obinrin naa ti ri taje ṣe bii Efunroye Tinubu, oun naa lowo, o lọla, o gbajumọ, to si n dari ọpọlọpọ ọkùnrin labẹ rẹ.

Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni Efunsetan pẹlu, oko-owo si lo gbe de ilu Ibadan nibi to ti gbọrẹgẹ-jigẹ ninu owo ẹrú ṣíṣe, to si di ara awọn alagbara to n dari ilu Ibadan.

Akọsilẹ si fi ye ni pe, Efunsetan maa n ni to ẹgbẹrun meji ẹru to maa n ko lọ ta nilu Badagry loore koore,

To si tun ni awọn ẹru to n ṣíṣẹ fun ninu ile, ti ẹru-binrin rẹ kankan ko si lori laya lati loyun, kiku ni onitọun yoo ku, lati ipasẹ ida.

Ẹfunroye Tinubu

Oríṣun àwòrán, others

Efunroye Tinubu:

Idile miran to tun gbajumọ fun owo ẹrú ṣíṣe ni idile oloye arabinrin Efunporoye Osuntinubu, ti adape rẹ n jẹ Efunroye Tinubu.

Obìnrin takuntakun, obinrin to ju ọkùnrin lọ, obinrin to si n fi ọba jẹ tabi rọ ọba loye ni arábìnrin Tinubu nigba aye rẹ, ẹni to yan kata-kara owo ẹrú laayo nigba aye rẹ.

Ọmọ ilu Abeokuta ni Tinubu, o fẹ ọpọ ọkọ nigba aye rẹ, lara wọn si ni Oba Adele Ajosun tilu Eko, to fẹ lọdun 1833 nilu Abeokuta nigba ti wọn rọ Oba naa loye, to si sa lọ silu Egba.

Ọba Adele ati Tinubu tun ko lọ silu Badagry, ti ọba naa si ran Tinubu lọwọ lati gbọrẹgẹ-jigẹ ninu owo ẹru ṣíṣe nilu ọhun,

Nibe ni obìnrin takuntakun naa si ti ni awọn ọmọ ogun to maa n ran nisẹ lati lọ jagun, ko ẹrú wa fun lati ta fun awọn oyinbo.

Kabiyesi Ọba Kosọkọ

Oríṣun àwòrán, others

Idile Ọba Kosoko tilu Eko:

Idile ọba Kosoko tilu Eko naa wa lara idile to gbaju-gbaja nilẹ Yoruba fun owo ẹru ṣiṣe,

Kosoko si jọba nilu Eko laarin ọdun 1845 si 1851, ki wọn to le kuro lori itẹ.

Ọba Kosoko gbajumọ bii isana ẹlẹẹta fun owo ẹru ṣiṣe, ọpọ igba si ni awọn oyinbo ti ṣipẹ fun un ko pinwọ owo ẹru,

Amọ ti ko dahun pẹlu awijare lọdun 1851 pe ayafi ti Oba Benin ba sinmi owo ẹru, ni oun naa yoo jami lori rẹ.

Eyi si wa lara ẹsun tawọn oyinbo amunisin ka si Oba Kosoko lọrun, ki wọn to rọ ọ loye, to si sa lọ silu Badagry pẹlu Balogun rẹ, Oshodi Tapa, níbi ti owo ẹru rẹ tun ti buyaari.