World Sickle Cell Day: Àwọn ǹkan ti alárùn SS kò gbọdọ̀ ṣe fún alááfíà ara - Dókítà Igbekele

Arabinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oogun ti wa fun aarun sickle cell

Ni igba akọkọ ti wọn yoo ṣe ayajọ ọjọ aisan arunmọleegun, ajọ isọkan agbaye lo kọkọ ṣe agbekalẹ rẹ lọdun 2008.

Wọn ṣee lati bẹrẹ si ni mọ aisan foniku fọla dide ati idojukọ awọn to n ṣaisan yii lagbaye.

Lẹyin ọjọ yii ni ajọ isọkan agbaye wa ya gbogbo ọjọ ikọkandinlogun, oṣu kẹfa sọtọ lati maa ṣe ayajọ ipolongo aisan foniku fọla dide lagbaye.

Ẹwẹ, oju lasan ni ọpọlọpọ ri lara awọn alaisan yii ṣugbọn gẹgẹ bi iwadi ṣe fi han, diẹ lara awọn nkan ti ẹ ko mọ tabi ti ẹ ko tii gbọ ri nipa awọn to n ṣaisan foniku fọla dide pọ.

Bi ẹjẹ alarun runmọleegun se ri

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ohun méje tí o kò gbọ́ rí nípa aláìsàn fòníkú fọ̀ladìde

Gẹgẹ bi Dokita ọmọ Naijiria kan to tun wa ni ilu London fun imọ ẹkọ, Ogunboye Igbekele ṣe sọ fun BBC Yoruba, ọpọ nkan ni ẹ ti mọ tẹlẹ nipa awọn alaisan foniku fọla dide bii ki egungun maa ro wọn.

O sọ nipa aya didun, inu rirun, oju wọn maa ni awọ pupa rẹsurẹsu, ati ki wọn maa padanu ẹjẹ pupọ ṣugbọn awọn ohun ti ẹ le ma mọ ree.

Dokita Igbekele lori iduro
Àkọlé àwòrán, Dokita igbekele salaye awon ipenija to maa n koju awon alaarun foniku fọladide

Awọn eyi to yẹ ni mimọ lasiko yii ni:

1. Ibẹru IkuIdamu inu ọpọlọ leyi nitori pe ọpọlọpọ wọn lo n bẹru iku ṣugbọn ti wọn ko le sọ ọ jade.

Nilẹ Afirika paapaa ju lọ ni Naijiria, bi wọn ba sọ ọ sita, awọn eeyan a ni wọn o nigbagbọ.

Awọn yii kan naa ni wọn a ni nilẹ Yoruba, bi wọn ba ti le kọja ọgbọn ọdun laye, wọn ti ye e niyẹn.

Tori eyi, awọn agba a maa gba awọn alaisan foniku fọla dide nimọran ki wọn tete fẹ ọkọ tabi iyawo ki wọn le tete bi ọmọ saye tori ti wọn o ba ku.

Atẹ awon eniyan ti eje won bara mu

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ohun méje tí o kò gbọ́ rí nípa aláìsàn fòníkú fọ̀ladìde

2. Ibẹru ta ni yoo fẹ mi lọkọ abi laya?Nigba miran, wọn ko ki n fẹ sọ ẹya ẹjẹ (genotype) wọn tori bi ẹlomii to ti yo ifẹ wọn. tẹlẹ ba gbọ eyi, o ṣeeṣe ko fẹsẹ fẹẹ ki ifẹ naa ka kuro loju rẹ

Eyi ko ṣẹyin lilọ họsibitu lonii, họsibitu lọla, daku lonii, ji lọla, wọn ko ki n le sọ fun ẹnikẹni ju ki wọn bo o mọra wọn lọkan lọ.

Àkọlé fídíò, Ọba Olutayọ: ìgbésẹ̀ Ọọni àti Alaafin ti ń mú ìṣọ̀kàn dé sáàrin àwọn Ọba Yorùbá

3. Ẹlomii wọn a maa ni iṣoro to le lasiko nkan oṣu wọn ni ti awọn obinrin.

4. Nigba mii, obi le ma tete ri apẹrẹ aisan yii lara ọmọ ti wọn ba ṣẹṣẹ bi titi yoo fi pe oṣu mẹfa tabi ọdun kan ti ọmọ naa ba bẹrẹ si ni ṣe aisan ati to n padanu ẹjẹ.

Pẹlu eyi ni dokita tabi nọọsi fi le mọ.

5. Njẹ ẹya ẹjẹ SS lee yipada?

Dokita Igbekele jẹ ko di mimọ pe ni ilana iṣegun oyinbo, ko ṣee ṣe rara ki ẹya ẹjẹ eeyan yi pada

O ni o ri bẹẹ nitori pe awọn onimọ iṣegun oyinbo ko gbagbọ ninu eyi rara lodi si bi awọn kan ṣe maa n ti ẹsin igbagbọ bọ ọ pe adura maa n yi ẹya ẹjẹ pada.

Awon wonyii a maa rọ igbagbọ wọn mọ ọ ti yoo si ri bẹẹ bi wọn ba tun ayẹwo ṣe.

Ẹwẹ, dokita ṣalaye pe bi wọn ba gbe eroja inu egungun (Bone Marrow) ẹni to jẹ AA fun apẹrẹ sinu ẹni to jẹ SS lati parọ rẹ, eyi ṣeeṣe o si wa lati wo o san ni ṣugbọn ko yi ẹya SS to ti wa ninu gbogbo ẹya ara to ku pada.

6. Ta ni SS ko gbudọ fẹ laelae?Dokita Igbekele sọ pe SS ko gbudọ daba rara lati fẹ AS. "Agbako gbaa leleyii".

"Awọn ẹya mii to tun wa ni AC SC ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣugbọn ọmọ iya kan naa ni wọn pẹlu SS".

7. Dokita jẹ ko di mimọ pe ẹya ẹjẹ kan ṣoṣo ti ẹni to jẹ SS le fẹ ni AA.