Abiola Ajimobi: APC àti ALGON ti mú àbá tuntun jáde lórí ọ̀rọ̀ gómìnà Ọyọ àná

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni ipinlẹ Oyo ati ẹgbẹ awọn alaga ijọba ibilẹ, ALGON, ẹka tipinlẹ Oyo, ti bẹrẹ eto aawẹ ati adura fun ilera adele alaga ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi.
Atẹjade kan ti ẹgbẹ APC fisita nilu Ibadan wa rọ gbogbo ẹmọ ẹgbẹ wọn lati gba awẹ ati adura ẹjọ mẹtanaa, eyi to bẹrẹ ni ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun oṣu kẹfa ọdun 2020.
" A rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC lati gbadura kikan kikan fun gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Sẹnetọ Abiola Ajimobi. A gbadura ki ara rẹ ya kia kia".
Ninu atẹjade mii ti alaga ẹgbẹ ALGON, ọmọba Ayodeji Abass Aleshinloye fọwọ si, o jẹ ko di mimọ pe ajọgba ni awẹ ati adura naa ko ba jẹ nita gbangba ṣugbọn nitori akoko ti a wa yii, eyi ti Coronavirus n dari, ni wọn ṣe ni ki onikaluku gba a ni adagba.
O ni "yala ẹnikẹni ro iku tabi iye ro o, gbogbo eeyan lo jẹ gbese iku ti wọn si gbudọ san, tori naa, ki lo de taa fẹ kanju tufọ rẹ nigba ti akoko rẹ ko tii to. Eewọ ni koda nile alaye ka maa ro iku ro ọta ẹni".
"Ọlọrun lo n fun ni, to si ngba a, fun idi eyi ko sẹni to lagbra lori aye ẹlomiran".
Abass ni ọlọyaya eeyan ni sẹnetọ Ajimobi, o si yẹ ki awọn ọmọ Naijiria kọ eti ikun si iru iroyin bẹẹ.
Bi ẹ o ba gbagbe, sẹnetọ Abiola Ajimobi to jẹ wipe ara rẹ ko ya nitori pe o lugbadi COVID-19, ni awọn kan n tan iroyin kalẹ pe o ti ku.
Ẹgbẹ ALGON Oyo ni "a fẹ fi yee yin pe, Sẹnetọ wa Abiola Ajimobi, adari wa ko ku, ko si ni ku bi ko ṣe yiye".

Oríṣun àwòrán, Instagram/ajimobi
Wọn ni "Ajimobi ti a mọ si ẹni to kọ Oyo ode oni ṣe iṣẹ ribiribi, o si tun sin ipinlẹ rẹ fun odidi ọdun mẹjọ, ko si wa yẹ ki wọn ro iku ro o, paapaa lasiko yii ti o ti gba igbega lati tukọ ẹgbẹ oṣelu APC ni gbogbo Naijiria.
Ohun tí a rí nílé Ajimobi rèé lẹ́yìn ìròyìn òfégè pé ó jáde láyé

Ninu igbiyanju wa lati fi idi otitọ mulẹ lori awuyewuye to n lọ ni igboro, ikọ BBC Yoruba ṣe abẹwo si ile gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi.
Ile naa wa ni agbegbe Oluyọle ni ilu Ibadan, ṣugbọn a ko ri ẹnikẹni ti o le ba wa sọrọ nibẹ.
Paroparo ni ayika ile naa da lasiko ti a ṣe abẹwo sibẹ lọsan ọjọ Ẹti.
Lọwọlọwọ, ile iwosan kan lagbegbe Ikoyi ni ilu Eko ni iroyin ni Ajimobi wa lasiko yii.
Ọpọ igba ti gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ọyọ naa ko ba si nile ni Ibadan naa ṣi ni lawọn ololufẹ rẹ kan tabi meji ṣi maa n wa bẹ ile naa wo lati ṣe baba kẹẹ pẹ si 'Akanji' gẹgẹ bi ọpọ tun ṣe maa n pe e.




Nigba ti akọroyin BBC News Yoruba de agbegbe ile rẹ ni Oluyọle Estate gbogbo ọna abawọle mejeeji to wọ adugbo Agbaoye ibadan naa lo da paroparo ti wọn si ti abawọle ile rẹ gba-gba-gba.
Koda, ko si ero ni titi nitori gbogbo adugbo naa da waiwai ni.

Abiola Ajimobi: Kíni ó ń ṣẹlè sí Senetọ Abiola Ajimobi?
Ẹbi Gomina àná ni ipinlẹ Oyo, Senetọ Abiola Ajimọbi ti jade sita wa sọ pé irọ ni pe Ajimọbi ku!
Wọn ni ahesọ lasan ni ọrọ tó n ja ranyinranyin nilẹ pe igbakeji alaga ẹgbe oṣelu APC naa ti jade laye nipasẹ ajakalẹ arun coronavrus.
Fatima Ganduje Ajimọbi to jẹ ọmọ gomina Abdullahi Ganduje to n tukó ipinlẹ Kano to fẹ ọmọkunrin Abiola Ajimobi fi ọrọ naa lede loju opo twitter rẹ pe irọ ni.
Ahesọ yii ko ṣẹyin bi wọn ṣe kọkọ n sọọ kiri pe Ajimọbi ti lugbadi Covid 19 to si n gba itọju nile iwosan aladani kan ni ipinlẹ Eko.
Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kéfa yii ni agbẹnusọ fun Senetọ Ajimọbi, Ọgbẹni Bolaji Tunji ti ba BBC Yoruba sọrọ ninu ifọrọwanilenuwo lori ohun to n ṣẹlẹ si Ajimọbi. sọrọ.
O ni Ajimọbi ti ṣelẹri lati yanju aawọ ẹgbẹ oṣelu APC lasiko ipade apapọ ẹgbẹ ti NEC to m bọ lọna.
Sugbọn Agbẹnusọ Ajimọbi kò sọ nipato lati dahun ibeere boya Ajimọbi ni arun Coronavirus tabi bẹẹkọ rara.
Eyi ko si ṣẹyin awuyewuye to n ṣẹlẹ nipinlẹ Edo lori ọrọ Gomina Obaseki ati Adams Oshiomọlẹ to jẹ alaga ẹgbẹ APC.
Ṣaaju ni ẹgbẹ ti kọkọ kede Ajimobi gẹgẹ bii adele alaga kuro nipo igbakeji alaga to wa tẹlẹ.
- Ṣé lóòtọ́ ni òjòjò dá Abiola Ajimobi wólẹ̀?
- Ọmọ atàpátadìde ni mí, télọ̀ ni bàbá mi- Abiola Ajimobi
- Seyi Makinde, bàtà tí Ajimobi bọ́ sílẹ̀ ni ko tẹsẹ̀ bọ̀ fún àṣeyọrí Ọyọ - APC
- Arisekola ló fún mi ní ilẹ̀ tí ìjọba Ọyọ gbẹ́sẹ̀ lé, ń kò ní gbà - Ajimobi
- Ayefele fi orin ẹ ṣeun sẹ́nu kí Ajimobi
- Seyi Makinde, yé é sọ̀rọ̀ mi láìdà - Gomina Ajimobi
Bakan naa ni Fatima tun dupẹ lọwọ awọn eeyan to n pe lati beere nipa Baba wọn Ajimọbi, o pari ọrọ rẹ pe ko si ẹni ti ko ni ku lọjọ kan ṣugbọn ẹbi Ajimobi n dupe pe o ṣi wa laaye.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ abiola ajimobi
Ṣé lóòtọ́ ni òjòjò dá Abiola Ajimobi wólẹ̀?
Bi awọn eeyan kan ṣe n sọ pe egungun agba oṣelu naa ṣe bi ẹni jinna si ode ijo fun igba pipẹ lawọn miran n sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ọrọ coronavirus yii to jawe joko jẹẹ fun gbogbo mutumuwa naa lo kan baba.
Ni ọsẹ to kọja ni BBC News Yoruba gbe iroyin jade to n beere ibi gan an ti ọkọ Florence wa.
Amọṣa, lọwọ yii iroyin to n lọ kaakiri ni pe o ṣeeṣe ki ojojo maa ṣogun Abiọla Ajimọbi ki ara ogun rẹ o maa le.
Ọpọ lo tilẹ n wi pe o ṣeeṣe ki o jẹ pe aisan rẹ fẹ le diẹ lo jẹ ki baba Abimbọla o lọ fidimọle sibi kan.
Ohun ti awọn iroyin miran to n lọ kaakiri tilẹ tun n sọ ni pe ileewosan kan lagbegbe Ikoyi ni ilu Eko ni wọn gbe agba oṣelu naa lọ bayii fun itọju.
Ohun to wa mu ki gbongbo iroyin yii tun fẹ ṣe bi ẹni gbilẹ sii bayii ni ti atẹjade kan ti ẹka ẹgbẹ oṣelu APC ni ilẹ Gẹẹsi gbe jade loju opo twitter rẹ nibi to ti n ki igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹ-ede Naijiria naa pe ko ṣara giri, aisan ko ni bori rẹ rẹ.
"A o maa gbadura fun ajinde ara ni kiakia fun ọ. Bi ọjọ ti ṣe n gori ọjọ naa ni ilera pipe n sun mọ ọ. Ero ilera pipe ni kiakia ni a n fi ranṣẹ si ọ-APC UK"
Ti wọn si tun fi fidio kan tii nidi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
- Àwọn akẹgbẹ́ ẹ̀ṣọ́ àjọ FRSC mẹ́ta tí àrá sán pa l'Ogun gbọdọ̀ ṣ'ètùtù- Elebubọn
- Àwọn ohun tuntun tí a mọ̀ nípa ìgbẹ́jọ́ Wòlíì Sotitobire
- Ṣé lóòtọ́ ni Sẹ́netọ̀ Bayo Osinowo ní ìfura ikú ara rẹ̀?
- Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá dá wàhálà sílẹ̀ l'Eko
- Gómìnà márùn ún tó fojú winá ìbínú bàbá ìsàlẹ̀ wọ̀n
- A kò tíì fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ògùn Dexamethsaone ń ṣiṣẹ́ fún àrùn coronavirus- WHO
Ileẹjọ giga l'Abuja ni ohun ti ṣe afikun igba ti Ọgbẹ Giadom yoo nipo adele alaga gbogbogbo APC pẹlu ọsẹ meji.
Victor Giadom: Iléẹjọ́ gíga pàṣẹ pé kí Giadom jẹ adelé alága APC
Victor Giadom gbàṣẹ iléẹjọ́ gíga láti jẹ adelé alága APC
Igbakeji akọwe apapọ agba ẹgbẹ oṣelu APC, Victor Giadom ti gbaṣẹ lati ileẹjọ eyi to fun un lanfaani lati maa tukọ ẹgbẹ naa gẹgẹ bi adele alaga gbogbogbo APC.

Oríṣun àwòrán, Other
Gẹgẹ bi akọsilẹ ileẹjọ giga niluu Abuja ṣe sọ, ileẹjọ ti fikun asiko ti Giadom yoo lo gẹgẹ bi adele alaga gbogbogbo APC.
Ileẹjọ giga l'Abuja ni ohun ti ṣe afikun igba ti Ọgbẹ Giadom yoo nipo adele alaga gbogbogbo APC pẹlu ọsẹ meji.

Ọjọ kẹfa oṣu kẹta ni ileẹjọ kọkọ paṣẹ pe ki Victor Giadom maa ṣe ojuṣe gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu APC.
L'Ọjọru ni igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ APC kede pe Giadom ko si lara awọn oloye ẹgbẹ naa mọ, wọn ni ko si ni ipo to di mu tẹlẹ mọ lati ọdun 2018.
APC ṣalaye pe Giadom kọwe fipo silẹ lọdun 2018 lati dije ipo igbakeji gomina nipinlẹ Rivers.

'Ètò ìdìbò sípò gómìnà Ondo, Edo yóò wọ́lẹ̀ nítorí rògbòdìyàn APC '
O seese ki eto idibo nipinlẹ Edo ati Ondo ki o ma lọ ni ọna ti awọn eniyan foju si nitori rogbodiyan to n waye nibẹ.
Onwoye eto oṣelu lawujọ, Yemisi Fadairo ni ija ati asọ to n ṣẹlẹ ni ẹgbẹ oṣelu le mu ki awọn eniyan dibo fun ẹgbẹ oselu miran to yatọ ẹgbẹ oselu APC ati PDP.

Oríṣun àwòrán, Others
Fadairo ni a ko le sọ ibi ti idibo naa yoo fori sanpọn si nitori Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti kuro ni ẹgbẹ oselu APC,
Bakan naa ni wọn ko ni alaga ẹgbẹ oselu ẹyọkan nitori ẹniyan mẹta ni wọn ti kede pe awọn ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC.
O fikun un pe ni ipinlẹ Ondo, ẹgbẹ oṣelu APC naa n koju aigbọraẹniye pẹlu bi igbakeji gomina ati gomina ipinlẹ naa ṣe n figagbaga lori ẹni ti yoo dije dupo nibẹ,
Eleyii ti o fihan pe igbakeji gomina naa ti yapa kuro ni ẹgbẹ oṣelu APC, amọ ti ko i tii fi lede ẹgbẹ oṣelu ti o ti fẹ dije dupo gomina.
Bakan naa, Fadairo ni ẹgbẹ oṣelu PDP naa ko i tii na ọwọ ẹnikẹni soke pe oun ni yoo dije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP,
Eleyii to ni o fihan pe ile ti wọn naa ko tooro rara.

Oríṣun àwòrán, Other
Imọran Onwoye eto oṣelu lawujọ naa ni wi pe ki awọn ẹgbẹ oṣelu yii pari aawọ to wa laarin wọn, ki wọn si tun ile wọn tọ daadaa nitori awọn ara ilu.
Bẹẹ lo kesi Aarẹ orilẹ-ede Niajiria lati maṣe foju kekere wo iṣẹlẹ to n waye ninu ẹgbẹ oṣẹlu APC, amọ ki o pẹẹtu saawọ naa, ki eto iṣejọba tiwantiwa ba le kẹsẹjari.
Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa ìdí tí Victor Giadom fi gbà'jọba ẹgbẹ́ òṣèlú APC
Victor Giadom ti kede pe oun ko dede darukọ ara oun gẹgẹ bi Alaga ẹgbẹ oselu APC, amọ ile ẹjọ lo na ọwọ soke gẹgẹ bi adele Alaga ẹgbẹ oselu APC.
Eyi ko ṣẹyin gbọnmisi omi oto to n waye ni ẹgbẹ oṣelu lẹyin ti ajọ amuṣẹya ẹgbẹ naa yan eniyan mẹta gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ laarin wakati mẹrinlelogun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ abiola ajimobi
Ajọ amuṣẹya APC, NWC tun yan Hilliard Etta lati ma a ṣiṣẹ dele de Abiola Ajimobi to wa ni idubulẹ aisan, amọ Victor Giadom sọ wi pe apo ara wọn ni wọn sọ iyẹn si.
Giadom ni ileejọ to kọkọ yọ Adam Oshiomole kuro nipo, fi lede wi pe oun gẹgẹ bi Akọwe ẹgbẹ ni ki o jẹ adele alaga titi wọn yoo fi yan alaga miran.


O ni igba ti wọn ba to da ẹjọ ileẹjọ giga naa nu ki ẹnikẹni to le yọ oun nipo, amọ o dabi ẹni pe ajọ amuṣẹya APC ko ka idajọ ileejọ giga to fi jẹ adele alaga si, ti wọn si kede ẹni ti o jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ na ni Gusuu Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Gẹgẹ bi adele Alaga, Giadom ti da gbagbo igbese ti Oshiomọle ru patapata lati Osu Kẹta, to fi mọ ayẹwo awọn oludije fun ipọ gomina ninu idibo sipo gomina nipinlẹ Edo.
Amọ, ti ẹgbẹ oṣelu APC ko ba tete wa wọrọkọ fi sada lori ọrọ ipọ alaga ẹgbẹ oṣelu naa, yoo da wahala silẹ fun idibo sipo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Ondo ati Edo.
Bawo ni Giadom ṣe di adari ẹgbẹ oṣelu APC?
Ọkan gboogi ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Sogbogbe Eli lo kọkọ fi idi ẹ mulẹ pe awọn ipo adari ninu ẹgbẹ oṣelu APC ṣofo ni Giadom ṣe di adele alagba.
Sogbogbe ni o asiko ti Adam Oshiomole yọ gbogbo awọn adari nipo ni ileẹjọ wa gbe ọpa aṣẹ le Giadom lọwọ lati tukọ ẹgbẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Jubril A. Gawat
Sinimá àwòòwòtán lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC; tani alága APC láàrín Ajimobi àti Victor Giadom?
Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni yajoyajo n fi ye ni pe, igbakeji akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu APC, Victor Giadom ti bọ sori oye gẹgẹ bii adele alaga apapọ ọgbẹ oṣelu naa.
Ọrọ ti di iṣu ata yanan-yanan bayii lẹgbẹ oṣelu APC bayii pẹlu bi ẹgbẹ oṣelu naa ṣe n ni adele alaga apapọ meji laarin wakati diẹ si ara wọn.
Ni kete ti ile ẹjọ paṣẹ ki Adams Oshiomole o fi ipo silẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC ti kede rẹ pe Sẹnetọ Abiola Ajimọbi gẹgẹ bi adele alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa.
Amọṣa ko pẹ pupọ ni ẹni to jẹ igbakeji akọwe agba ẹgbẹ oṣelu ọhun, Victor Giadom jade sigboro pẹlu iwe idajọ lati ile ẹjọ kan eleyi to ni oun ni o tọ si lati di ipo naa mu.
Ni ọjọru si ni Gaidom gun ori aga naa gẹgẹ bi adele alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ni kete ti o si ti wọle ni o ti kede pe oun n gba akoso ni ibamu pẹlu idajọ ile ẹjọ to ni o fun oun lagbara ati ṣe bẹẹ.
Bakan naa lo wọgile eto ayẹwo awọn oldije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Edo.
O fi kun un pe gba-gba-gba lawọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ ẹgbẹ oṣelu naa wa lẹyin oun lori igbesẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi
APC: Ajimobi di adelé alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú
Ajọ Amuṣẹya ẹgbẹ oṣẹlu APC, NWC ti kede Sẹnetọ Abiola Ajimobi gẹgẹ bi Alaga ẹgbẹ tuntun ni Ila Orun orilẹede Naijiria.
Eyi ko seyin idajọ ileejọ kotẹmilọrun ni ilu Abuja to fi ontẹ lu u pe ki wọn yọ Adam Oshiomọlẹ gẹ̀gẹbi Alaga ẹgbẹ oṣelu naa.
NWC fi lede wi pe ni itẹle idajọ Ileejọ Kotẹmilọrun lo mu ki awọn gbe igbesẹ naa lọna to ba ofin ẹgbẹ mu.
Amọ, nibayii ohun ti awọn eniyan n sọ ni wi pe Sẹnetọ Abiola Ajimọbi wa ni idubulẹ aisan lati bii lóṣu diẹ sẹyin.
Bakan naa, awọn eniyan to n fi ero wọn han lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter ni ko ye ki ẹgbẹ oṣelu APC fi ẹni to wa lori idubulẹ aisan ṣe alaga ẹgbẹ lasiko ti idibo n bọ lọna ni ipinlẹ Ondo ati Edo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4

Oríṣun àwòrán, Instagram/ abiola ajimobi
Abiola Ajimobi: Awuyewuye ń lọ lórí afẹ́fẹ́ nípa ipò ìlera gómìnà Ọyọ àná
Gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ ni Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, ko si si bi iru wọn yoo ṣe gbin ti gbogbo ilu ko ni ṣojojo.
Ni aarin ọsẹ yii ni iroyin kan jade si igboro aye pe lori idubulẹ aisan ni gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ ọhun wa ni ileewosan nla kan nilu Eko.
Iroyin naa tilẹ fi kun un pe ni ọsẹ to kọja ni wọn gbe Sẹnetọ Ajimọbi digbadigba lọ sileewosan ti a n sọrọ rẹ ọhun nigba ti ọrọ ilera rẹ n ṣebi ẹni fẹ maa mẹhẹ eleyi to si n da aya ja awọn mọlẹbi rẹ.
Wọn ni jiji ti Oloye Ajimọbi ji lọjọ naa lati ṣ'ẹmi ara to si pada ls si inu yara rẹ lo ba ṣubululẹ daku rangbọndan ki awọn ẹṣọ rẹ to gbee digbadigba lọ si ileewosan.
Amọṣa, ninu ilepa ati mọ boya lootọ ni iroyin yii tabi irọ ni BBC News Yoruba ti fi ipe ṣọwọ si ọkan lara awọn eeyan to sun mọ igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu APC naa lati mọ ootọ ọrọ naa.
Ohun ti onitọhun ti ko fẹ ki a darukọ oun ṣe lalaye ni pe ko si ootọ kan ninu iroyin naa ati pe ṣaka lara baba le.
Fidio kan to fi sita loju opo instagram rẹ lọjọ kini, oṣu karun un ni Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ṣi ti n ki ijọba apapọ atawọn oṣiṣẹ eto ilera ati aabo fun iṣẹ takuntakun ti wọn n gbe ṣe lori igbesẹ ati dẹkun itankalẹ ajakalẹ arun coronavirus lorilẹ-ede Naijiria.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Bakan naa lo farahan nibi eto idanilẹkọ ori afẹfẹ kan eleyi ti ileeṣẹ redio kan ṣe lasiko awẹ Ramadan to waye loṣu karun nibi ti o ti ko ipa gẹgẹ bi alaga eto idanilẹkọ awẹ naa
Pẹlu iroyin to n ja ranyinranyin nilẹ yii ati ohun ti ẹni to sun mọ Sẹnetọ Ajimọbi sọ yii, ibeere to wa gbode lẹnu awọn ololufẹ agba oṣelu yii atawọn onwoye ni pe:
'Nibo gan an ni Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi wa lọwọ yii'?
















