Tope Alabi, Ron Kenolly àtàwọn míì yóò kọrin níbi ọjọ́ ìbí àṣẹ̀yìndè fún olóògbé Ighodalo lónìí

Aworan olorin ẹmi, Tope Alabi ati Oloogbe Ibidunni

Oríṣun àwòrán, Topealabi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Olorin kan lo kọrin pe "bi a ba n jẹ, bi a ba n mu, bi a ba n fitan ewurẹ jẹ'ka o, ka ma gbagbe pe atipo o la jẹ laye o.

Ọrọ orin naa rinlẹ, to bẹ to mu ni ranti iku oloogbe Ibidunni Ighodalo arẹwa obinrin aya Pasitọ ijọ Trinity House to jẹ Ọlọrun nipe ninu oṣu kẹfa nigba to ku jọ di ko pe ogoji ọdun.

Yoo wa pe ogoji ọdun ọhun lọla ṣugbọn kii ṣe lorilẹ aye.

Ẹwẹ, awọn gbajugbaja olorin ti pọ rẹpẹtẹ ti yoo ṣe isin orin nibi ọjọ ibi aṣẹyinde oloogbe naa lonii lati ago mẹjọ alẹ wọ mejila oru ti yoo ti bọ si ọjọ ibi rẹ.

Awn olorin ẹmi ni Naijira ati lati awọn orilẹede mii - Tope Alabi, Ron Kenolly, Sammy Okposo, Yetunde Are, TY Bello, Muyiwa Olanrewaju, BJ SAx, Ibiayo Jeje, Polmira, USA, Alabi Oke, Psalmos, Efe Nathan, Seyi Ajayi, Tosin Alao, Mike Aremu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Amọ iṣọ oru ni wọn yoo fi ṣe eyi ti yoo bẹrẹ lati ago mẹjọ alẹ si mejila oru gẹgẹ bi ijọ Trinity House ati ọkọ oloogbe to jẹ pasit ijọ naa ṣe fi si ori ayelujara wọn.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Aworan Oloogbe Ibidunni

Oríṣun àwòrán, Topealabi

Aworan olorin ẹmi, Tope Alabi ati Oloogbe Ibidunni

Oríṣun àwòrán, Topealabi

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lara eto ti wọn tun la kalẹ fun ayyẹ naa ni pe ajọ ti Ibidunni da silẹ ko to lọ iyẹn Ibidunni Ighodalo Foundation yoo ṣe onigbọwọ fun lọkọlaya ogoji tii ṣe dede iye ọdun to pe, lati lọ ṣe ayẹwo ati itọju iṣoro ibimọ.

Wọn ko awọn olorin iyin jọ lati gbe ohun iyin soke si Ọlọrun nitori oloogbe aya pasitọ Ituah Igbhodalo.

Aworan olorin ẹmi, Tope Alabi ati Oloogbe Ibidunni

Oríṣun àwòrán, Topealabi

Bi ẹ o ba gbagbe, owurọ ọjọ aiku ọjọ kẹrinla oṣu kẹfa ni oloogbe Ibidun Ighodalo ku ninu yara rẹ nile igbafẹ kan ni ilu PortHarcourt latari ikọlu inu ọkan gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ.

Bo tilẹ jẹ pe idile, awọn ọrẹ atawọn ololufẹ rẹ ti n ṣeto bi ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun ogoji rẹ yoo ṣe ri ṣugbọn ọlọjọ de ko to di ọjọ kọkandinlogun oṣu keje ọdun 2020.

Aworan Oloogbe Ibidunni

Oríṣun àwòrán, topealabi

Ó di gbéré! Arẹwà Ibidunni Ighodalo wọ káà ilẹ̀ lọ nílùú Eko

Ibidun Ighodalo

Oríṣun àwòrán, Instagram/trinityhouseng

Iku o dọjọ, aarun ko doṣu. Ọjọ Abamẹta tii ṣe ogunjọ oṣu kẹfa ọdun 2020 ni arẹwa Ibidunni Ighodalo wọ kaa ilẹ lọ niluu Eko.

Ti eeyan ba jẹ ori ahun, to ba ba de ibi isinku Ibidunni, omi gbọdọ bọ loju rẹ.

Ọgọrọ eeyan lo peju pesẹ sibi eto isinku naa lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un.

Awọn eeyan jankanjankan lo wa nibi isinku naa, ninu wọn ni Gomina Rotimi Akeredolu ipinlẹ ONdo.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Pasitọ Idowu Oluyomade to jẹ amugbalẹgbẹ alufaa Enoch Adeboye ijọ Redeem naa wa nibi eto isinku ọhun.

Alufaa Adeboye ti kọkọ sọ siwaju pe oun mọ pe Ibidunni ti wa nibi to dara bayii.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Daju daju, gbogbo agbaye lo n ṣelede lẹyin ẹniire to lọ, arẹwa obinrin, aya pasitọ ijọ Trinity House lorilẹede Naijiria, Ibidunni Ighodalo.

Eyi lo mu ki igbakeji aarẹ orilẹede Liberia, arainrin Jewel Howard Taylor fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ ati adura fun idile to fi silẹ lọ.

Arabinrin Jewel fi ọrọ sita loju opo instgram rẹ bii ewi pe " aye wa ṣe ri firi to da bi eyi ti ko pẹ rara koda bi a ba ṣi wa laaye.

"Lọsẹ yii a ti padanu arabinrin wa, ẹni daradara ati arẹwa obinrin, Ibidunni."

O wa gbadura pe ki Ọlọrun ko tu ọkọ, ọmọ, ẹbi ati ọrẹ oloogbe ninu.

Ibidun Ighodalo

Oríṣun àwòrán, Instagram/ibidunni_ighodalo

Igbakeki aarẹ Liberia ni iba wu oun ki awọn lee fa a pada lẹẹkan sii ṣugbọn o ti di alaarira tori o ni o daju daju, Ọlọrun ti nilo ko wa si ajule ọrun ni.

Ọjọ kẹrinla oṣu kẹfa, ọdun 2020 ni arabinrin Ibidunni dagbere faye lẹni ọdun mọkandilogoji to ku oṣu kan pere ko ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun.

Ètò ìsìnkú Ibidunni Ighodalo wáyé lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán

Ijọ Trinity House ti sọ pe eto isinkun aya oludasilẹ rẹ to doloogbe, Ibidunni Ighodalo yoo waye lori ẹrọ amohunmaworan bo ba ṣe n lọ lọwọ.

Isinku ọhun yoo waye lọjọ Abamẹta, ogunjọ oṣu kẹfa ọdun 2020.

Ibidun Ighodalo

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ibidun Ituah Ighodalo fayé silẹ̀ ìlúmọ̀ọ́ká arẹwà tí fáyésilẹ̀

Iroyin ni awọn eeyan kereje atawọn eeyan diẹ to sun mọ oloogbe naa ni wọn fiwe pe sibi isinkun naa.

Ijọ Trinity House sọ pe eto isinku ọhun yoo waye lori ẹrọ ileeṣẹ Arise TV lori itakun DSTV channel 416 ni aago mẹrin irọlẹ.

Bẹẹ naa ni awọn eeyan tun lee wo bo ba ṣe n lọ loju opo Facebook, Twitter, Instagram ati YouTube.

Wọn tun sọ pe idagbere ikẹyin yoo waye lori ẹrọ amohunmaworan AIT, lori ikanni DSTV channel 253.

Ọjọru ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹfa ọdun 2020 ni wọn ṣe eto aṣalẹ orin onigbagbọ fun oloogbe naa.

Lara awọn kọ orin nibẹ ni ọmọ rẹ obinrin, ọkọ rẹ, pasitọ Ituah Ighodalo ati gbajugbaja olorin ẹmi, Tope Alabi.

Ọjọ kẹrinla oṣu kẹfa ọdun 2020 ni obinrin naa dagbere faye.

Pásítọ̀ Adeboye ní òun mọ̀ pé ibi tó dára ni Ibidun Ighodalo wà báyìí

Oloogbe Ibidunni Ighodalo

Oríṣun àwòrán, Instagram/ibidunnuighodalo

Pasitọ agba ijọ Redeem, Enoch Adeboye ti sọ pe ibi to dara ni oloogbe orekelẹwa Ibidunni Ighodalo wa.

Pasitọ Adeboye fọrọ yii lede loju opo Twitter nigba ti o n daro arẹwa to dagbere faye.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Alufaa Adeboye ni iroyin to ba ni ninu jẹ ju iroyin iku Ibidunni Ighodalo.

Adeboye gbadura pe ki Eleduwa tu ẹbi Pasitọ Ituah Ighodalo to fi silẹ lọ ninu.

Ẹni ogoji ọdun ni Ibidunnu i ṣe nigba ti ọlọjọ de.

Báyìí ni orin ìsìn ìkẹyin olóògbé Ibiduni Ighodalo ṣe lọ

Awọn ẹbi olóògbé
Àkọlé àwòrán, Báyìí ni orin ìsìn ìkẹyin olóògbé Ibiduni Ighodalo ṣe lọ
Báyìí ni orin ìsìn ìkẹyin olóògbé Ibiduni Ighodalo ṣe lọ
Àkọlé àwòrán, Olórin ìgbàgbọ́ Tope Alabi náà péjú sibi ìsìn òrin to wáye
Báyìí ni orin ìsìn ìkẹyin olóògbé Ibiduni Ighodalo ṣe lọ
Àkọlé àwòrán, Awọn ènìyàn to n sọ̀rọ̀ nípa olóògbé
Báyìí ni orin ìsìn ìkẹyin olóògbé Ibiduni Ighodalo ṣe lọ
Àkọlé àwòrán, Olùsọagutan Ituah Ighodalo nínú ìṣìn orin ìkẹ́yìn
Gbógbó àwọn tó péjú síbẹ̀ fún ara wọ́n ni àlà tí ìjọba pa lásẹ̀
Àkọlé àwòrán, Báyìí ni orin ìsìn ìkẹyin olóògbé Ibiduni Ighodalo ṣe lọ

Ibidun Ighodalo death: Ilé Ighodalo dá páropáro, òkú Ibidunni Ighodalo ti wà nílé ìgbókúpamọ́sí l'Eko

aworan Ibidunni Ighodalo

Awọn ebi oloogbe Ighodalo ti gbe oku rẹ lọ si ileewosan kan ni agbegbe Lagos Island ni ilu Eko.

Alamojuto ileeṣẹ rẹ, lo fi ọrs sita faraye gbọ.

O ni ọjọ Aiku ni ọkọ oloogbe naa atawọn mọlẹbi gbe oku rẹ

Nigba ti ikọ BBC news de ile oloogbe naa lagbagbe Bourdilourn ni ilu Eko lowurọ ọjọ Aje nibi ti awọn eeyan leni ejeeji ti n wọle ba wọn daro.

Paroparo ni agbegbe naa da ti iwọnba awọn eeyan melookan to n wọle si n ks ọrọ idaro wọn si iwe ibanikẹkun ti wọn ṣi pẹlu aworan oloogbe naa.

Ibidun Ighodalo: Ǹkan ti amọ̀ nípa ilúmọ̀ọ́ká arẹwà obìnrin nígbà kan rí tó d'olóògbé

Ibidunni

Oríṣun àwòrán, Others

Ọpọlọpọ awuye lo n lọ lori iku to pa Ibidun Ighodalo to jẹ́ ọbinrin tó rẹ̀wà jùlọ nígbàkan rí, tó sì tún jẹ́ ìyàwó adarí àti olùdásílẹ̀ ìjọ Trinity House.

Bi o tilẹ jẹ pẹ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló tí n fi èrò wọ̀n hàn lórí ikú tó pa Ibídun.Ìròyìn sọ pé, arẹwa náà kú ní ìdájí òní Ọjọ́ àìkú ní ìlú Port Harcourt, nípìnlẹ̀ Rivers.

Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ tó máa ń báni ṣètò ayẹyẹ Elizabeth R ní, àti pé ó ti wà ní ìpínlẹ̀ Bayelsa àti Rivers láti ṣèrànwọ́ kíkọ́ ibudó ti wan yóò ti maa tójú àwọn aláàrùn Covid-19 sí.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Nurudeen Lawal adarí Elizabeth R tó jẹ́ ilé iṣẹ́ olóògbé sàlàyé fún BBC pé àwọn kò mọ ǹkan to ṣe ku paa nítori lẹ́yìn ti àwọn pari iṣẹ́ ní alẹ́ àná, olúkúlùkù wọ yàrá rẹ̀ lọ láti sù, sùgbọ́n nígbà ti ilẹ̀ mọ́ ni owúrọ̀ yìí ni kò jí mọ.

"Ó lọ sùn lánàá sùgbọ́n nígbà ti olúkúlùkù jí láàrọ̀ òní ni kò jí mọ́

Ọkùnrin náà kò dárúkọ ilé ìtura tàbi àdúgbò ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé sùgbọ́n ìlú Port Harcourt lo ti ṣẹlẹ̀.

Bákan náà ni ẹni tó sún mọ́ ọkọ olóògbé náà fìdi ìṣẹ̀lẹ̀ aburu náà múlẹ̀ fún ìwé ìròyìn "The Nation", sùgbọ́n kò sọ bóyá o ti ṣe àìsàn tẹ́lẹ̀.

Ibídùn fí ọkọ àti ìbejì rẹ̀ silẹ̀ sáyé lọ

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ọjọ́ kọkàdínlógún Oṣù tó ń bọ̀ ló pinu láti ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ojójì ọdún rẹ̀.

Kogi Robbery: Wọ́n sin ọ̀gá ọlọ́pàá táwọn Ọlọ́ṣà pa ní ìpínlẹ̀ Kogi láàrín ọ̀pọ̀ omijé

Awọn alabaro lasiko isinku ọga ọlọpaa naa

Oríṣun àwòrán, oyo insight

Ọga ọlọpaa ni ileeṣẹ ọlọpaa t'awọn Adigunjale ti ṣọṣẹ ni ipinlẹ Kogi ti wọ kaa ilẹ sun ni ilu Ibadan

Agbegbe Olunde ni ilu Ibadan ni wọn gbe sin Ọgbẹni Adebọla Tajudeen si.

Ni ọjọ Ẹti ti kọja l'awọn igara ọlọṣa kan ya wọ ilu Isanlu ni ipinlẹ Kogi nibi ti wọn ti pa awọn ọlọpaa ataraalu nibẹ l'asiko ti wọn lọ digun ja banki kan lole nibẹ

Taní Ibidunni Ighodalo tí gbogbo ọmọ Nàìjíríà ń selédè lẹ́yìn rẹ̀

Ibidunni Ighodalo

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Ǹkan tí a mọ̀ nípa Ibidunni Ighodalo tó kú

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ń bèrè pé taa ni Ibídunni Ighodalo, nítori náà ni aṣe ṣe àkójọpọ̀ àwọn ǹkan ti a ti mọ nígbà ayé rẹ̀

  • Àrẹwa tí ojú rẹ̀ wà lára èpo oṣẹ Lux ní Ibidunni ti ó sì ti jẹ́ ilúmọ̀ọ̀ká láti ẹni ọdún méjìdílógún.
  • O fẹ́ olùṣọ́àgùntàn Ituah Ighodalo olórí ìjọ Tirinity House ní ọjọ́ kẹ̀rìndinlógun oṣù kejì ọdún 2007.
  • Òun ni olùdásílẹ̀ àjọ kan tó ń poun réré ọ̀rọ̀ àìrọ́mọbii tí a mọ̀ sí Ibidunni Ighodalu Foundation tó sì tún n ń ran àwọn tó kù díẹ̀ káàtó fún láwùjọ lọ́wọ́ láti ṣe IVF
  • Ìgbà mọ́kànlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ ló gbìyànjú àti di ọlọ́mọ láyé nípa ṣíṣẹ ọ̀nà àti rọ́mọbí ìgbàlódé IVF
  • Ibidunni àti Ituah ní ọmọ méjì papọ̀
  • Ilé iṣẹ́ rẹ̀ Elizabeth R ló maa ń ṣe ilú Eko lóge lásìkò ọdún kérésì

Ẹ̀wẹ̀, ọkọ rẹ̀ Ituah Ighodalo lẹ́yìn tó gba ipè pé ọkọ rẹ̀ kú lótún ṣe ètò ìsìnkú fún ẹnikan lówòrọ̀ òní ojọ́ àìkú.

Ìsìnkú Deji Okoya ọmọ-ọmọ ilúmọ̀ọ́ka onísòwò Rasak Okoya ni olùsáàgùntàn náà ṣe, tgí ó sì sọ níbẹ̀ pé gbogbo àyé fẹ́ẹ̀ dojúdé pẹ̀lú ìròyìn ikú ìyàwó òun, sùgbọ́n ènìyàn gbọdọ tẹ̀síwájú ìgbé ayé rẹ̀.

Ituah ní láti ǹkan bí wákàtí díẹ̀ sẹyìn, gbogbo ǹkan lo daru papọ.

"Tí wọ́n bá sọ fún wá ni ọjọ́ àìkú tó kọjá wipe àó wá sòkú Ayodeji ènìyàn yóò jiya"

Ọdún kẹtalá rẹ̀ẹ́ tí Ituah àti Ibidunni ti wà bíi tọkọtaya kí ó to dédé dolóògbé ní ilú Port harcourt láàrọ̀ kùtù ọjọ́ àìkí

Ibidun Ighodalo

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ibidun Ituah Ighodalo fayé silẹ̀ ìlúmọ̀ọ́ká arẹwà tí fáyésilẹ̀
Ibidun ati ẹbi rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @prettypearl