One Million Boys: Ta ló dá ẹgbẹ́ òkùnkùn tó ń dààmú àdúgbò sílẹ̀

Awọn afurasi ẹlẹgb okunkun

Oríṣun àwòrán, PoliceNG

Ọrọ ti ẹ rọra n gbọ nipa Ebila olori ikọ "One Million Boys" lẹnu ọjọ mẹta ti wọn pa Abiola Ebila yii, kii ṣe ibi to ti bẹrẹ ree.

Njẹ ẹ mọ pe kii ṣe ilu Ibadan nìkan ni orúkọ ẹgbẹ janduku, One Million Boys, ti gbajúmọ?

Ìtàn tilẹ sọ pe adugbo Ajegunle nilu Eko ni awọn ọdọmọkunrin kan ti bẹrẹ ẹgbẹ naa lọdun diẹ sẹyin.

Wọn ni afojusun àwọn ni lati ma a gbéjà àwọn alailagbara láwùjọ.

Sugbọn, ẹgbẹ naa tun gbajúmọ̀ fun ole jíjà, ipaniyan, ati ifipabanilopọ ni Eko.

Aworan Ebila ati Ekugbemi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Sinima àgbéléwò Yoruba kan ti wọn pe orúkọ rẹ ni One Million Boyz ti ẹ jade lọdun 2014, eyi to safihan ihuwasi wọn.

Lọdun 2012, ọwọ ọlọpaa tẹ awọn bi aadoje to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa ni adugbo Apapa ati Ajegunle.

Orúkọ wọn tun jẹ jade lasiko isede coronavirus laarin oṣu Kẹrin si oṣu Karun un, ọdun 2020, fun pe wọn n ka àwọn eeyan mọ́lé lati ja wọn lólè nipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

One Million Boys ni Ibadan:

Adugbo Kudeti nitosi Molete nilu Ibadan ni a le pe ni ibùba tabi ibùdó àwọn ọmọ ẹgbẹ 'One Million Boys' nilu Ibadan.

Adugbo Kudeti kii ṣe ibi to pamọ rara. Koda, àwọn oloṣelu nla bi i oloogbe Adelabu Adegoke 'Penkelemesi' fi ṣe ibugbe nigba aye rẹ, ile rẹ ṣi wa nibẹ titi di oni.

Awọn akọsilẹ kan ti ẹ sọ pe ko jina si opopona Adebipon, ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti kọkọ fa wahala.

Iwaju ile ijọsin nla Cathedral Church of Saint David, ni Kudeti, ni awọn janduku naa ti fa rogbodiyan kan to waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2016.

Àkọlé fídíò, Pastor Omotoso Oluwatobi, CAC Iwo: Lẹ́yìn ìsọjí 21 days tí a ṣe ni wọ́n jí wa gbé

Kii ṣe igba akọkọ niyẹn ti ẹgbẹ naa ati awọn orogún wọn fa wahala ni agbegbe naa.

Ni nkan bi aago mẹjọ alẹ ni ìró ìbọn bẹrẹ si ni i dún, eyi to mu ki ọpọ eeyan o fi ile, sọọbu wọn silẹ, koda awọn kan fi ara pa.

Iroyin sọ nigba naa pe ọkọ ayọkẹlẹ, kẹẹkẹ 'maruwa', ati ọkada ni awọn janduku naa gùn wọ adugbo ni alẹ ọjọ buruku, eṣu gbomi mu ọhun.

Iṣẹlẹ naa mu ẹ̀mí awọn ara adugbo kan lọ.

Àkọlé fídíò, Rachel Oluwole: Ọdún mẹ́fa ni mo wà tí Ìyá mi kú lẹ́yìn ìbímọ ṣùgbọ́n àìní kò jẹ́ kí n rów

Wọn tun dana sun awọn ile itaja kan ni adugbo naa.

Awọn iroyin kan tilẹ sọ pe búrẹ́dì ni awọn janduku naa rẹ ni epo bẹtiro, ti wọn si n ju sinu sọọbu, ki wọn o to sọ ina si i.

Nkan to fà iṣẹlẹ buruku to sọ awọn idile kan sinu ibanujẹ ko ṣe e sọ ni pato.

Awọn iroyin kan sọ pe ija naa waye nitori pe awọn ọmọ ẹgbẹ million boys mú ọmọ ẹgbẹ alatako, 'indomie' kan, to ji ẹ̀rọ ibanisọrọ, ti wọn si 'ba a wi'.

Àkọlé fídíò, Charles Olumo Agbako: Ọjọ́ tí ìyá mi kú jẹ́ kò ṣeé gbàgbé-

Rogbodiyan wo lo waye laarin Indomie ati Abiola Ebila?

Eyi lo fa a ti olori ẹgbẹ naa, Indomie, fi ko awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ, ti wọn si lọ ọ doju ogun kọ Abiola 'Ebila' , to jẹ olori ẹgbẹ one million boys.

Abala kejì ija wọn lo waye ni alẹ ọjọ ti a n sọ yii.

Ko fi bẹẹ si akọsilẹ nipa rẹ, sugbọn a le sọ pe ọdun 2014 ni orúkọ rẹ kọkọ jade sita lasiko ti àṣírí ibuba awọn ajinigbe kan tú ni agbegbe Soka niluu Ibadan.

Àkọlé fídíò, Taiwo Awoniyi: Ìlú Oyìnbó kò rọrùn ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ ibi tí orí, Olúwa, ẹbí àti ará gbé mi

Oun la gbọ pe o siwaju awọn eeyan kan lati wa ọrẹ rẹ to di awati, ki asiri ibùba naa to o tu.

A ti ẹ gbọ pe ileewe girama St. Lukes, to wa ni Molete lo lọ.

To si di gbajumo janduku lẹyin to pada silu Ibadan lẹyin irinajo rẹ si Eko.

Awọn kan ti ẹ tun sọ pe pupọ lara awọn ọmọ ẹyin rẹ lo jẹ àwọn ti ko rikan-sekan lẹyin ti gbajugbaja oloṣelu nilu Ibadan, Lamidi Adedibu, di oloogbe. Awọn janduku maa n jẹ lọdọ Adedibu nigba aye rẹ.

Àkọlé fídíò, Ṣe lootọ;Njẹ́ o ní nkán tí èèyàn lè ṣe tí kò bá fẹ bí ọmọ àfín

Ile rẹ ko to wa ni Molete ko si jina si Kudeti, ti one million boys fi ṣe ibujoko.

Àmọ́ o, kii ṣe adugbo Kudeti nikan ni awọn ọmọ ẹgbẹ yii wa. Wọn tun ni ẹka si awọn adugbo bi i Beere, Mapo, Born Photo, Idi-Aro, Isale Asaka, Idi-Arere, Odinjo, Modina, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oṣu Karun, ọdun 2020, ni ileesẹ ọlọpaa ti n wa Ebila, fun ipa to ko ninu iku to pa olori ẹgbẹ janduku miran, Moshood Oladokun 'Ekugbemi' l'oṣu Kẹrin.

Ki oun naa o to kagbako iku lasiko ti ija waye laarin one million boys ati orogún wọn kan lọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Keje ni adugbo Olomi.

Àkọlé fídíò, Funke Felix Adejumo: Èmí kìí gba owó oṣù lọ́wọ́ ìjọ kankan, oníṣòwò gidi ni mi

Iru eeyan wo ni Ekugbemi jẹ?

Gbajugbaja janduku ni Ekugbemi nigba aye rẹ, ti awọn iroyin kan si sọ pe olori ẹgbẹ okunkun kan, to n da wahala silẹ nilu Ibadan ni.

Ko pẹ ti wọn fi Ekugbemi silẹ ni ọgbà ẹ̀wọ̀n Agodi nilu Ibadan, ni wọn pa a.

A ko le e sọ ọmọ ẹgbẹ ti Ekugbemi jẹ́ ninu one million boys, Indomie, ati Abe igi Boys.

Àkọlé fídíò, Gbajugbaja osere, Yemi Elesho ti sọ iriri reki o to di ilumọọka ni ẹka amuludun

Awọn ẹgbẹ mẹtẹẹta ni orúkọ wọn ma n jẹ jade lasiko ti wahala bá waye ni awọn adugbo to wa ni aarin gbùngbùn Ibadan.

A gbọ pe awọn janduku naa ma n kopa ninu gbígba ilẹ̀ onílẹ̀, ija àgbà, eyi to ma n yọrí sí iku, ati òfò dukia.

Lọjọ ti wọn pa Ekugbemi, iroyin sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Biola Ebila lo kọlu u, lasiko ti wọn fẹ ẹ gba owó ọmọ onílẹ̀ , lọwọ ẹnikan to n fi paanu bo ilé rẹ ni agbegbe Olunde, nitosi ile Ekugbemi.

Àkọlé fídíò, Láti ìgbà tí mo ti n wọ àmì ìdánimọ̀ Naijiria ni mo ti n rí àmì rere

Ada ni wọn fi ṣá a yanna-yanna.

Ileesẹ BBC ti ẹ gbọ nigba naa pe wọn sare gbe e lọ si ìdí òrìṣà ni agboole wọn ni adugbo Born Photo, lẹyin ti wọn ṣá.

Sugbọn o kú nitori pe o padanu ẹ̀jẹ̀ to pọ.

Iroyin ti ẹ sọ pe o jíǹde lẹyin ti wọn ṣe àwọn ètùtù kan, ko to o tun pada kú.

Titi di oni, iyalẹnu lo ni iku rẹ si n jẹ fun ọpọlọpọ to gbagbọ pe ko yẹ ki ada o ran an, nitori agbara ibilẹ to ni.

Àkọlé fídíò, Adedibu