Ebila: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá ni ẹgbẹ́ One Million Boys ṣe lọ́ṣẹ́ ni Ibadan

Ẹgbẹ One Million Boys

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni one million boys mi ilẹ gidi nitori iṣẹ ole ati ipaniyan ti wọn n ṣe.

Gẹgẹ bi iwadii ti fi ye wa, ogun ọdọ pere lo da ẹgbẹ naa silẹ lati fi jija gbara fun idajọ ododo lagbegbe Ajegunle nilu Eko lọdun mẹfa ṣẹyin.

Amọ nigba to ya ni awọn ọdọ kan ja ẹgbẹ ọhun gba, ti wọn si bẹrẹ si ni lo fun iwa ipa, idigunjale, ati ipaniyan, bẹẹ ni wọn n da alaafia ilu ru Ohun tí o kò mọ̀ nípa Ebila "One Million Boys" àti Ekugbemi, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó da ìlú Ibadan rú.

Ni ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹwaa, ọdun 2012, awọn ọdọ to to aadoje ni Ileesẹ ọlọpaa ṣe afihan wọn pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ one million boys ladugbo Apapa ati Ajegunle.

Amọ kaka ki ewe agbọn ẹgbẹ okunkun naa dẹ nidii iṣẹ ibi wọn, ko ko ko lo n le si, ti ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Abiola, ti ọpọ mọ si Ebila si n lewaju wọn nilu Eko lọdun 2014.

Abiola Ebila

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ọmọ bibi ilu Ibadan ni Abiola Ebila, ile ẹkọ girama St Lukes to wa ni Molete nilu Ibadan si lo ti kawe, lati ẹni ọdun mejidinlọgbọn si lo ti n dari ẹgbẹ naa.

Ẹgbẹ okunkun miran lo wa ba awọn ọmọ ẹgbẹ one million boys ja, ko si ẹni to laya ninu one million boys lati koju ẹgbẹ okunkun to wa bawọn ja naa afi Abiola Ebila, o jagun, to si segun, lati igba naa si ni wọn ti fi ṣe olori wọn.

Àkọlé fídíò, Lockdown updates: Naira Marley gbóríyìn fún Jude Chukwuka pẹ̀lú #1 míliọnù

Ilu Eko gbona mọ awọn ọmọ ẹgbẹ one million boys gidi lasiko naa, eyi si lo mu ki Ebiola sa wa silu Ibadan, lati wa fi ori ara rẹ pamọ.

Nitori iwa aburu ti wọn n hu, awọn ara adugbo Ajegunle ta gba wọn, eyi ti ọwọ ba tẹ ninu wọn ni araalu n jo ni ina, ti wọn si n ju oku wọn soju titi fun gbogbo aye lati ri.

Ọpọ wọn sa kuro nilu Eko lọ si agbegbe Ojo ati Badagry, Cotonou nigba ti awọn miran sa wa silu Ibadan, lara awọn to si wa si Ibadan ni Abiola Ebila.

Ẹgbẹ Okunkun nigboro Ibadan

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ṣugbọn ọrọ iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni adugbo Soka, nilu Ibadan lo jẹ ki okiki Abiola Ebila tan nilu Ibadan nitori ọrẹ rẹ Ọlọkada to sọnu, to n wa kiri lo gbe e de agbegbe Soka, níbi ti akara ti tu sepo nipa iṣẹlẹ ijinigbe to n waye nibẹ.

Lati igba naa ni okiki Abiola Ebila ti kan ni Ibadan, ó si di ọrẹ imulẹ pẹlu awọn agba oselu.

Ọpọ awọn ọdọ to jẹ janduku bẹrẹ si darapọ mọ, ti wọn si n lo ada, ìbọn ati ọbẹ lati da ilu ru.

Àkọlé fídíò, Black women live matters: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best

Oniruuru eto idibo to waye lasiko ti ẹgbẹ one milionu boys n tan kalẹ nilu Ibadan tun mu agbega ba agbara wọn.

Eyi waye nitori atilẹyin ti wọn n ṣe fun awọn oloselu, eyi to mu ko nira fun awọn ọlọpaa ati adari ijọba lati tete ṣẹ eegun ẹyin ẹgbẹ okunkun naa.

Ẹgbẹ one million boys bẹrẹ si gbilẹ nilu Ibadan, lati adugbo Beere, Mapo, Idi Aro, Odinjo, Eleta, Modina de Born Photo ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti n ṣe ọṣẹ, wọn n jale, wọn si n pa eeyan.

Okiki ẹgbẹ one million boys yii kan gidi nitori ojoojumọ ni wọn n lowo lọwọ, wọn n fẹ ọmọge to wu wọn, ti awọn ẹgbẹ okunkun miran si n jowu wọn.

Lara awọn ẹgbẹ okunkun ti wọn si jọ n jija ìwọ ko ju mi, emi ko ju ọ ni ẹgbẹ Indomie ati Abẹ-igi aanu nitori wọn siwaju ẹgbẹ one million boys bẹrẹ iṣẹ nilu Ibadan.

Akole lẹta latọwọ Ẹgbẹ One Million Boys

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ọṣẹ ti one million boys ṣe ni Ibadan:

Ni alẹ Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kejila ọdun 2019, awọn ọmọ ẹgbẹ one million boys ya bo mọsalasi kan ladugbo Kudeti, pẹlu ọkọ Micra kan, kẹkẹ ẹlẹṣẹ mẹta ati ọkada pupọ.

Lẹyin ikọlu wọn naa, obìnrin kan fara gba ọta, to si ku.

Wọn ge ọwọ ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun mii kan, Sikiru Mufutau, to si ku, bẹẹ ni wọn ba ọpọ dukia jẹ.

Oniruuru awọn ikọlu bayii lo ti waye lati igba ti One million boys ti bẹrẹ iwa ika wọn, ti ọpọ ẹmi si ti bọ laarin ẹgbẹ naa ati awọn orogun wọn bii Indomie.

Bakan naa tun ni One million boys maa n fi iwe ransẹ si adugbo ti wọn ba ti fẹ lọ jale.

Koda, wọn yoo si sọ tẹlẹ fawọn aladugbo naa lati pese owo silẹ fun awọn, bi bẹẹ kọ, wọn yoo ge ọwọ wọn.

Ṣe iku Abiola Ebila yoo fopin si ẹgbẹ one million boys bi?

Ni ọjọ mẹta ṣẹyin, ni osu kẹrin, ọdun 2020, ni Abiola Ebila pa orogun rẹ ninu ẹgbẹ okunkun miran, Ekugbemi, lati igba naa si ni awọn agbofinro ti n wa Abiola Abila, ko le e koju igbejọ ẹṣun naa.

Ni irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ Kejila oṣu Keje ọdun 2020 ni ariwo gba ilu kan pe ọwọ ti tẹ olori ọmọ ẹgbẹ one million boys, Abiola Ebila, to si ti jẹ Ọlọrun nipe.

Ẹgbẹ One Million Boys

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ariwo ayọ gba ilu kan pe eegun ẹyin ẹgbẹ okunkun naa ti ṣẹ, paapaa pẹlu olori rẹ to ku naa, ti awọn ọmọ ẹyin rẹ yoo si fi ẹsẹ fẹ.

Ṣugbọn ibeere ti ọpọ eeyan n beere ni pe, ṣe opin patapata ti de ba ẹgbẹ aseku pani one million boys ni bayii ti olori wọn ti silẹ bora?

Ẹgbẹ One Million Boys

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ṣugbọn awọn miran n ro ninu ọkan wọn pe, agbo to fi ẹyin rin lọ ni ọrọ ẹgbẹ okunkun one million boys yii lee jẹ, o ṣee ṣe ki wọn lọ tun agbara mu wa.