Canada Visa Application: Canada bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí fọ́ọ̀mù àwọn tó fẹ lọ sí orílẹ̀-èdè náà

Oríṣun àwòrán, @truwayofficial
Ijọba ilẹ Canada ti bẹrẹ si n ṣiṣẹ lori fọọmu awọn to nifẹ lati tẹko leti lọ silẹ naa lati Ọjọ Kinni, Oṣu Keje, ọdun 2020.
Ileeṣẹ to n risi eto irinajo ilẹ okere lorlẹ-ede naa, IRCC sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn gbedeke kan yoo wa fun awọn arinrinajo, ṣugbọn o ti bẹrẹ iṣe pada nitori awọn ti yoo bẹrẹ si n rinrinajo lọ ilẹ ọhun laipẹ.
IRCC ni ootọ ni pe awọn kan ko tii le lọ si Canada lọwọ yii nitori arun Coronavirus, ṣugbọn aye wa fun awọn mọlẹbi ti yoo lo ju ọjọ marundinlogun lọ nilẹ naa, atawọn ti iṣẹ wọn ṣe koko lati wọ Canada lasiko yii.
O sọ pe awọn arinrinajo ni lati ṣalaye fun awọn oṣiṣẹ aṣọbode pe iṣẹ wọn ṣe koko ki wọn to le gba wọn laye lati wọ orilẹ-ede ọhun.
IRCC tun ti bẹrẹ iṣe lori fọọmu awọn akẹkọ to fẹ lọ kawe ni Canada, iwe fun awọn to ti ri iṣe nilẹ naa ati iwe awọn to fi orukọ silẹ lati di ọmọ onilu.
Ijọba ilẹ Canada ti ni ọrọyan ni fun ẹnikẹni to ba ṣẹṣẹ wọ ilẹ naa lati wa ni igbele fun ọjọ mẹrinla gbako.
Bakan naa ni awọn arinrinajo ọhun ni lati pese ẹri fun awọn ẹṣọ aṣọbode pe wọn ni alakalẹ bi wọn yóò ṣe wa ni igbele ọhun.
Ṣaaju ni ijọba ilẹ Canada ti sọ pe oun ko ni gba ki ẹnikẹni wọ orilẹ-ede ọhun lati oke okun titi di Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje ọdun 2020 nitori ajakalẹ arun Coronavirus.













