Europe: Yúrópùù ní ọmọ Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè Áfíríkà 43 míì kò ni wọ ilẹ̀ òun

Coronavirus Border reopening: Ìdí tí Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè míì kò fi ni wọ àwọn orilẹ̀-èdè EU mọ́

Oríṣun àwòrán, others

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Naìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè mẹtalelogoji míràn nílẹ̀ Afirika, ni kò ni lé wọ ilẹ̀ Yuroopu, EU láti Ọjọ́ Kíní, Oṣù Keje, ọdún 2020.

Kò sí ìdí méjì ti EU fi yọ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Afírika yìí sílẹ̀ ju bí ààrùn Coronavirus ṣe n tànkálẹ̀ àti bi ìjọba kò ṣe kọbi ara sí ọ̀nà ti yóò fi dáwọ́ rẹ̀ dúró lọ.

Wọn ni èyí yóò sì níra fún àwọn orílẹ̀-èdè Yuroopu láti sàyẹ̀wò wọn lásìkò ìrìnàjò si orilẹede awọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ní báyìí, ènìyàn tó lé ni ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún ló ti lùgbàdì Covid-19 ni Nàìjíríà, ti Ghana si ni ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdinlógún.

South Africa ti ni ènìyàn ẹgbẹ̀run lọ́nà mẹ́jìdínlógóje, ti Cameroon sì ti ni ẹgbẹ̀run méjìlá lé díẹ̀ ènìyàn to ko Coronavirus.

Ẹ̀wẹ̀, ìròyìn sọ pé, àjọ EU ní orílẹ̀-èdè mọ́kànla nínú orílẹ̀-èdè mẹ́rìnléláàdọ́ta to wà ni Afirika, nìkan ni yóò láàfàni láti maa wọle, ti wọ́n ba ṣi ibodè náà pada.

Papakọ ofurufu ni Cyprus

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àwọn orilẹ̀-ède Afirika náà ni Algeria, Angola, Egypt, Ethiopia, Mauritius, Morocco, Mozambique, Namibia, Rwanda, Uganda àti Zambia.

Agbẹnusọ àjọ EU, Eric Mamer sàlàyé pe, àwọn ni ọ̀nà ti àwọn ń gbà láti mọ orílẹ̀-èdè tí yóò le gba arìnrìn àjò, ó fi kún pé, ìpinu àwọn dá lórí ìlànà ìjọba lórí ẹ̀ka ètò ìlera.

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde; Ilé iwosan kan ṣoṣo tó wà ní Idí-Iroko /Adewole tí bàjẹ́ pátápátá.

Bákan náà ni Brazil, Quatar Ilẹ Amerika àti Russia kò si nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò láànfàní láti wọ EU, títí di àsìkò yìí, ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì si ni ẹtọ́ kan náà gẹ́gẹ́ bi ara EU títí ti àdehuń Brexit yoo fi kẹ́sẹ jári lópin ọdún yìí.