Sotitobire church news: Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ pásítọ̀ ìjọ Sotitobire sí ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsàn án

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran n wọ inu ile ẹjọ lọ

Ile ẹjọ giga to kalẹ si ilu Akure ti sun igbẹjọ pasitọ ijọ Sotitobire Miracle Centre, Alfa Babatunde Sotitobire si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan an ọdun 2020.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti pastitọ naa atawọn mẹfa miran ti wọn fẹsun kan pari awijare wọn niwaju ile ẹjọ ọhun.

Eyii n tumọ si pe o ṣeeṣe ki ile ẹjọ naa fi ọjọ ti yoo ṣe idajọ rẹ lede lọjọ naa.

Lẹyin ti ẹlẹri ikarundinlogun ti olujẹjọ pe sọ tẹnu rẹ tan, adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun, Olusola Odusola mu Sotitobire si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan an ọdun 2020 gẹgẹ binọjọ to kan ki ọjọ idajọ to de.

Alfa Babatunde ati awọn afurasi miran n jade kuron inu ile ẹjọ lọ

O ni oun ko ni gba ki agbẹjọro ijọba tabi agbẹjkọro Sotitobire da oju ẹjọ ọhun ru nitori pe idajọ odo ni ou n fẹ lori ọrọ na.

Wolii Sotitobire atawọn ọmọ ijọ rẹ mẹfa miran dẹni to n kawọ pọn tojọ niwaju adajọ lẹyin ti ọmọ ọdun kan, Kolawole Gold, dede poora ninu ijọ rẹ lopin ọdun 2019.

Sotitobire Latest news: Adájọ́ yarí lórí bí àwọn ẹlẹ́rìí ṣe ń fi ẹjọ́ falẹ̀

Alfa Babatunde n ba agbẹjọro sọrọ

Ile ejọ giga tipinlẹ Ondo, to kalẹ si ilu Akure, ti fari ga lori bi igbejọ Alfa Babatunde se n fa nilẹ bii igbin.

Adajọ Olusegun Odusola to n gbọ ẹjọ ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan wolii ijọ Sotitobire naa, lo woye bẹẹ lasiko igbẹjọ to waye lọjọ Isẹgun.

Adajọ Odusola wa fajuro lori bi agbẹjọro fun olujẹjọ, Alfa Babatunde, se tun beere pe ki wọn sun ẹjọ naa siwaju nitori ailera rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adajọ naa ni igbẹjọ ẹsun ijọmọgbe naa gbọdọ wa si òpin kí oṣù keje tó ń bọ̀ ó to parí.

An agbẹjọro nile ẹjọ

Ikede yii si ni adajọ naa tun fi n sọ ero ọkan rẹ, lori bi awọn ẹlẹrii ti olujẹjọ naa pe, se n mu isunsiwaju ati ifasẹyin ba ẹjọ naa.

Adajọ Odusola wa sun igbẹjọ náà siwaju di ọjọ́ Kẹrìnlá, ikẹẹdogun àti ìkẹrin dínlógún oṣù keje ọdún 2020.

Ẹ pèsè ẹlẹ́rìí púpọ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Sotitobire yóò jẹ́rìí fúnrarẹ̀ o! - Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ Ondo

Wọn ti sún igbejo sì ọlá ọgbọ́n ọjọ́ oṣù kẹfà fún ìparí gbígbé jọ àwọn ẹlẹri wòlíì Alfa Babatunde.

Adajọ tí wá ṣàlàyé pé, kí wọn gbìyànjú láti jẹ ki awon Ẹlẹ́rìí náà pọ ni iye bíi bẹẹ kọ, ilé ẹjọ́ yóò pé àwọn ẹni a fẹ̀sùn kan, ní pàtàkì Alfa Babatunde láti jẹ ẹlẹ́rìí ara rẹ nítorí wọn fẹ ki igbejo náà tètè parí.

Àkọlé fídíò, Sotitobire n jẹjọ nipa Gold Kolawole ọmọ ọdun kan to di awati nile ijọsin rẹ ni ilu Akure.

Ṣáájú ni àwọn eleri méjì tí sọ̀rọ̀ gbé sẹ́yìn Alfa Babatunde dípò àwọn mẹta tí ó yẹ kí o sọ̀rọ̀.

Èyí ló mú kí Adajọ Olusegun Odusola pé àkíyèsí ilé ẹjọ́ pé, tí àwọn Ẹlẹ́rìí kò bá pè dáadáa lọ́nà, olórí ẹni afesunkan ni yóò ṣe ẹlẹ́rìí ara rẹ.

Wolii Babatunde Sotitobire tun de ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo lonii lati jẹjọ nipa Gold Kolawole ọmọ ọdun kan to di awati nile ijọsin rẹ l'Akure.

Gẹgẹ bo ti maa n ṣe ni kete to ba ti de ile ẹjọ nipa fifọ ọwọ ati lilo sanitaisa ko to wọ ile ẹjọ lọ.

Wolii Sotitobire

Ọjọ pẹ ti ọrọ bi ọmọ ọdun kan to sọnu ni ie ijọsin kan nipinlẹ Ondo eyi ti Wolii Alfa Babatunde Sotitobire n dari ẹ ti n waye.

Lonii, ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo tun ti pe Wolii Sotitobire atawọn to pe ni ẹlẹri rẹ ki wọn wa wi tẹnu wẹnu wọn.

Lọsẹ to kọja, iyawo rẹ ti kun awọn ẹlẹri to si sọ ohun to mọ, bakan naa ni awọn eeyan ogun mii naa ti n jẹri ohun ti wọn mọ.

Nile ẹjọ, wọn wo awọn fọran kọọkan lori ifọrọwanilẹnuwo to waye pẹlu Wolii naa.

Ẹ tẹti leko lonii lori ikani yii, BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ bo ba ṣe n lọ nile ẹjọ.

Sotitobirẹ