Lagos School reopening: Ìjóba ìpínlẹ̀ Eko kéde ṣíṣí àwọn ilé ìwé padà

Lagos School reopenig: Ìjóba ìpínlẹ̀ Eko kéde ṣíṣí àwọn ilé ìwé

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko tí kéde pé kí àwọn ipele ikẹ́kọ̀ọ́ jáde, ipele àkọ́kọ́ girama (JSS3) àti akẹ́kọ̀ọ́ jáde girama (SSS3) kí wọ́n wọlé pade silé ẹ̀ká wọ́n láti ọjọ́ kẹta ọsù kẹjọ ọd'un yìí lọ.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu kéde ọ̀rọ̀ yìí pé, lẹ́yìn ti àwọn tí ọ̀rọ̀ kan ti fikùnlukùn ni àwọn pínnu láti ṣilèkùn ilé iwé ní ọjọ kẹta, oṣù kẹjọ, ọdun yii.

O ní ìwọlé yìí wà fún àwọn tọ fẹ́ ṣe ìdánwò àṣe kágbágbá nìkàn ni.

Gómìnà ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ fásiti gbogbo yóò sì wà ni títì pa, kí wọ́n tẹ̀síwájú nínú ètò ẹ̀kọ́ orí ayélujara.

Papako ofurufu Naijiria

Oríṣun àwòrán, FAAN

Airport reopening in Nigeria: Wo ohun tó yẹ kó o mọ̀ tó bá fẹ́ rìnrìnàjò pẹ̀lú ọkọ̀ òfúrufú ní Naijiria

Minisita fun eto irinna ofurufu ni Naijiria, Hadi Sirika ti kede igbẹṣẹ tuntun ti awọn to n rinrinajọ gbọdọ tẹle ti wọn ba de papakọ ofurufu ni Naijiria.

Eyi ko ṣẹyin bi wọn yoo ṣe si papakọ ofufuru fun igbokegbodo ọkọ ofurufu ni Naijiria lati Ọjọ Kẹjọ, Osu Keje yii.

Hadi Sirika ti laa ni ẹṣẹẹsẹ, awọn igbesẹ ti awọn eniyan gbọdọ tẹlẹ ti wọn ba ṣe n de papakọ ofurufu:

  • Ọ gbọdọ yẹra fun fifi ọwọ kan ohunkohun ni bẹ
  • Awọn arinrinajọ gbọdọ yago fun awọn oṣiṣẹ papako ofurufu
  • O ti gbọdọ de papakọ ni nkan bii wakati mẹta ki o tọ wọ ọkọ baalu nitori awọn eto ti o gbọdọ tẹle.
  • Wọ ibomu rẹ tabi iboju ni gbogbo igba ti o ba wa ni papakọ abi ninu ọkọ ofurufu.
  • Ri wi pe o duro si ibi ti wọn la kalẹ fun awọn eniyan nipa ti tẹle ofin yiyagofunraẹni.
  • Tẹ si waju lati lọ fi oogun apakokoro fọ ọwọ rẹ ati finfin ẹru rẹ ni awọn ibi ti wọn ba ti la kalẹ.
Àkọlé fídíò, Nikesuliat: Ọ̀dọ́mọdébìnrin akéwì tó n fi ẹ̀ṣà kìlọ̀ ìwá lásìkò yìí
  • Fọ ọwọ rẹ, ki o si fi oogun apakokoro fọ ọwọ rẹ.
  • Tẹsiwaju lọ si iwaju lati lọ ṣe ayẹwo bi ara rẹ ṣe gbona si.
  • Ninu papakọ ofurufu naa, ri wi pe o yago fun awọn eniyan ni gbogbo igba ti o ba n mura lati wọ ọkọ baalu.
  • Ti o ba ti wọ inu ọkọ, yago fun awọn ọkọ ti wọn ti fa ala si wi pe ki o ma ṣe joko si
Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀
  • Ko si ẹni ti yoo fun ọ ni ounjẹ ninu ọkọ nitori naa ma ṣe yọ ibomu rẹ, amọ omi yoo wa fun ọ.
  • Ti awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu ba ri wi pe oun wukọ lọpọ igba, wọn yoo lọ fi ẹ si yara iyasọtọ nibi ti ajọ NCDC yoo ti wa ṣe ayẹwo Coronavirus fun ẹni naa.

Bakan naa ni Minisita fun irinna ọkọ ofurufu, Hadi Sirika ni ẹnikẹni to ba ni iba tabi to n wu kọ lati ma ṣe wa si papakọ ofurufu, nitori wọn ko ni gba ki ẹnikẹni to ba ni ami to farajọ ti arun Coronavirus wọ ọkọ ofurufu.

Ọjọ́ Kẹ̀jọ, oṣù yíì ní ìrìnà ọkọ́ òfúrufú yóò bẹ̀rẹ̀ padà ní Naijiria

Ijọba orilẹ-ede Niajiria ti paṣẹ ki wọn ṣi awọn papakọ ofurufu to wa lorilẹ-ede Naijiria lẹyin oṣu mẹta ti wọn ti i pa nitori ajakalẹ arun Coronavirus.

Minisita fun eto irinna ofurufu ni Naijiria, Hadi Sirika lo kede rẹ loju ọpọ ikansiraẹni Twitter rẹ.

Papakọ ofurufu Eko

Oríṣun àwòrán, Others

Hadi ni Ọjọ Kẹjọ, Osu Keje ni papakọ ofurufu ti ilu Eko ati Abuja yoo ṣi pada.

Papakọ ofurufu ti ipinlẹ Kano, Port Harcourt, Owerri ati Maiduguri yoo si ni Ọjọ kọkanla, Osu Kẹjọ,

Nigba ti awọn papakọ ofurufu to ku yoo ṣi ni Ọjọ Karundinlogun, Osu Kẹjọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ni bayii, iye awọn to ti lugbadi arun Coronavirus ni Naijiria ti da 26,484, ti eniyan 603 si ti ku.

Eniyan 10,152 lo ti ri iwosan gba lọwọ arun Coronavirus ni Niajiria.

Àkọlé fídíò, Oríṣí ìjìyà ní àwọn bíi Gómìnà El Rufai àti Fayemi ń bèèrè f'àwọn afipábánilòpọ̀

Ìrìnà ọkọ̀ akérò àti ọkọ̀ òfurufú bẹ̀rẹ̀ padà jákèjádò Nàìjíríà!

Ijọba apapọ lorile-ede Naijiria ti kede pe igbokegbodo ọkọ laarin ipinlẹ kan si omiran le bẹrẹ pada lati ọjọ Kini oṣu Keje.

Amọ to wa nibẹ ni pe laarin wakati ki konileogbele to bẹrẹ ni wọn le fi rinna.

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bashirahmad

Alaga igbimọ eleto ijọba lori Covid-19 Boss Mustapha lo lede ọrọ yi lasiko to n jabọ ilana ti yoo de ipele keji idẹwọ isede ti ijọba gbe kalẹ.

Boss sọ pe idẹwọ isede yi yoo waye fun oṣu mẹrin pẹlu iyipada diẹ si eyi to wa nilẹ tẹlẹ.

Ikede yi n waye pẹlu bi iye awọn to lugbadi arun yi ti se kọja ẹgbẹrun mẹrinlelogun.

Àkọlé fídíò, Uber Lady: Bùkátà pọ̀ lọ́rùn mi ní mo ṣe ń wa taxi akérò

Awọn nkan miran ti o ba ikede yi wa ni wọn yi:

  • Awọn ọlọkọ baalu yoo bẹrẹ isẹ lorile-ede Naijiria nikan
  • Awọn akẹkọọ ile ẹkọ to fẹ se idanwo asekagba ni ile iwe alakọbẹrẹ ati girama yoo pada si ile ẹkọ
  • Ni awọn ijọba ibilẹ ti ọwọja arun yi ko pọ, lilọ bibọ ọkọ yoo maa waye
  • Awọn garaji ọlọkọ ni lati pese ọsẹ ifọwọ, aaye ti awọn ti o fẹ wọ ọkọ yoo duro si ti wọn ko si ni gbe ju ida meji iye ero ti wọn n gbe tẹlẹ
  • Ilana to de awọn ile igbafẹ, ile ounjẹ, si wa nilẹ.
  • Ayẹyẹ Isinku ati igbeyawo ko ni kọja pe ki eeyan ogun ninu ipejọpọ wọn
Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'