Kaduna Rape: Wọ́n rí òkú ọmọ ọdún mẹ́fà tí wọ́n fipá bálopọ̀ nínú mọ́ṣálàáṣí

Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn ti ri oku ọmọbìnrin kan, ọmọ ọdún mẹfa, ti awọn kan fi ipa balopọ niluu Kaduna.

Inu mọsalasi kan to wa ni agbegbe New Road, Kurmi Mashi, ni ijọba ibilẹ Kaduna North ni wọn ti ri oku ọmọ naa.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Trust ṣe jabọ, ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ naa waye.

Ọpọlọpọ iṣẹlẹ ifipabanilopọ lo ti n waye laipẹ́ yii kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria to si n waye nibikibi yala ninu ile, ẹyin ile atawọn ile ijọsin.

Iroyin sọ pe wọn ti kọkọ n wa ọmọde naa nile, ko to di pe awọn ara adugbo mu iroyin wa fun ẹbí rẹ pe wọn ti ri oku rẹ ninu mọṣalaṣi.

Ayẹwo ti wọn ṣe si ara rẹ nigba ti wọn fẹ sin in, lo fihan pe wọn ba a lopọ, paapa bi oju ara rẹ ṣe wa ni ṣíṣí silẹ.

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ naa sọ pe ọwọ ko tii tẹ ẹnikẹ́ni lórí iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn iwadii ti n lọ.

Ati pe ni nkan bi aago mẹta aabọ ọsan ti wọn n mura fun ìrun kiki, ni wọn ri oku ọmọ naa.

Ọjọ Ẹti nikan ni wọn n ṣi mọsalasi, nitori isede coronavirus.

L'Eko, Bàbá ẹni ọdún 61 bá ọmọ rẹ̀ lopọ̀, ó fún un lóyún

Ọrọ awọn afipabanilopọ yii lo ti n gab ẹbọ lọwọ gbogbo ipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria lasiko yii.

Laipẹ ni iroyin jade nipa baba ẹni ọdun mọkanlelọgọrin kan to fipa ba ọmọdebinrin kan lo pọ ni ipinlẹ Eko

Koda, iroyin sọ pe ọmọ naa ti loyun.

Awọn ọlọpaa sọ pe ọwọ tẹ Eke Kanu, lẹyin ti wọn ẹgbẹ awọn agbejọro l'obinrin (FIDA), fi ọrọ to àwọn l'eti.

Ọmọ ọdun mọkandinlogun ni ọmọbìnrin naa ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si.

Gẹgẹ bi ọmọ naa ṣe sọ, lati igba kekere rẹ ni baba naa ti ma n ba lopọ̀.

O sọ fún awọn ọlọpaa pe baba oun ni oun yoo fi iya jẹ òun, to ba fi le sọ fun ẹnikẹ́ni.

O ni: "Nigba ti baba mi rí i pe mo ti loyun, o mu mi lọ si ile itaja òògùn kan.

Nibẹ ni wọn si ti fun mi ni oògùn lati ṣẹ oyun náà."

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ọwọ́ tẹ ayédèrú dókítà Abdallah tó ń tà oògùn Coronavirus

Awọn ọlọpaa sọ pe awọn ti gbe ọmọbìnrin naa lọ si ileewosan Mirabel, fún ayẹwo.

Baba rẹ si ti wa ni ẹka ileesẹ ọlọpaa to n wadii ẹsun iwa ọ̀daràn, ni Panti ni ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Nikesuliat: Ọ̀dọ́mọdébìnrin akéwì tó n fi ẹ̀ṣà kìlọ̀ ìwá lásìkò yìí

Iroyin ifipabanilopọ ti lọ soke si ni Naijiria lẹ́nu ọjọ mẹta yìí.

Obinrin meji ni wọn fi ipa ba lopọ̀, ti wọn si tun pa, nilu Ibadan.

Iru rẹ naa waye nipinlẹ Edo.

Gbogbo ẹ si waye laarin oṣu kan.