Abiola Ajimobi: Ikọ̀ ìjọba Oyo sọ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé Ajimobi ní ọwọ́ aya olóògbé ni kọ́kọ́rọ́ géètì wà

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Oyo ti sọ pe oun ko mọ idi ti wọn ṣe da ikọ asoju oun pada lẹnu ọna ile gomina ana, Abiola Ajimobi, nigba to yọju sibi adura ọjọ kẹjọ lẹyin to papoda.
Oluranlọwọ pataki fun igbakeji gomina lori ọrọ to n lọ, Omoetan Omolere lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
Omolere ni awọn ẹṣọ ile gomina ana ọhun sọ fun awọn ẹṣọ igbakeji gomina pe, ọwọ iyawo oloogbe naa ni kọkọrọ ẹnu ọna wa, ati pe ki igbakeji gomina ma ṣeyọnu lati jade kuro ninu ọkọ to gbe e wa.
O ni "Lara awọn ẹṣọ to wa lẹnu ọna lo sọ fun awọn eeyan wa pe, ka ma tilẹ jade kuro ninu ọkọ wa nitori wọn ko ni ṣilẹkun fun wa."

Oríṣun àwòrán, BBC Sport
Ni ti pe boya ede aiyede ti wa laarin iyawo Ajimobi ati igbakeji gomina tẹlẹ, Omoetan ni oun ko le sẹ boya ija wa laarin awọn mejeji ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni kii ṣe igbakeji gomina nikan ni wọn le pada lẹnu ọna ile oloogbe naa.
O ni wọn tun le awọn kọmiṣọna meji miran, ati iyawo gomina tẹlẹri ni ipinlẹ ọhun, Alhaja Mutiat Ladoja, to jẹ iyawo ṣẹnatọ Lamidi Ladoja pada lẹnu ọna.
Omolere pari ọrọ rẹ pe "Kii ṣe Rauf Olaniyan ni wọn da pada lẹnu ọna gomina Abiola Ajimobi, bi ko ṣe ijọba ipinlẹ Oyo."

"Nitori ko lọ sibi adura naa lorukọ ara rẹ, ṣugbọn o lọ lorukọ ijọba ipinlẹ Oyo."
Ẹwẹ, agbẹnusọ fun Abiola Ajimobi, Bolaji Tunji ti sọ ninu atẹjade kan pe kii ṣe pe awọn mọọmọ le igbakeji gomina pada nibi adura ọjọ kẹjọ ọhun, ṣugbọn o wa lasiko ti ko yẹ ni.
Tunji sọ pe igbakeji gomina naa de lẹyin ti adura ti bẹrẹ ati pe, awọn ẹbi oloogbe nikan ni adura ọhun wa fun.
O tẹsiwaju pe, wọn gbe kọkọrọ ṣenu ọna ni titẹle ilana ijinasiraẹnu gẹgẹ bi ajọ NCDC ṣe gbe kalẹ lọna ati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus.
Tunji sọ pe yatọ si pe ko ṣi ẹnikẹni to mọ pe igbakeji gomina yoo yọju sibi adura naa, wọn gbiyanju lati pe igbakeji gomina naa pada, ṣugbọn o ti kuro nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Igbákejì gómìnà, olórí òṣìṣẹ́ ọba àtàwọn míì ni wọ́n dá padà níbi àdúrà
Saaju la ti kọkọ s fun yin pe ikọ ijọba ipinlẹ Oyo to lọ sibi adura Fidau ọjọ mẹjọ fun Gomina ana, Abiola Ajimobi ni wọn ko jẹ ki wọn wọle sile Ajimobi to wa ni Oluyole nilu Ibadan.
Gẹgẹ bi Omolere tii se akọwe feto iroyin fun igbakeji Gomina, onimọ ẹrọ Raufu Olaniyan ti se sọ, Igbakeji Gomina, olori awọn oṣiṣẹ ijọba, Alhaja Amidat Agboola ati Kọmisana fọrọ ilẹ, Abiodun Abdul Raheem wa lara awọn ti wọn ko ribi wọle sibi adura Fidau naa.
Ninu ohun ta ri gbọ, n ṣe ni awọn agbofinro to wa nibi isinku naa da ọkọ wọn pada, ti ọrọ naa si fẹ di fa ki n fa ki wọn to fi ibẹ silẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn agbofinro naa ko kede ẹni to paṣẹ pe ki maṣe gba awọn asoju ijọba laye lati wọle, ṣugbọn lẹnu igba ti Ajimobi ti papoda ni aawọ ti n waye laarin mọlẹbi rẹ ati ijọba ipinlẹ Oyo.

Oríṣun àwòrán, Others
Bi awọn mọlẹbi ṣe n naka abuku si ijọba Gomina Seyi Makinde, naa ni ijọba n tako wọn pe awọn ko jẹbi ẹsun ti iyawo oloogbe Florence Ajimobi fi n kan ijọba pe, wọn ko fi apọnle to yẹ fun ọkọ ohun lẹyin iku rẹ.
Florence Ajimobi tahùn sí igbákeji gómìnà Oyo lórí ikú ọkọ rẹ̀, "Gbogbo wa làó kú"

Oríṣun àwòrán, BBC Sport
Ọrọ ti n ba ọrọ bọ lori iku to mu ẹmi gomina ana nipinlẹ Oyo lọ ati ipa ti ijọba ipinlẹ Oyo ko lasiko ti oloogbe naa wa ni idubulẹ aisan.
Idi ni pe Florence, aya oloogbe Abiola Ajimobi, ti n tahun si ijọba ipinlẹ Oyo lori ọna to gba huwa si ọkọ rẹ lasiko to n ṣe aisan.
Florence tahun si igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Rauf Olaniyan to lewaju igbimọ alasẹ ìjọba ipinlẹ Oyo wa ba kẹdun iku ọkọ rẹ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Koda, fọnran aworan kan to nii ṣe nipa iṣẹlẹ naa ti gba awọn oju opo ori ayelujara kan.
Florence, ẹni to n sọrọ pẹlu ibinu salaye pe oun ko fi igba kankan kan si gomina Seyi Makinde tabi ẹnikẹni ninu awọn alasẹ ijọba l'Ọyọ lati beere iranwọ lasiko ti ọkọ oun wa lori aisan, eyi to ja si iku.
Bakan naa lo tun ṣẹ pe, idile Ajimobi ko ran ẹnikẹni si ijọba gẹgẹ bi gomina Makinde ti sọ.Aya oloogbe Ajimobi, ẹni to gba pe lootọ ko tii yẹ ki oun maa sọrọ síta bayii lasiko ti oun n kẹdun iku ọkọ oun lọwọ, tun salaye pe,
o di dandan ki oun sọrọ sita nitori aimọye iṣẹlẹ aidaa to n waye lati ọdọ ijọba ipinlẹ Oyo.Nigba to n rọ ijọba Oyo lati yago fun oselu buruku, aya Ajimobi ni ololufẹ alaafia ni ọkọ oun, to si sin ipinlẹ Oyo fun ọdun mẹjọ gbako.
O ni "Gomina Ipinlẹ Oyo ko fi igba kankan pe oun lori aago tabi fi ọrọ itunu ransẹ fun osu kan ti ọkọ oun fi wa ni idubulẹ àìsàn, iru oselu wo wa nìyẹn?" Ile aye yii kere pupọ, o si yẹ ka maa ni ibẹru Ọlọrun ninu ohun gbogbo ta ba n ṣe, Ajimobi ti lọ lonii, iwa to ba si hu si ẹnikẹni ko ni ìtumọ mọ."
Orin ó digberé gb'ọkàn àwọn èèyàn níbi ìsìnkú Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Oyo insight
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni wipe wọn ti gbe oku gomina ana ipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Abiola Ajimobi bọ ilẹ ni inu ọgba ile rẹ ni Oluyole, Ibadan.
Awọn iroyin ti a n gbọ latọdọ awọn oniroyin to wa labẹle lawọn to wa nibi eto isinku ni wi pe wọn ti sin oku rẹ ni bonkẹlẹ lai jẹ ki awọn oniroyin wọle.

Ni nkan bii ago mẹwaa kọja iṣẹju marun owurọ yii ni wọn sin in. Ko ju eeyan ogun pere to wa ni bẹ gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Gẹgẹ bi akọroyin BBC Yoruba to wa nibẹ ṣe sọ ọ, gba gba gba lawọn ọlọpaa duro sẹnu ọna ti awọn eeyan kan wa nita.
Ṣaaju, ijọba ipinlẹ Oyo ati ẹbi oloogbe ti fi sita wi pe ilana Covid 19 gbaa ni awọn yoo tẹle fun eto isinku naa.

Oríṣun àwòrán, Oyo insight
Lara awọn agbaagba aafaa to wa nibi eto isinku Oloogbe ni Alaga gbogbo ẹgbẹ awọn musulumi nipinlẹ Oyo, Alhaji Kunle Saani, Sheikh Muiydeen Bello, Olori awọn Imamu ilu Ibadan, Sheikh Abubakar AbdulGaniyu Agbotomokekere ati awọn mii.
Ni deede ago mejila ọsan ni adura idagbere fun oloogbe bẹrẹ ni Mọṣalaṣi Sẹnetọ Ishaq Abiola Ajimobi to wa ni Oke Ado, Ibadan.
Lootọ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ, ilana Covid-19 ni wọn tẹle. Nibi itẹ gangan, eeyan perete pẹlu iyawo oloogbe, Oloye Florence Ajimobi atawọn ẹbi gangan lo wa nibẹ.
Eyi mu ki ero pọ nita ile rẹ ti wọn si n wọ loju titi.

Oríṣun àwòrán, Ajimobi Lives on
Bakan naa nibi eti adura to waye ni Mọṣalaṣi Sẹnetọ Ishaq Abiola Ajimobi, ori ayelujara ni wọn ti ni ki gbogbo eeyan maa wo o. Awọn aafaa diẹ nikan lo peju sibẹ.













