Kogi Coronavirus Status: Kìí ṣe ààrùn Covid-19 ló pa adájọ́ àgba ìpínlẹ̀ Kogi-Kọmísọ́nà ìlera

Kogi Coronavirus Status: Kìí ṣe ààrùn Covid-19 ló pa adájọ́ àgba ìpínlẹ̀ Kogi-Kọmísọ́nà ìlera

Oríṣun àwòrán, Othrers

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 27

Kọmísọna fún èòì ìlera ní ìpínlẹ̀ Kogi Saka Audu Haruna ní kìí ṣe ààrùn coronavirus lo pa adájọ agbà to jẹ́ Ọlọrun nipe ni ibudó ìtọ́jú àwọn aláàrùn coronavirus ní ìpínlẹ̀ Kogi.

Lásìkò tó n bá BBC news Yoruba sọ̀rọ̀ kọmísọ́nà ètò ìlera náà sàlàyé pé, ibi ètò ìsìnkú rẹ̀ ni àwọn ti n bọ̀ bi òun ṣe n bá BBC sọ̀rọ̀ lọ́wọ́.

"Kìí ṣe coronavirus ló paá, sùgbọ́n à ó ṣe ìwádìí ǹkan to n fa ikú tó ń ṣẹlẹ̀."

Haruna ni kò sí ààrùn Coronavirus ni ìpínlẹ̀ Kogi titi di àsìkò yìí gẹ́gẹ́ bi gómínà ìpínlẹ Yahaya Bello ṣe sọ.

Nípa ìjọba ìpínlẹ̀ náà tó ti ìjọba ìbílẹ̀ Kabba Bunnu pa ní ǹkan bi ọsẹ díẹ̀, ó ni gómínà ṣe èyí láti lé jẹ kí àwọn eletò ìlera ṣe ìwádìí ni, nígbà ti ba abájade ìwádìí náà ba sì jáde àtéjáde tabi ìpàdé oníròyìn yóò wáyé.

A ṣì ń ṣe ìwádìí ikú tó pa adájọ́ àgbà náà lọ́wọ́.

Kíni àwọn ọmọ Naijiria ń sọ lori ayélujára

Ariwo gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello lawọn eeyan n pa bayii lori itakun ayelujara.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ti adajọ agba ipinlẹ naa, Nasir Ajanah dagbere faye nile itọju awọn to ni arun Coronavirus ni ilu Abuja.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ ọhun ti ni ko si arun Coronavirus nilẹ oun, ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ lẹyin ti àjọ NCDC ni irọ nla ni.

Pupọ lara awọn to fi erongba wọn lede loju opo Twitter lo n bu ẹnu atẹ lu gomina naa lori iha to kọ si ọrọ Coronavirus ni ipinlẹ Kogi.

Lopez Iyke ni gomina ọhun àti pe ipinlẹ Kogi ko ni ilọsiwaju kankan labẹ iṣakoso gomina naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Alfred Aji ni tirẹ sọ pe Yahaya Bello ni gomina ti ko ṣe dáadáa ju ninu itan orilẹ-ede Naijiria.

Ni ti Morris Monye, o ni o ṣeni laanu pe awọn eeyan n ku nitori arun Covid-19 ṣugbọn Yahaya Bello ṣe bi pe ko kan oun.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ẹ wo awọn nnkan miran ti awọn eeyan n sọ:

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

Kogi Lockdown: Adájọ́ àgbà ìpínlè Kogi, jẹ́ Ọlọ́run nípè nílé ìtọjú àwọn àláàrùn Covid-19

Iroyin ni Ajanah ku sile itọju awọn alarun Covid-19 to wa ni Gwagwalada, ni ilu Abuja.

Oríṣun àwòrán, others

Adajọ agba ipinlẹ Kogi, Nasir Ajanah ti dagbere faye..Iroyin ni Ajanah ku sile itọju awọn alarun Covid-19 to wa ni Gwagwalada, ni ilu Abuja.Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin nnkan bi ọsẹ meji ti ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ gomina ipinlẹ naa, Yahaya Bello ku sile iwosan kan ni Abuja.

Eyi jẹ ọsẹ kan lẹyin ti Ibrahim Shaibu Atadoga to jẹ aarẹ ile ẹjọ magisrati ipinlẹ naa, jade laye.Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Kogi ti sọ pe ko si arun Covid-19 ni ipinlẹ oun, ṣugbọn ajọ NDCD sọ pe irọ patapata ni ọrọ naa.NCDC ni lara awọn eeyan to ni arun ọhun sọ pe ipinlẹ Kogi ni wọn ti wa, eyi to da ariyanjiyan silẹ laarin ijọba ipinlẹ Kogi ati ajọ naa.

Kogi Lockdown: Ǹkan tí a mọ̀ nípa àṣẹ kóníléógbélé níjọba ìbílẹ̀ Kabba-Kunnu

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, Yahaya Bello

Àkọlé àwòrán, Gómínà Kogi pàṣẹ kóníléógbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ kan ní Kogi

Gómínà ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello ti kéde kóníléógbélé ọṣẹ̀ méjì níjọba ìbílẹ̀ Kabba-Kunnu , nípìnlẹ̀ Kogi nítori ààrùn coronavirus.

Èyí wáyé lẹ́yìn tí àjọ tọ gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NCDC) fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn méjì tó ni ààrùn coronavirus jẹyọ níjọba ìbílẹ̀ náà, àwọn méjì náà ni Imaamu àgbà ibẹ̀ àti ọmọ rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn

Kóníléógbélé náà yóò bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́jìlá ọjọ kejì oṣù kẹfa títí di ọjọ kẹẹdógún ọṣù kéfa, bákàn náà ni wọ́n kò gbọdọ rí ẹnikẹni rìn ládùgbọ́n wọn.

Yahaya Bello ni ìgbélé náà yóòràn ìjọba lọ́wọ́ láti lé jẹ ki wọ́n rí àwọn tó ti ní ǹkan ṣe pẹ̀lú imaamu náà ati ọmọ rẹ.

Sùgbọ́n kan tó wà nínú ọ̀rọ̀ yìí ni pé ìròyìn sọ pé gómínà náà kò gbà pé ààrùn coronavirus wà nípínlẹ̀ Kogi.

Nínú àtẹjáde gómìnà Yahaya Bello, ó ní ki gbogbo àwọn to wà ni àyíka àti ni ipinlẹ Kogi maa tẹ̀lé àwọn ìlànà àjọ NCDC bótilẹ̀ jẹ́ pé ko sí ààrùn náà ni ìpínlẹ̀ Kogi

Kogi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ méjì tí kò tíí ní ààrùn náà ní Naijiria.

Irọ́ lásán ni, ṣe ni NCDC ń fi Coronavirus tan àwọn ọmọ Naijiria jẹ- ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi

Coronavirus in Nigeria: Ní ṣe ni NCDC ń fi Coronavirus tan àwọn ọmọ Naijiria jẹ- ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ipinlẹ Kogi ti sọ pe ko si ẹnikẹni to ni arun Coronavirus ni ipinlẹ naa.

Bakan naa lo tun ni ṣe ni ajọ to n gbogun ti itankalẹ ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC n fi ọrọ arun naa ja orilẹ-ede yii lole ni.

Kọmiṣọnna ọrọ to n lọ ni ipinlẹ ọhun, Kingsley Fanwo lo sọ ọrọ naa ninu iforowerọ pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan abẹle Channels.

Fanwo ni "O yẹ ki ajọ NCDC dẹkun ati maa tan awọn eeyan orilẹ-ede yii jẹ pẹlu Coronavirus nitori mi o gbagbọ pe NCDC n ṣe iranlọwọ kankan fun orilẹede yii."

Kọmiṣọnna ọhun tẹsiwaju pe "Ni erongba temi ni pe, afojusun NCDC ni lati pin arun Covid-19 kaakiri orilẹ-ede yii."

Fanwo ṣalaye pe ajọ NCDC fẹ fi tipatikuuku jẹ ki ipinlẹ Kogi ni arun Coronavirus ti ko si yẹ ko ri bẹ.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ni awọn arun mii wa to n pa awọn eeyan kaakiri Naijiria ju ti Coronavirus lọ bii aisan iba, ṣugbọn Coronavirus ni NCDC joko ti.

Ẹwẹ, adari agba NCDC, Chikwe Ihekweazu ti fesi pe awọn meji kan ti ayẹwo ṣẹṣẹ fihan pe wọn ni arun ọhun sọ pe ipinlẹ Kogi ni wọn ti wa.

Ṣaaju ni NCDC ti sọ pe arun Covid-19 ti rapala wọ ipinlẹ Kogi, ṣugbọn ijọba ipinlẹ naa ni ko si ohun to jọ bẹẹ, eyi si ti n fa họwuhọwu laarin ajọ naa ati ijọba ipinlẹ ọhun.

Ìjọba fẹ́ ṣe ìwádìí ohun tí kò jẹ́ kí ìpínlẹ̀ Kogi àti Cross River tíì ní covid-19

Yaya Bello, Ehanire Osagie ati Ben Ayade

Oríṣun àwòrán, Twitter

Minisita eto ilera ni Naijiria, Dokita Osagie Ehanire sọ pe ijọba yoo ṣe iwadii ohun to faa gan an ti ipinlẹ Kogi ati Cross River ko fi tii ni akọsilẹ aarun coronavirus.

Dokita Osagie ṣalaye awọn eeyan ti ijọba kọkọ ran lọ si ipinlẹ Kogi kuna nitori ede-ai-yede to ṣẹlẹ laarun awọn eeyan naa ati ijọba ipinlẹ Kogi.

Minisita ni igbesẹ ti ijọba yoo gbe naa ni lati ṣabẹwo si awọn ipinlẹ pada.

Dokita Osagie ni ọsẹ ti o n bọ yii naa ni ijọba yoo ran awọn si ipinlẹ Cross River ati Kogi lati ṣiṣẹ iwadii naa.

Atupalẹ awọn ipinlẹ to ni coronavirus ni Naijiria

Titi di ọjọ kejila osu kini ọdun 2020,orileede China nikan ni o ni eeyan to ni arun coronavirus.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ kẹtala, kokoro aifojuri yi di ajakalẹ ti awọn orilẹede bi Thailand, Japan, South Korea ati Amẹrika naa si bẹrẹ si ni kede awọn to kọkọ nii lọdọ wọn.

Laipẹ, arun yi tan kaakiri de agbaye, koda ilẹ Afrika naa ba wọn nipin ninu rẹ.

O le ni miliọnu mẹta eeyan to ti ni Coronavirus lagbaye gẹgẹ bi iroyin to n jade lọdọ ileeṣẹ to n pese iroyin nipa Coronavirus ti fasiti John Hopkins l'Amẹrika.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ni Naijiria kede ẹni akọkọ ti yoo ni arun yii lẹyin ti arakunrin ọmọ orileede Italy kan gbe wọle ti ayẹwo si fihan pe o ni Covid-19.

Lọjọ kẹsan osu kẹta, Naijiria kede ẹni keji iyẹn ọmọ Naijiria to ṣalabapade ọmọ Italy to gbe arun naa wọle.

Lẹhinnaa, awọn to ni arun naa bẹrẹ si ni pọ si.

Iroyin to n tẹwa lọwọ lati ileesẹ to n gbogun ti idena aisan ni Naijira, NCDC, wọn ni eeyan 3,912 lawọn ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ni arun yi,ti ilu Eko si ni iye awọn to pọju tii se 1,667.

Awọn to ti ba Coronavirus lọ ti wọ mẹtadinlọgọfa ti awọn ti ara wọn ya lẹyin itọju si jẹ 679.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Ipinlẹ mẹrinlelogoji pẹlu olu ilu Naijiria, Abuja ni coronavirus ti wọ pẹlu ohun ti a ri gbọ lọdọ wọn lọwọ yi.

Gomina Yaya Bello ati Ben Ayade

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ni bayii, ipinlẹ Kogi ati Cross River ni ipinlẹ meji ti aarun covid-19 ko tii wọ lorilẹede Naijiria.

ATUPALE BI NNKAN SE RI PELU CORONAVIRUS NI NAIJIRIA TITI DI ỌJỌ́ KEFA OSU KAARUN 2020

Iye ayẹwo ti wọn ti se - 23,835

Iye awọn to ni arun naa ti wọn fidi rẹ mulẹ- 3,912

Awọn tara wọn ya - 679.

Awọn to gba tọwọ rẹ ku - 117

Ipinlẹ Iye awọn to laarun covid-19Awọn to wa nibudo iyasọtọ Awọn to ti gbadun Awọn to ti ku

Lagos 1,667 1,186 448 33

Abuja FCT 336 292 40 4

Kano 547 509 20 18

Gombe 110 100 10 0

Borno 142 128 0 14

Ogun 113 81 28 4

Katsina 137 120 9 8

Edo 67 51 12 4

Osun 38 4 30 4

Kaduna 95 79 14 2

Bauchi 117 110 6 1

Sokoto 93 80 4 9

Oyo 59 43 14 2

Akwa Ibom 17 5 10 2

Kwara 24 15 9 0

Ekiti 12 7 4 1

Ondo 15 9 6 0

Taraba 15 15 0 0

Delta 17 11 3 3

Rivers 21 15 4 2

Jigawa 83 82 0 1

Benue 2 2 0 0

Anambra 1 0 1 0

Zamfara 65 62 0 3

Abia 2 1 1 0

Enugu 10 8 2 0

Niger 6 4 2 0

Adamawa 15 15 0 0

Plateau 15 14 1 0

Imo 3 2 1 0

Bayelsa 5 5 0 0

Ebonyi 7 7 0 0

Kebbi 18 18 0 0

Nasarawa 25 24 0 1

Yobe 13 12 0 1

Bi Coronavirus se n tan kiri Naijiria ti awọn orileede agbaye miranon mii si n ka iye awọn to gba tọwọ rẹ ku to fi mọ awọn miran to n ko lojumọ,ipinlẹ meji kan ni Naijiria wa ti ko ti d'ọdọ wọn.

•Ipinlẹ Cross Rivers

•Ipinlẹ Kogi

Lati igba ti Covid-19 ti bẹrẹ ni Naijria awọn ipinlẹ mejeeji wọn yi gbe awọn igbesẹ kan lati ma se jẹ ki o wọ ọdọ wọn ti wọn si ti n gbaradi de bi o ba fi le wọ ọdọ wọn.

Ijọba Cross River goment lawọn ti mura de tawọn si ti se ibomu to pọ pẹlu pe wọn pọn dandan lilo rẹ fara ilu.

Gomina ipinlẹ Kogi,Yahaya Bello sọ pe awọn ti se appu kan eleyi ti oo jẹ ki awọn mọ apẹrẹ arun naa.