Buhari's 2nd term achievements: Ẹ wo díẹ̀ lára àṣeyọrí tí ìṣèjọba Ààrẹ̀ Buhari sọ pé òun ti ṣe láàrin ọdún márùn-ún

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Oni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un ni Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣe ajọyọ ọdun kan saa rẹ keji ti wọn dibo yan si ipo.

Botilẹjẹ pe orilẹ-ede Naijiria koju awọn ipenija l'oriṣiriṣi, iṣejọba Buhari sọ pe oun ti ṣe aṣeyọri ni awọn ẹka kan.

Ṣugbọn o, awọn eeyan kan, paapa ẹgbẹ alatako sọ pe ko si iyatọ ninu saa rẹ akọkọ ati ikeji.

Eyi lo mu wa ṣe akojọpọ diẹ lara awọn aṣeyọri ti ijọba Muhaamadu Buhari sọ pe oun ti ṣe.

Iṣẹ Agbẹ

Ijọba Buhari sọ pe owo to le ni igba biliọnu Naira l'oun ti fi ran awọn agbẹ lọwọ, iyẹn awọn to n gbin irẹsi, wheat, agbado, owu, ẹgẹ, ẹwa Soya, ẹpa, ati ọsin nkan abiyẹ, ati ẹja, laarin ọdun 2015 si 2020.

Awọn nkan amayedẹrun

Ijọba Buhari sọ pe oun ti ṣe iṣẹ takun-takun nipa ṣiṣe atunṣe ati idagbasoke si eto irinna, ina mọna-mọna, ati eto ilera.

  • O ti pari iṣẹ oju ọna irin mẹta ti awọn ijọba to kọja ṣe pati: oju'rin laarin ilu Abuja, Abuja si Kaduna, ati Itakpe-Ajaokuta-Warri, ti wọn bẹrẹ l'ọdun 1987, ti pari l'ọdun 2020.
  • Oju ọna irin kẹrin, to jẹ ti ilu Eko si Ibadan, bẹrẹ l'ọdun 2017, yoo si pari l'ọdun 2020.
  • O ti ya owo sọtọ fun ṣiṣe afara Niger keji, oju ọna marosẹ Eko si Ibadan, ati Abuja-Kaduna-Zaria-Kano.
  • Bakan naa ni ijọba sọ pe oun ti ko miliọnu mọkanla Dọla si idasilẹ ibudo ti wọn yoo ti ma a wo aisan jẹjẹrẹ ni ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo fasiti ilu Eko, to bẹrẹ l'ọdun 2019.
  • Iṣẹ n lọ lọwọ ni awọn ibudo ayẹwo ilera nileewosan ikọṣẹ iṣegun to wa ni Faisit Amina Kano, ati ileewosan ijọba apapọ to wa nilu Umuahia.
  • Ibudokọ ni papakọ ofurufu ilu Abuja ati Port Harcourt ti pari l'ọdun 2018.

Eto Ẹkọ

Ijọba sọ pe oun ti pin owo to ju aadọjọ biliọnu Naira fun awọn ajọ eto ẹkọ ni awọn ipinlẹ, ati ilu Abuja, laarin ọdun 2015 si asiko yii.

O ti buwọlu awọn ile ẹkọ bi i:

  • Fasiti irinna ori omi, nipinlẹ Delta State
  • Fasiti awọn ọmọ ogun, nipinlẹ Borno
  • Ileewe awọn olukọni kọọkan ni ẹkun idibo mẹfẹẹfa

Eto Aabo

  • Ijọba ti fi kun owo to fi n ra awọn nkan ijagun lati America, China, Russia, ati Pakistan.
  • Wọn ti ra ọkọ ijagun mẹtadinlogun fun ileeọẹ ologun ori ilẹ, lati gbogun ti Boko Haram.
  • Ileeṣẹ ologun oju ofurufu naa ti ra baalu ijagun tuntun mejilelogun lati ọdun 2015 ti Aarẹ Buhari ti wa ni iṣakoso.
  • Aarẹ Buhari ji ileeṣẹ to n mojuto ọrọ awọn ọlọpaa dide l'ọdun 2019, lati le maa mojuto idagbasoke ati ilana eto aabo ni Naijiria.
  • Aarẹ Buhari buwọlu gbigba ẹgbẹrun mẹwa ọlọpaa siṣẹ lọdọọdun.