Coronavirus in Nigeria: Ìjọba àpapọ̀ kéde pé káwọn òṣìṣẹ́ ìpele 12 àti 13 padà s'ẹ́nu iṣẹ́

Muhammadu Buhari ati Ọmọwe Folashade Yemi-Esan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Tolu Ogunlesi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba apapọ ti kede pe ki awọn oṣiṣẹ rẹ to wa ni ipele kejila ati ẹkẹtala pada si ẹnu iṣẹ.

Bakan naa ni ijọba kede pe ki gbogbo awọn oniṣẹ ko ṣee mani naa pada si ẹnu wọn.

Olori awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, Ọmọwe Folashade Yemi-Esan lo sọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ, ọdun 2020 yii.

Ṣaaju akoko yii, awọn oṣiṣẹ lati ipele kẹrinla soke lo ti pada sei ẹnu iṣẹ, igbesẹ naa wa ni nibamu pẹlu akitiyan ijọba lati dena itankalẹ aarun coronavirus.

Ọjọ mẹta pere lawọn oṣiṣẹ naa ṣi fi n ṣiṣẹ laarin ọsẹ.

Ṣugbọn Yemi-Esan ti sọ pe lati igbayi lọ, awọn oṣiṣẹ yoo maa lọ sibi iṣẹ lati ọjọ Aje si ọjọ Ẹti.

Bakan naa lo ṣalaye pe aago mẹjọ lawọn oṣiṣẹ yoo maa wọṣẹ, nigba ti wọn yoo ṣiwọ laago mẹrin irọlẹ.

Igbimọ PTF to n ri si ari dena ajakalẹ aarun covid-19 lo gba ijọba nbi imọran tẹlẹ jẹki awọn oṣiṣẹ ijọba lati ipele kejila pada sẹnu iṣẹ.

June 21 ni pápákọ̀ òfurufú márùn-ún yóò di ṣíṣí padà - Ìjọba àpapọ̀

Ijoba apapọ ti kede pe, papakọ ofurufu marun-un pere ni oun yoo si lati bẹrẹ iṣẹ pada ni ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹfa ọdun 2020.

Awọn papakọ ofurufu maraarun ti yoo bẹrẹ iṣẹ ni ti Murtala Muhammed nilu Eko, Nnamdi Azikiwe tilu Abuja, Malam Aminu Kano tilu Kano, Omagwa tilu Portharcourt ati Sam Mbakwe tilu Owerri.

Atẹjade kan ti oludari agba fun Ileesẹ to n ṣe akoso eto irinna ofurufu nilẹ wa, ọgagun Musa Nuhu fọwọsi tun salaye pe awọn papakọ ofurufu yoku labẹle yoo si wa ni titipa nigba ti awọn baalu ilẹ okeere naa ko ni raye ba sawọn papakọ ofurufu wa.

Nuhu fikun pe, lẹyin ọpọ agbeyẹwo ati aato, diẹ diẹ ni ìjọba yoo si awọn papakọ ofurufu yoku labẹle pada.

papakọ ofurufu MMA nilu Eko

Oríṣun àwòrán, others

Bẹẹ ba gbagbe, oṣu kẹta ọdun 2020 ni aarẹ Muhammad Buhari pasẹ pe, ki wọn ti awọn papakọ ofurufu ilẹ wa pa, eyi to wa gẹgẹ bii ara ọna lati dẹkun ọwọja itankalẹ arun Coronavirus ni Naijiria.

Airport reopening in Nigeria: Àwọn ìlànà fún ìrìnàjò bàálù tí pápákọ̀ òfurufú bá sí padà ní Nàìjíríà

Papakọ ofurufu ilu Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n mojuto igboke-gbodo ọkọ ofurufu ni Naijiria, NCAA, ti gbe ilana ti awọn arinrinajo gbọdọ maa tẹle ti wọn ba ṣi awọn papakọ ofurufu pada

Ajọ NCAA sọ pe nibi ti nkan de duro bayii, awọn oṣiṣẹ inu baalu gbọdọ maa wọ aṣọ idaabo bo ara lọwọ aarun, lasiko ti wọn ba wa ninu baalu.

Ninu atẹjade kan ti Oludari Agba fun ajọ naa, Captain Musa Nuhu fi ọwọ si, NCAA sọ pe dandan ni fun awọn baalu to ba wọ Naijria lati ilẹ okeere, lati pa gbogbo ilana aabo, idena ati amojuto aarun mọ.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ni ijọba Naijria da eto irinna oju ofurufu duro fun awọn baalu ilẹ okeere, nitori itankalẹ aarun coronavirus.

Lara oun ti ajọ NCCA tun sọ ni pe oun ko ni fi awọn oṣiṣẹ inu baalu si iyasọtọ , ṣugbọn wọn gbọdọ maa ṣe ayẹwo Covid-19 ni ọjọ mẹrinla-mẹrinla.

Awọn ileeṣẹ baalu si ni yoo san owo ayẹwo naa fun awọn oṣiṣẹ rẹ. Eyikeyi oṣiṣẹ to ba ni i yoo si gba itọju.

Awọn nkan miran to tun wa ninu ilana tuntun naa

  • Ajọ NCAA sọ pe awọn ileeṣẹ baalu to n ko eero lati Naijiria lọ si orilẹ-ede miran gbọdọ tẹle awọn ilana yii:
  • Wọn gbọdọ da awsn oṣiṣẹ wọn l'ẹkọọ nipa aarun, idena rẹ, ati amojuto rẹ
  • Wọn gbọdọ ri i daju pe wọn ra aṣọ idaabo bo ara ẹni lọwọ aarun, sanitaisa, ki baalu o to gbera.
  • Awọn oṣiṣẹ baalu gbọdọ wọ awọn aṣọ naa, ki wsn o si tẹle ilana titakete sira ẹni.
  • Awọn oṣiṣẹ inu baalu gbọdọ ri i daju pe awọn eero fi sanitaisa pa ọwọ wọn ti wọn ba fẹ ẹ sọkalẹ ninu baalu.
  • Wọn gbọdọ fi akọle ti yoo rọ awọn eero lati fọ ọwọ wọn si ile igbọnsẹ ati ile- iwẹ
  • Ounjẹ ti wọn ti di soju kan naa ṣaaju ki baalu o to gbera ni awọn oṣiṣẹ inu baalu gbọdọ pin
  • To ba ṣe e ṣe, ki awọn oṣiṣẹ inu baalu o ya ile igbọnsẹ kan sọrọ fun ara wọn.
  • Oṣiṣẹ inu baalu gbọdọ pọ si, lati le mu ki o rọrun lati gba iṣẹ lọwọ aara wọn. Eyi ko ni fi aaye silẹ fun oṣiṣẹ kankan lati kuro ninu baalu to ba ya loju ọna.

Ṣaaju ni agbẹnusọ fun ajọ ṣe akoso awọn papakọ ofurufu ni Naijiria, Henrietta Yakubu sọ fun BBC pe awọn arinrinajo gbọdọ maa de papakọ ọkọ ofurufu o keretan, wakati mẹta ṣaaju asiko ti baalu wọn yoo gbera.

Ajọ naa sọ pe oun n ṣiṣẹ kara-kara lati ṣe eto ti yoo daabo bo awọn arinrinajo, ti papakọ ofurufu ba ṣi pada.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ajọ FAAN ti kọkọ kede pe hun ti fin oogun apakokoro si awọn papakọ ọkọ ofurufu, ṣaaju ki wọn o to o ṣi wọn pada.

Bakan naa lo sọ pe awọn tun ti bẹrẹ si ni fi ami si ilẹ'lẹ papakọ ọkọ ofurufu, lati ṣaami aaye ti eero kọọkan yoo duro si lori ila.