Oyo state: Rauf Adeniyan, igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní àwọn ọ̀tá ìdàgbàsókè ló ń gbé ìròyìn ààwọ̀ láàrín òun àti gómìnà Makinde

Igbakeji gomina, Rauf Adeniyan lu gomina Seyi Makinde n rin musẹ

Oríṣun àwòrán, Rauf adeniyan

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Oloye Rẹmi Ọlaniyan ti sọ pe ko si idi ija kankan laarin oun ati gomina Seyi Makinde gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n sọ kiri.

Lawọn ọsẹ diẹ sẹyin ni iroyin jade si igboro pe nnkan ko dan mọran laarin gomina Ṣeyi Makinde ati igbakeji rẹ, Oloye Rẹmi Ọlaniyan. Iroyin yii ko fẹrẹ ṣe ọpọlọpọ eeyan ni kayeefi nitori awọn iroyin ati iriri awọn irufẹ edeaiyede bẹẹ to ti waye laarin awsn gomina tabi aarẹ atawọn igbakeji wọn lorilẹede Naijiria.

Amọṣa, oloye Adeniyan ni ahess ọrọ lasan leyi ati pe, labẹ ofin Gomina Seyi Makinde ni ojuṣe ti ofin la kalẹ fun un, bẹẹni oun gẹgẹ bii igbakeji pẹlu ni ilakalẹ ojuṣe ti ofin gbe le oun lọwọ paapaa lati maa duro fun gomina gẹgẹ bi o ba ṣe paṣẹ fun oun.

O fi kun pe awọn eeyan kan ti ara n ni pẹlu idagbasoke ti iṣejọba gomina Makinde n ṣe lo n fina ahesọ iroyin wahala naa ti ko waye.

Coronavirus Cases in Africa: Gómìnà Makinde yan tíṣà rẹ̀ sí ipò òṣèlú ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Gomina Makinde pẹlu Alagba Kamorudeen Aderibigbe

Oríṣun àwòrán, others

Yoruba ni ẹyin lo n di akukọ, ibi ti agba ba si dagba de, ni ọmọde yoo ba, awọn ọmọde si lo ni ọjọ ọla.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu alagba Kamorudeen Aderibigbe, tii ṣe olukọ lọdun 1979, nile ẹkọ alakọbẹrẹ St Michael to wa ladugbo Yemetu, nilu Ibadan.

Lara awọn akẹkọọ to wa ni kilaasi baba Aderibigbe lọdun naa lọhun ni Oluwaseyi Abiodun Makinde, ẹni to di gomina ipinlẹ Oyo lonii.

Nigba to n salaye bi oun ṣe pada mọ Seyi Makinde, baba Aderibigbe ni oun ko tete da akẹkọọ oun naa mọ rara ni ọjọ ti oun kọkọ fi oju kan an.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Aderibigbe ni ọjọ pẹ ti oun ti kuro lẹnu iṣẹ olukọ, ti oun si n ṣe akọwe fun Aarẹ musulumi ilẹ Yoruba lati ọdun mọkanlelogoji sẹyin.

"Emi ni akọwe fun aarẹ Musulumi nilẹ Yoruba, Alhaji Dauda Makanjuola, ti ọpọ eeyan n pe ni D-Damak, lẹyin ti mo fẹyinti ninu iṣẹ olukọ, ibẹ si ni mo ti pade Seyi Makinde, to wa fi ara rẹ han aarẹ musulumi gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu ẹlẹsin SDP ni ọdun diẹ sẹyin."

"Mo wo iwe akọsilẹ nipa ara rẹ to mu wa, mo si ri pe ile ẹkọ St Michael ni Yemetu lo lọ lasiko ti mo jẹ olukọ nibẹ, ti mo si tete da mọ kiakia pe ara akẹkọọ ti mo ti kọ nile iwe ri ni."

Àkọlé fídíò, Ifayẹmi Elebuibon: Ọ̀pọ̀ òkú ló ń rìn káàkiri ìlú Èkó, Ìbàdàn, Òṣogbo

Aderibigbe tun sọrọ siwaju pe, Seyi Makinde tun wa lẹẹkeji lati wa fi iwe pe aarẹ musulumi si ibi waasi aawẹ to seto, oun si ni aarẹ ni ki oun tẹle lọ soju oun, inu mọto Seyi si ni oun wọ lọ sibẹ.

O salaye pe asiko yii ni Seyi wa wo oun loju, to si ni oun ni olukọ oun nile ẹkọ St Michael, ti awọn si di mọ ara awọn.

Lati igba naa ni ọpọ eeyan ti n pe Aderibigbe ni 'Tisa Seyi', to si ko ipa to jọju si aseyọri akẹkọọ rẹ naa ninu ibo gomina to gbe wọle lọdun 2019.

Ni wọn igba ti ere olukọ ko si ni ọrun mọ, lọwọ lọwọ bayii, gomina Seyi Makinde ti fi orukọ baba Kamorudeen Aderibigbe sọwọ sile asofin ipinlẹ Oyo, lati fi ontẹ lu gẹgẹ bii alaga ajọ to n ṣe akoso iṣẹ ọba.

Short presentational grey line

Coronavirus Cases in Africa: Agbaṣẹ́ṣe ti ní kí Seyi Makinde fún òun ní ₦156m lórí iṣẹ́ ọpọlọ òun to lò láì tọ́

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Olufemi Oluyide tí í ṣe Agbaṣẹ́ṣe pẹ̀lú ìjọba Ọ̀yọ́ ní, iṣẹ́ ọpọlọ òun ni ìlànà tuntun fún àkóso gáréèjì ọkọ̀ ní Ìpínlẹ̀ náà, tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ.

Agbaṣẹṣe kan pẹlu ijọba ipinlẹ Oyo, Olufemi Oniyide ti n fi apa janu lori ilana akoso tuntun lawọn gareeji ọkọ, ti ijọba ipinlẹ Oyo mu lo laipẹ yii.

Oniyide, ẹni to kede pe iṣẹ ọpọlọ oun ni ilana tuntun ọhun, ti wa wọ ijọba ipinlẹ Oyo lọ sile ẹjọ lori amulo iṣẹ ọpọlọ naa, eyi to ni wọn lo lai jẹ ki oun mọ nipa rẹ.

Lara awọn olujẹjọ ninu ẹjọ naa, to wa nile ẹjọ giga ipinlẹ naa to kalẹ silu Ibadan ni, agbẹjọro agba ati kọmisana feto idajọ nipinlẹ Oyo.

Awọn olujẹjọ yoku ni olori oṣiṣẹ ni ọọfisi gomina, Oloye Oyebisi Ilaka, kọmisana fun iṣẹ ode ati igbokegbodo ọkọ, Raphael Afonja, to fi mọ igbimọ to n pawo wọle fun ijọba ipinlẹ Oyo.Ninu ẹjọ naa, ti nọmba rẹ jẹ 1/421/2020, ti agbẹjọro fun Oniyide gbe lọ sile ẹjọ ni ọjọ kẹrinla oṣu karun ọdun 2020, lo ti n beere miliọnu lọna mẹrinlelaadọjọ naira, N156m owo itanran fun onibara rẹ.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ninu alaye to ṣe sinu iwe ipẹjọ, Oluyide ni iṣẹ ọpọlọ oun, ti oun ṣe akọsilẹ rẹ fun agbeyẹwo niwaju ijọba ipinlẹ Oyo gẹgẹ bii Agbaṣẹṣe, ni ilana akoso tuntun fawọn gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo.

Olupẹjọ naa ni lati ipasẹ ọọfisi olori oṣiṣẹ fun gomina, ni oun ti gbe akọsilẹ ilana tuntun ọhun silẹ fun ijọba ipinlẹ Oyo ni ọjọ keji, oṣu Kẹwa ọdun 2019, ti wọn si ṣe ifilọlẹ ilana naa ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu keji ọdun 2020, lai bun oun gbọ mọ. Olupẹjọ naa tun salaye siwaju pé, oun tí kọkọ kọwe saaju ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keji ọdun 2020 si gomina Seyi Makinde lori iṣẹlẹ yii, amọ titi di akoko yii, ko tii fesi pada fun oun tabi ransẹ pe oun kawọn dijọ sọrọ lori rẹ.

Ilé kọmíṣọ́nà Oyo tó kú, Kehinde Ayoola kún fọ́fọ́ fáwọn olùkẹ́dùn

Ile Oloogbe Kehinde Ayọọla ti o jẹ kọmisana fun ọrọ ayika ni ipinlẹ Ọyọ ti kun fọfọ fun awọn abanikẹdun to pejupesẹ lati ṣe idaro ẹni to papoda.Ẹbi, ara, ọrẹ, alabaṣiṣẹpọ ati awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ ko gbẹyin ninu awọn ọgọrọ eeyan to korajọpọ sile oloogbe naa.

Ile oloogbe Kehinde Ayoola

Ohun ti iroyin sọ ni wi pe aisan to jẹ mọ ọkan lo da ẹmi ẹni to ti fi igba kan jẹ adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ naa tẹlẹri legbodo.

Ọ̀rẹ́ mi ni Kẹ́hìndé Ayọ̀ọlá tó kú, olùfọkànsìn ńlá ni-Ṣeyi Makinde

Gomina Seyi makinde ti ṣe apejuwe skan lara awọn ksmiṣọna rẹ, Kẹhinde Ayọọla to jade laye ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinla oṣu karun ọdun 2020 ni Kẹhinde Ayọọla ku lẹyin aisan ranpẹ.

Gbogbo ọfiisi gomina ipinlẹ Ọyọ lo dakẹ rọrọ ti oju gbogbo si faro ni idaro iku rẹ; eleyi ti gomina ipinlẹ Ọyọ ni o jẹ ibanujẹ nla fun oun nitori pe ọrẹ ni oloogbe naa jẹ si oun.

Ile oloogbe Kehinde Ayoola

Gomina Makinde ni ọdun 2002 loun ati oloogbe Kẹhinde Ayọọla pade ti o si jẹ olootọ ati olufọkansin eeyan.

Gomina makinde nikan kọ lo daro kọmiṣọna fọrọ ayika atohun alumọni ni ipinlẹ Ọyọ naa, Ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC pẹlu ko gbẹyin.

Kehinde Ayoola to jade laye

Oríṣun àwòrán, Makinde

Ninu ọrs ibanikẹdun tirẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP ninu atẹjade kan ti wọn fi sita eyi ti agbẹnusọ rẹ, Akeem Ọlatunji fọwọsi ṣe apejuwe Ayọọla gẹgẹ bi akinkanju ọmọogun to si tun jẹ ẹlẹyinju aanu nigba aye rẹ.

Ni tirẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ṣe apejuwe iku rẹ gẹgẹ bii ajalu nla fun gbogbo olugbe ipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò, What causes coronavirus: Akeugbagold sọ àṣírí ohun ti àrùn coronavirus ń dá lárá f

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn alaga ijọba ibilẹ, ALGON ni ipinlẹ Ọyọ pẹlu sọrọ ti wọn si woye pe, loju tawọn o, oloogbe Kẹhinde Ayọọla nikan lawọn ri gẹgẹ bii ọlọpọlọ pipe ti awọn ri tọkasi ni iṣejọba gomina Seyi Makinde.

Kọmiṣọna fọrs ayika atohun alumọni ni ipinlẹ Ọyọ, Kẹhinde Ayọọla dakẹ si ileewosan aladani kan lagbegbe Iyaganku ni ilu Ibadan, gẹgẹ bi awọn iwe iroyin abẹle ṣe sọ.

Ile oloogbe Kehinde Ayoola

Titi di bi a ṣe n ko iroyin yii jọ, ko tii si ẹni lee sọ ni pato ohun to ṣokunfa iku rẹ, ṣugbọn ohun ti a gbọ ni wi pe, ohun funra rẹ lo wa ọks lọ si ileewosan naa ni ọsẹ meji sẹyin fun ayẹwo ilera rẹ ti wọn si daa duro lati sinmi. Lati igba naa wa ni a gbọ wi pe o ti wa nileewosan naa ki o to dagbere faye lọjọbọ.

line

Kehinde Ayoola: Ọ̀rọ̀ tí Kọ́míṣọ́nà fọ́rọ́ àyíká ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bá BBC News Yorùbá sọ gbẹ̀yìn kó tó jáde láyé nìyí

Àkọlé fídíò, Oro ti Ayoola ba wa sọ gbeyin
line

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé Kọmiṣọna fọrọ Ayika ati ohun alumọni ilẹ ni ipinlẹ Ọyọ, Kẹhinde Ayọọla ti jade laye.

Iroyin ti a gbọ ṣalaye pe, o ti pe ọsẹ meji bayii ti kọmiṣọna naa ti dubulẹ aisan ki o to jade laye loni.

Ki o to di kọmiṣọna, Ayọọla ni aṣofin to n ṣoju ẹkun ila orun ipinlẹ Ọyọ ni ile igbimọ asofin ipinlẹ naa laarin ọdun 1999 si ọdun 2003.

Kehinde Ayoola

Oríṣun àwòrán, Oyo Insight

Gẹgẹ bi eeyan kan to wa nijọba ṣe sọ, owurọ Ọjọbọ lo jade laye.

oun ni Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ lasiko iṣejọba Lam Adesina gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ọyọ

line

Bi a ba n wa ọna atijẹ kiri, afi kaa yara maa gbadura ki a maa pade ohun ti yoo jẹ wa o.

Bẹẹ lọrọ ri fun Ọgbẹni James Daniel, ọlọkada kan ni ilu Akurẹ to jade lọ ibi iṣẹ ọkada rẹ ṣugbọn to ba ara rẹ ni ileewosan.

Idi abajọ ni pe, awọn ọkunrin meji kan, gẹgẹ bi James Daniel ṣe sọ, ni wọn da oun duro gẹgẹ bi onibara loju popo lagbegbe Igbatoro nilu Akurẹ pe ki o gbe awọn lori ọkada rẹ de Ibafo ki o si tun gbe awọn pada.

Ọgbẹni James to ni darandaran Fulani lawọn afunrasi naa, ṣalaye pe nigba ti awsn n lọ lori ere ni awọn afunrasi mejeeji naa ys ada ti oun ti wọn ṣa oun lada yannayanna ki wsn to gbe ọkada oun sa lọ

O ṣalaye fawọn oniroyin pe n ṣe ni wọn fi oun silẹ ninu agbara ẹjẹ ni kete ti wọn rii pe oun ti daku ki oun le gba ibẹ dero ọrun.

O ni alaanu eeyan kan to n kọja lọ lo to gbe oun lọ sileewosan.

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ileewosan kan ni ilu Akurẹ ni Ọgbẹni Daniel wa to ti n gba itọju.

Ẹkunrẹrẹ ajọsọ ọrs pẹlu BBC News Yoruba lori ẹrọ ayelujara lo wa loke iroyin yii.