Coronavirus Drugs: Àjọ NAFDAC ti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò àgbò mẹ́rin tí wọ́n ṣe ní Nàìjíríà fún Covid-19

Oríṣun àwòrán, AFP/NAFDAC
Ajọ to n mojuto ipese ounjẹ ati oogun ni Naijiria, NAFDAC, sọ pe oun ti bẹrẹ iṣẹ lori oogun coronavirus mẹrin l'orilẹ-ede Naijiria.
Oludari Agba fun ajọ naa, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye lo sọ bẹ ẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe nileeṣẹ amohunmaworan ipinlẹ Oyo, BCOS lọjọ Iṣẹgun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
O ni "A fi ikede sita pe ki awọn eeyan to ba ni oogun ti wọn gbagbọ pe o le wo Covid-19 ko yọju si ajọ naa. A si ti n ṣe ayẹwo mẹẹrin lara wọn fun igbesẹ ti o kan".
Ọjọgbọn Adeyeye sọ pe oun gba ijọba ni imọran pe ki wọn o maa wulẹ ṣe ayẹwo agbo ti orilẹ-ede Madagascar ko ranṣẹ.
O ni eyi ribẹ ẹ nitori pe diẹ lara eroja ti wọn fi ṣe e wa ni orilẹ-ede Naijiria, eyi to tumọ si pe a ko fi bẹ ẹ kọbi ara si awọn nkan ti a ni ni Naijiria.
Oludari ajọ NAFDAC sọ pe o san ki ijọba o nawo lori agbo ti wọn ṣe ni Naijiria, ju ti orilẹ-ede Madagascar lọ.
Minisita kekere fun eto ilera ni Naijiria, Senetọ Olorunninbe Mamora ti sọ pe agbo aarun coronavirus ti orilẹ-ede Madagascar ko ran ṣe si Naijiria ko ba ọ̀fẹ́ de.
Àgbo Madagascar ti wà ní Nàìjíríà ṣùgbọ́n kìí ṣe ọ̀fẹ́, a ní láti sanwó-Mínísítà
Minisita naa sọ ọrọ yii lasiko ifọrọwanilẹnu kan pẹlu BBC lọjọ Iṣẹgun.
Ọsẹ to kọja ni ijọba Madagascar ko agbo naa ránṣẹ si awọn orilẹ-ede ilẹ Afrika yooku. Orilẹ-ede Guinea-Bissau ti agbo naa de si, si ni Naijiria ti lọ ọ ko ti ẹ.
Aarẹ Andry Rajoelina ti Madagascar lo kede ni ọsẹ melo kan sẹyin pe orilẹ-ede oun ti fi ewe Artemisia ati awọn ewe ibilẹ miran ṣe agbo to le wo coronavirus san.
Awọn ileesẹ iroyin kan ni Naijiria si ti sọ pe ẹgbẹrun lọna aadọsan Euro ni Madagascar fẹ ẹ gba lori agbo naa lọwọ Naijiria.
Botilẹjẹ pe Mamora sọ pe oun ko le sọ iye ti Naijiria yoo san fun awọn agbo naa ni pato , o sọ pe kii ṣe ọ̀fẹ́ ni Madagascar ko fun Naijiria.
Mamora sọ pe Naijiria gba awọn agbo naa lati ṣe atilẹyin fun akẹẹgbẹ rẹ nilẹ Africa to kede pe oun ti ri iwosan fun Covid-19.
Lọwọ-lọwọ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe oun ko le gba ki wọn o lo agbo naa fun ọmọ Naijiria kankan lai ṣe ayẹwo to yẹ fun agbo naa.
Àrùn Coronavirus ti mú ẹ̀mí ẹni àkọ́kọ́ lọ nílẹ̀ Madagascar

Oríṣun àwòrán, @Scara_King
Ijọba ilẹ Madagascar ti kede ẹni akọkọ ti yoo gbẹmi mi nitori arun Coronavirus lorilẹede naa.
Wọn ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ọhun, to jẹ oṣiṣẹ eto ilera ti ni aisan itọ ṣuga ati ẹjẹ riru lara tẹlẹ ki ọlọjọ to de lọjọ Abamẹta.
Ṣaaju ni Aarẹ ilẹ Madagascar, Andry Rajoelina ti kede agbo kan to ni o lagbara lati wo arun Covid-19 to n ba gbogbo aye finra, leyi ti ọpọ orilẹ-ede nilẹ adulawọ si ti ni ko fi ṣowọ si wọn.
Ọjọ kẹrindinlogun oṣu karun un ọdun 2020 ni agbo naa balẹ si orilẹede Naijiria.
Ṣugbọn ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO ti kilọ pe ki awọn eeyan ṣora fun ogun ti awọn onimọ nipa eto ilera ko ba fọwọ si.
Eeyan mẹrinlelọọdunrun lo ti lugbadi arun Coronavirus lorilẹede ọhun.
NAFDAC ti ṣetán láti ṣ'àyẹ̀wò àgbo covid-19 tì Madagascar fi ránṣẹ́ ní kíákíá!

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ NAFDAC ni awọn yoo ṣe ayẹwo agbo coronavirus ti Madagascar fi ranṣẹ si Naijiria ni kiakia.
Agbẹnusọ fun ajọ NAFDAC, Dokita Abubakar Jimoh ṣalaye pe oṣu mẹta lajọ naa maa fi n ṣe iru ayẹwo bẹẹ, ṣugbọn o ni ayẹwo agbo Madagascar ko ni pẹ rara.
Dokita Jimoh ṣalaye pe ajọ NAFDAC mọ pe awọn ọmọ Naijiria fẹ gbọ esi ayẹwo ajọ naa lori agbo ilẹ Madagascar, o ni idi niyii ti ajọ naa yoo fi ṣiṣẹ lori rẹ kiakia.
Lọjọ Satide ni agbo naa de si Naijiria, Aarẹ orilẹede Guinea Bissau lo gbe oogun naa fun Aarẹ Muhammadu Buhari nile ijọba l'Abuja.
Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Buhari ni awọn ajọ to n ri si ọrọ oogun lilo yoo ṣayẹwo lori agbo ọhun ki o to le di lilo ni Naijiria.
Orílẹ̀èdé Naijiria ti gba Àgbo Coronavirus ti ilẹ̀ Madagascar ṣe tọwọ́tẹsẹ̀!
Ijọba Naijiria ti tẹwọ gba agbo ilẹ Madagascar ti wọn ni o lagbara lati wo ajakalẹ arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Abamẹta.
Nibi ipade kan pẹlu aarẹ orilẹede Guinea Bissau to mu agbo naa wa, Umaro Sissoco Embalo, aarẹ Buhari ni oun ko ni gbe igbesẹ lati sọ agbo naa di lilo fun ọmọ Naijiria titi di igba ti awọn eleto ilera ilẹ yii yoo fọwọ si.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Buhari sọ pe "A ni awọn ilana eto ilera ti a n tẹlẹ lorilẹede yii, nitori naa, a ko ni sọ agbo naa di lilo fun awọn ọmọ Naijiria ayafi ti awọn oṣiṣẹ eto ilera wa ba ṣayẹwo rẹ, ti wọn si fọwọsi pe o dara ni ."
Ìdí táwọn apòògùn Nàìjíríà fi tako oògùn Coronavirus láti Madagascar
Ẹgbẹ awọn apoogun lorilẹede Naijiria, PSN ti ni ijọba orilẹede Niajiria ko kọ ibi ara si awọn ogun abẹle ti awọn eniyan n ṣe lati koju arun Coronavirus.
Akowe ajọ naa lorilẹede Naijiria, Dudu Emeka lo fi ero rẹ han lasiko to n sọrọ lori idi ti awọn fi tako agbo lati orilẹede Madagascar ti ijọba Naijiria sọ wi pe awọn ti fẹ gba lati koju arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Others
Dudu Emeka ni awọn ọjọgbọn ni abẹle ti ṣe awọn ogun to le e koju arun naa, amọ ijọba apapọ ko tilẹ fun wọn ni anfaani lati ṣe ayẹwọ rẹ boya ohun ti wọn le lo ni abi bẹẹ kọ.
Wọn ni eleyii ti ajọ to n sakoso oogun ati ounjẹ lorilẹede Naijria, NAFDAC n ṣe ayẹwo rẹ lọwọlọwọ jẹ oogun to n to n koju ikọ, eleyii to jẹ ọkan ninu awọn ami to ma n fihan pe eniyan ni arun Coronavirus.
O ni kii ṣe pe awọn le e dari ijọba apapọ lori rira agbo lọwọ orilẹede Madagascar, amọ awọn fẹ ki ijọba ṣe ayẹwo awọn oogun ti wọn ti ṣe abẹle naa lati koju arun Coronavirus.
Akowe ajọ naa lorilẹede Naijiria, Dudu Emeka wa fikun pe awọn ti ṣe oogun labẹle to koju aisan ẹjẹ, Sickle cell Anaemia, oogun ikọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Amọ ajọ NAFDAC ninu atẹjade wọn sọ wi pe, ileeṣẹ ẹyọkan pere lo ti gbe oogun wa labẹle fun agbẹyẹwọ bọya lootọ ni oogun naa le ṣe awotan arun Coronavirus.
Ajọ NAFDAC wa fi asiko yii kesi awọn apoogun lati ṣiṣẹ karakara lori ati wa ọna abayọ si arun Coronavirus ni Naijiria, ati wi pe awọn ṣetan lati ṣe ayẹwo awọn oogun ti wọn ba ṣe labẹle.
O ti fẹrẹ to ẹgbẹrun marun un eniyan to ti lugbadi arun Coronavirus lorilẹede Naijiria, ti eniyan mejidinlọgọjọ si ti papoda.
Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àgbo Covid-19 ti Madagascar n lò
Ọ̀pọ̀ lo tí ń bèrè àwọn èròjà tó wà nínú àgbo ti orílẹ̀-èdè Madagascar ní ó lé wo ààrùn coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹ́yìn ti orílẹ̀-èdè náà ni àwọn ti lo àgbo náà o sì ṣiṣẹ ni ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ní Africa ti pè fún, eyí ti kò yọ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà silẹ̀
Kíní àwọn èròjà tí wọ́n fi ṣe àgbo náà?
Gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀-èdè Madagascar Andry Rajoelina ṣe sọ ewé artemisia annua ti hausa n pè ni Tazargade ti yorùba sì n pé ní Ewe Egbin Zulu
Sáájú àsìkò yìí ní ní àwọn onímọ̀ ti n ṣe ìwádìí ewé náà fún àwọn èròjà ìtójú àìsàn míràn bíi àìsàn ibà, Cancer àti HIV.
Títí di àsìkò yìí, àjọ WHO ní kò sí àyẹ̀wò sáyẹ́Nsì to fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àgbo náà lé wo àarùn Covid-19

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Wo àwọn ǹkan tí a mọ̀ nípa àgbo tí orílẹ̀-èdè Madagascar ṣe fún Covid-19

Aarẹ orilẹ-ede Madagascar sọ fun awọn onimọ lati ṣe oogun ibilẹ, ko si pẹ ti wọn fi ṣe ọkan jade.
Fun ọpọlọpọ ọjọ lẹyin ti aarẹ Madagascar sọ pe oun ti ri iwosan fun Covid-19, ni ọpọ eniyan ti n gba ọrọ naa bi ẹni gba igba ọti.Aarẹ Andry Rajoelina sọ pe eweko bi i Artemisia, ti wọn fi n tọju aisan iba, ni wọn fi ṣe agbo naa.
Eweko Artemisia ni eroja gboogi to wa ninu agbo naa, pẹlu afikun awọn eweko miran to wa orilẹ-ede Madagascar. Covid-Organics si ni wọn pe orúkọ rẹ.Olori awọn oṣiṣẹ fun aarẹ naa sọ fun BBC pe lẹyin ti wọn dan agbo naa wo lara bi ogún eniyan, ni wọn to ṣe e sinu igo ti wọn si n ta a gẹgẹ bi agbo mimu.

Oríṣun àwòrán, others
Aarẹ Rajoelina sọ fun awọn ọmọ ileewe lati ma a mu agbo naa lataarọ di alẹ.
Bakan naa lo sọ pe "agbo naa n fun awọn eeyan ni iwosan laarin ọjọ meje".
Aarẹ Rajoelina sọ pe orilẹ-ede naa n sisẹ pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ lati ilẹ okeere, lati ṣọ agbo naa di abẹẹrẹ.
Fasiti John Hopkins sọ pe "titi di ọjọ kẹfa, oṣu Karùn-ún, eeyan mejidinlaadọjọ lo ni coronavirus lorilẹ-ede Madagascar, mokandinlọgọrun-un lo si ti ri iwosan. Ko si ti i si ẹnikẹni to kú.
Njẹ agbo naa dara fun ara?
Ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, ti gba awọn eeyan nimọran pe ki wọn o ma ṣe lo oogun tabi agbo ti ko ti wọn ko se ayẹwo rẹ fun itọju Covid-19.
Ajọ naa sọ lọjọ Aje to kọja pe "awọn ọmọ ilẹ Afrika lẹtọọ lati lo oogun ti iwadii nipa rẹ wa ni ibamu pẹlu awọn eeyan to ku ni agbaye".
"Koda ki iwosan o wa ni ilana ibilẹ, o ṣe koko lati fidirẹ mulẹ pe o n sisẹ ati pe ko le ṣe ijamba fun ara."
Koda, oun fúnra rẹ mu agbo naa lasiko ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ, nitori ibẹru pe boya o lewu.
Buhari pàṣẹ lílo àgbo tí orílẹ̀-èdè Madagascar ṣe fún coronavirus fún ìtọ́jú ọmọ Nàìjíríà
Madagascar herbal cure : Buhari pàṣẹ lílo àgbo Madagascar fún ìtọ́jú ọmọ Nàìjíríà tó ní covid-19

Oríṣun àwòrán, Twitter/Muhammadu Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ lilo agbo lilo agbo coronavirus lati orilẹede Madagascar ṣe itọju awọn to lugbadi aarun ni Naijiria.
Akọwe ijọba apapọ to jẹ alaga igbimọ amuṣẹya lori ati gbogun ti ajakalẹ aarun covid-19 ni Naijiria, Boss Mustapha lo fidi ọrọ naa mulẹ fawọn akọroyin niluu Abuja lọjọ Aje.
Ijọba orilẹede Madagascar ti sọ tẹlẹ pe agbo naa n dena coronavirus, bakan naa lo n wo aisan naa.
- Coronavirus: Kíni àwọn àmì tuntun tó n fihàn?
- Coronavirus: Ǹjẹ́ àwọn dókítà tó ń tọ́jú eyín ń ṣisẹ́ lásìkò pàjáwìrì? Àti àwọn ìbéèrè míràn
- Àwọn nǹkan tí obìnrin lè ṣe pẹ̀lú olólùfẹ́ oníwà ipá lásìkò ìgbélé Coronavirus yìí
- Owó ìtanràn N40,000 ni mo san nítorí pé mí ò wọ ìbòmú- Vincent
- Ǹjẹ́ òògùn vitamin C lè pa coronavirus?
- Ǹjẹ́ ewé dongoyaro lè wo aàrùn coronavirus?
Ijọba orilẹede naa ohun ti fi agbo naa to jẹ ti Naijiria ranṣẹ si Equitorial Guinea nibi yio ti wọ ilu Abuja.
Bo tilẹ jẹ pe akọwe ijọba ko sọ ọjọ kan pato ti wọn yoo ko agbo naa wọ Naijiria, o ni gbogbo eto ti to lati lọ ko agbo naa lati Equitorial Guinea.
Ọgbẹni Mustapha ni aarẹ Buhari paṣẹ pe ki awọn eleto ilera ṣe ayẹwo oogun naa finifini ki wọn to bẹrẹ si ni maa loo fawọn eeyan.
Ẹwẹ, minisita eto ilera, Dokita Ehanire Osagie ti sọ tẹlẹ pe awọn eleto ilera yoo ṣe ayẹwo agbo naa.
Awọn onimọ ijinlẹ kaakiri agbaye ṣi n ṣiṣẹ iwadii lati wa oogun tabi abẹrẹ to le wo aarun coronavirus, ṣugbọn ko ti si oogun aarun naa di akoko yii.
Lọwọ-lọwọ, aarẹ orilẹ-ede Tanzania, Guinea-Bissau, ati Comoros ti ṣeto lati ra agbo naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo tí bẹ àwọn oníṣẹ̀gùn lọ́wẹ̀ lórí ààrùn Coronavirus
Coronavirus: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo tí bẹ àwọn oníṣẹ̀gùn lọ́wẹ̀ lórí ààrùn Coronavirus
Edotimi ni NAFDAC ti ṣetan lati ṣe iforukọsilẹ fun awọn ibudo ti ipesẹ awọn ogun ibilẹ naa yoo ti maa waye.
Ijọba ipinlẹ Ọyọ ati awọn alakoso fasiti ilẹ Ibadan ti ṣe ipade pẹlu awọn oniṣegun ibilẹ to n bẹ nipinlẹ naa
ìpàdé náà dá lori ọna abayọ si aarun aifojuri, Coronavirus to n ba gbogbo agbayhe fira.
Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ lẹyin ipade ti o waye ninu ọgba fasiti ilẹ Ibadan, ọkan lara awọn oluranlọwọ fun gomina ipinlẹ Ọyọ,
Ẹniọwọ Idowu Ogedengbe ṣe alaye pe lara awọn oniṣegun ibilẹ naa ti ni itọwo awọn ogun ti wọn popọ.
O ni, "a o fẹ muu lerefe ki a bẹrẹ sini polongo awọn ogun ibilẹ naa lai ṣe ayẹwo ti o tọ pẹlu imọ sayẹnsi.
"Nigba ti awọn onimọ iṣegun oyinbo to n wo aarun, awọn oṣiṣẹ ni yara ayẹwo ati awọn akọṣẹmọṣẹ mii to n bẹ ninu ọgba fasiti ilẹ Ibadan ba ṣe agbeyẹwo awọn ọna abayọ nilana ibilẹ, a o ṣe agbekele ogun ibilẹ ti yoo ṣe anfani fun gbogbo agbaye".
Giwa fasiti ilẹ Ibadan, Ọjọgbọn Olayinka Idowu sọ wi pe ajọṣepọ laarin awọn to n bẹ lẹka eto ẹkọ, awọn oṣiṣẹ ijọba,
Awọn oniṣẹ adani ati awọn oniṣegun ibilẹ je ọna kan gboogi lati wa ojutu si aarun to n ba gbogbo aye finra.
Idowu ni ọpọlọpọ eeyan ko fi bẹẹ ni igbagbọ ninu iṣegun ibilẹ lati ọjọ pipẹ wa, pẹlu alaye wi pe iṣẹ iwadi ti awọn
Onimọ sayẹnsi yoo ṣe ni yara ayewo ni yoo mu ki o rọrun lati fi ọwọ awọn ogun ibilẹ naa sọya.
O ni, "bi a ṣe n sọrọ lọwọlọwọ, ko tii si ogun ti o le wo aarun Corona.
Mo lero wi pe awọn onimọ sayẹnsi to n bẹ laarin wa le ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oniṣegun ibilẹ lati wa ọna abayọ.
Ẹni ti o ṣoju awọn oniṣegun ibilẹ nibi ipade naa Ọgbẹni Taye Oyerinde ṣe alaye wi pe ogun ibilẹ ni ọna abayọ ti daju fun iwọsan aarun Corona.
Oyerinde ṣe akiyesi wi pe ọlaju lo ṣe okunfa ina iṣegun ibilẹ ilẹ adulawo to n jo ajorẹyin.
O ni ohun ti awọn ọmọ Naijiria nilo bayii igbesẹ kiakia lati rẹyin aarun yii, pẹlu afikun wi pe iṣegun ibilẹ ni ọna abayọ.
Adari ajọ to n mojuto ipese ogun ati ounjẹ ni ẹkun iwọorun, NAFDAC,
Mrs Preye Edotimi, ṣe alaye wi pe ajọ naa ti ṣetan lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn oniṣegun ibilẹ ti o ni ọna abayọ si aarun Corona.
Edotimi ni NAFDAC ti ṣetan lati ṣe iforukọsilẹ fun awọn ibudo ti ipesẹ awọn ogun ibilẹ naa yoo ti maa waye.
When would schools reopen in Nigeria?: Ìdí tí gbígbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tì pa nítorí àrùn COVID-19 ṣe ṣòro fún mi-Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde
Gomina Makinde ti ni wiwa ọna lati mu idọgba ba ilera ara ati ilera ọrọ aje ipinlẹ Ọyọ atawọn eeyan rẹ lo ṣokunfa bi oun ko ṣe paṣẹ konile-o-gbele ọlọjọyipo ni ipinlẹ Ọyọ latigba ti ajakalẹ arun Coronavirus ti bẹ silẹ nibẹ.
Lasiko to fi n dahun ibeere lori eto redio kan nilu Ibadan ni Gomina Makinde sọ eyi.
O ni gbogbo eeyan lo mọ pe ipinlẹ oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ Ọyọ leyi ti wọn ko si lee da gbogbo oṣiṣẹ sile fun ọjọ gbọrọ. O ni idi niyi ti wọn fi ni ki iwọn perete ninu awọn oṣiṣẹ to jẹ ipele lọgalọga o pada si ẹnu iṣẹ.
O ni bo ti wu ko ri, ijọba ni lati rii daju pe eto ọrọ aje n lọ bo ti yẹ gẹgẹ bi awọn onimọ ti ṣe fi to ijọba leti.
Gomina Makinde ni ida aadọta awọn arun coronavirus to n waye ni ipinlẹ Ọyọ ko ṣẹyin ileewosan nla UCH ni ilu Ibadan. O fi kun un pe ko si idi fun ileewosan naa lati maa gbarata pẹlu bi awọn eeyan ṣe n na ika si wọn.
Amọṣa o ni ijsba yoo joko lati wadi ọna abayọ nibẹ. O ni lootọ ni edeaiyede waye laarin oun ati dokita agba nileewosan nla UCH, ṣugbọn awọn ti pari rẹ.
Lorim ọrọ obu irẹsi to n fa awuyewuye laarin ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ijọba apapọ nipasẹ ileeṣẹ wọlewọde ilẹẹwa lọwọlọwọ, gomina ipinlẹ Ọyọ ni kokoro lo bo awọn ẹgbẹsan apo irẹsi ti wọn gbe fun wọn ati pe nigba ti ọrọ ti ri bo ṣe ri, o di dandan ko oun jabọ bi ọrọ ṣe jẹ fawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.
O fin kun un pe ọdunrun o le ọgbọn miliọnu naira (N330m) ni wọn ti ko jọ bayii gẹgẹ bi owo fun imayedẹrun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.
Corornavirus: Lọ́jọ́ Ajé làwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo láti ipele kẹtàlá padà sí ẹnu iṣẹ́

Awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n bẹ ni ipele ikẹtala soke ti wọle pada sẹnu iṣẹ lonii.
Ohun iyalẹnu ni wi pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ti ko si ni ipele ikẹtala soke ni ko lanfani lati wọle ni ẹnu iloro.
Awọn ẹṣọ aabo duro wamuwamu si ẹnu ọna ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati ṣe ayewo kaadi idanimọ gbogbo ẹni ti yoo lanfani lati ri aye wọlẹ si ofisi wọn.
Lara awọn oṣiṣẹ kekeeke ti wọn se mọ ẹnu ọna ṣe alaye fun awọn oniroyin labẹ aṣọ wi pe awọn ọga kan lo ni ki wọn maa bọ lẹnu iṣẹ ṣugbọn ọrọ ko ri bi wọn ṣe ro lẹnu ọna abawọle.

A gbiyanju lati ba awọn to n bẹ ni ipele ikẹtala soke lati mọ boya wọn ni ibẹru kan tabi omii lori ipada sẹnu iṣẹ wọn ṣugbọn wọn kọ lati ba awọn oniroyin sọrọ.

Lopin ọsẹ ti o kọja ni gomina Ṣeyi Makinde kede wi pe ki gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n bẹ ni ipele ikẹtala soke wọle pada sẹnu iṣẹ wọn lonii ọjọ aje lẹyin ti onikaluku wọn ti deju mọle fun osẹ melo kan nitori aarun Corona to n ba gbogbo aye finra lọwọlọwọ.
Mo gbé òkúta léná kí àwon ọmọ mi le rò pé oúnjẹ ni mo ń sè- Obìnrin Opó
Coronavirus updates: Mo gbé òkúta léná kí àwon ọmọ mi le rò pé oúnjẹ ni mo ń sè- Obìnrin Opó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Kisauni lórilede Kenya ni o gbe okuta léna nitori ko si ounjẹ kankan ti yoo fun wọn jẹ
Kasauni ọlọmọ mẹwàá to tun jẹ opo ni, láti igba ti igbele aarun coronavirus ti bẹrẹ ni o ti nira fun oun láti bọ àwọn ọmọ mẹjọ yìí.
O ni inú oyún oṣùmeji ni oun wa nigba ti ọkọ oun kú ni ọdun tokoja lásìkò ti àwọn ọdaran gun pa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
O ní òun ni lati gbé ǹkan kana kí àwọn ọmọ fi ọkan si pé ounjẹ n bọ, sùgbọ́n ìrètí oun ni pe, wọ́n o sùn lọ.
Aládugbọ Kisauni lo gbọ ohun ọmọ rẹ to n sunkun asùn-dákẹ lo fi bere pé ki lo ṣe ọmọ náà, igbayi ni o wa gbe isoro arabinrin yii sori ayelujara.
Ní bayii ọ̀pọ̀ awon eniyan lo ti n wa láti wa ran obinrin náà lọwọ pẹlú oniruuru ounjẹ ati nkan iranwọ.
Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè yarí, kò gba ìrẹsì tó bàjẹ́ padà lọ́wọ́ Ṣeyi Makinde
Ileeṣẹ Aṣọbode fún ẹkùn Oyo ati Osun, tí ibùjókòó rẹ wà n'ilu Ibadan, tí kọ láti gba ẹgbẹsan irẹsi ti wọn lo bajẹ padà lọ́wọ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ Oyo.

Oríṣun àwòrán, others
Nígbà tó ń báwọn akọroyin sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Kọmisana fún ètò ọgbin nipinlẹ Oyo, Jacob Ojemuyiwa ṣàlàyé pé, gbogbo ìyànjú òun láti kó àwọn irẹsi náà padà fún ileesẹ Aṣọbode lo ja si pàbó.
- Wòlíì TB Joshua, Apostle Suleman, Wòlíì Odumeje, Pásítọ̀ D.K Odukoya 'ń gun orí òkè àdúrà nítorí COVID-19'-Wò báwọn èèyàn fi wò wọ́n
- Gómìnà Ṣèyí Mákindé ṣàlàyé ìdí tí òun kò fi leè ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pa nítorí COVID-19
- Ọwọ́ tẹ̀ èèyàn 65 tó tàpá sí òfin gbéléẹ níbi ayaẹyẹ ọjọ́ ìbí
- Orúkọ Abiku ni Okunnu tí mo ń jẹ nínú eré, inú orin Barrister ni mo sì ti ri - Wale Akorede
O ni ṣáájú ni òun ti kọ ìwé sì ileesẹ Aṣọbode náà pé, àwọn fẹ́ kó ẹgbẹsan irẹsi tí kò dára, tí wọ́n fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bíi èròjà iranwọ fún igbele Covid-19 padà, àmọ́ wọn kò gba àwọn láàyè láti rí ọ̀nà wọlé sínú ileesẹ
wọn láti ja irẹsi ọhun silẹ.
Ojemuyiwa wá sọ síwájú sí pé, àwọn yóò bun àwọn akọroyin gbọ padà, nípa ìgbésẹ tó kàn, tí àwọn yóò tún gbé lórí ọ̀rọ̀ náà
Corornavirus: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti pàṣẹ ki àwọn òṣìṣẹ́ láti ipele kẹtàlá padà sí ẹnu iṣẹ́ lọ́jọ́ ajé

Oríṣun àwòrán, Others
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo Seyi makinde ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti ipele kẹtàlá sókè yóò pada ṣenu iṣẹ́ láti ọjọ́ ajé tọ n bọ, pàápàá jùlọ àwọn to bá dá ọfíìsì ni.
Gómìnà fi ọ̀rọ̀ yìí léde lóri àtẹjíṣẹ́ twitter rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìjíròrò pẹlú ìgbìmọ amúṣẹ́ṣe lóri Corornavirus ní àwọn fẹnukò lórí ìgbésẹ̀ yìí pẹlú àwọn àlàálẹ̀.
Seyi Makinde ni gbogbo ẹni ti yóò ba pada sẹnu iṣẹ́ gbọdọ maa gba ẹnú ọ̀nọ́ kan ṣoṣo ti wọ́n o ṣí sílẹ̀ láti wọ sẹkitríàtì nígba ti gbogbo ìloro to kù yóò wà ni títì pa, eyi ni la'ti dẹ́kun ìtànkalẹ̀ ààrun Corornavirus.
Gbogbo ìpàdé yóò maa wáye lóri ayélujára bakan náà ni ko ni sí ààye fún àlejò láti wọlé àfi ti o ba pọ́n dandan.
O ní ìjọba yóò ṣeto àwọn ibùdó ti àwọn ènìyàn yóò ti maa fọ ọwọ wọ́n nínú ọgbà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan yóò maa gba "hand sanitizer" àti ìbòjú-bomú.
Gbogb ilé ounjẹ láyíká, ilé iṣk ìjọba yóò sì wà ni títì pa, nítorí náà ki àwọn òṣìṣẹ́ máa gbe oúnjẹ wá láti ilé.
Gómìnà fi kú pé àwọn yóò dẹ ọwọ́ òfin kóníléógbélé díẹ̀ ti àwọ̀n ènìyàn yóò maa jáde láàrin ààgo méje alẹ́ sí aago mẹ́fà ìdájí kí àwọn àgbẹ le maa ri iṣk wọ́n ṣe.
Makinde ni àwọn ǹkan ìrànwọ ti ìjọba pèsè fún ará ìlú ti wà ni ṣẹpẹ báyìí ti wan si ti yan ìdílé ẹgbẹ̀run 'lọ́nà ààdọ́rùn sọtọ̀ láti jẹ àǹfàní ètò náà
















