coronavirus updates: TB Joshua, Apostle Suleman, Odumeje, D.K Odukoya 'ń gun orí òkè àdúrà nítorí COVID-19'-Wò báwọn èèyàn fi wò wọ́n

TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ọmọ Naijiria ṣi n sọrọ nipa awọn iranṣẹ Ọlọrun kan ti wọn ni awọn yoo gba adura ati aawẹ lati fi ṣẹgun arun Coronavirus.

Lootọ awọn onimọ nipa ajakalẹ arun ti jẹ ko di mimọ pe ṣiṣe gaaya funra ẹni ati fifọ ọwọ wa ko mọ tonitoni nikan lo lee gba wa lọwọ arun yii,

Sibẹ awọn wolii Ọlọrun kan ṣi n sọ pe awọn ni igbagbọ pe aawẹ ati adura n ṣe bẹbẹ.

Ko si aniani pe awọn wolii wọnyii ni ipa pupọ ninu ironu awọn eeyan lorilẹ-ede Naijiria ọpọ lo si maa n gba gbogbo ohun ti wọn ba n sọ gbọ lorilẹ-ede Naijiria.

Ni oṣu to kọja ni wolii kan to jẹ gbajugbaja lagbegbe ila oorun orilẹ-ede Naijiria, Chukwuemeka Odumeje to jẹ oludasilẹ ijọ Holy Ghost Intervention Minisitry kede pe oun yoo fi han arun coronavirus idi ti wọn fi n pe oun ni "opin aisan ati ailera gbogbo"

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bakan naa ni eekan wolii miran, bii, Apositeli Suleiman Johnson to jẹ adari ijọ Omega fire Ministries Worldwide n bẹ ijọba pe ko gba oun laaye lati lọ sawọn ibudo ayẹwo ati itọju awọn alaarun Coronavirus.

Aposteli Suleiman Johnson ni nitori iru awọn akoko bayii ni awọn iranṣẹ Ọlọrun gbogbo wa fun.

Koda, alamojuto agba fun ijọ Mountain of Fire and miracles Minisirties (MFM), Pasitọ Daniel Olukọya naa ko gbẹyin. Oun pẹlu ti kede adura ati awẹ ọlọjọ meje lati koju arun yii eleyi to ti da gbogbo agbaye wolẹ soju kan naa to si ti ran ọpọ lọ sọrun ọsangangan.

Amọṣa eleyii to mu kawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria o pariwo julọ ni ti olori ijọ Synagogue Church of All Nations, Wolii TB Joshua.

O gbe ẹni ati irọri lọ sori oke lọ gbadura fun arun Coronavirus lati dopin.

Ṣaaju, bi ẹ ko ba gbagbe, loṣu kẹta ọdun yii ni wolii TB Joshua ti kọkọ sọ pe arun naa yoo parii

Iyẹn lasiko ọkan lara awọn isin ijọ rẹ amọṣa ti arun yii faake kọri ti ko lọ. Iranṣẹ Ọlọrun naa ti gbe agbada adura gba orioke lọ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Wo nnkan tawọn eeyan sọ lori rẹ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Eeyan kan loju opo twitter ni ṣekarimi lawọn iranṣẹ Ọlọrun naa n ṣe kaakiri.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Kong Nonny ṣalaye loju opo twitter tirẹ pe eto foto yiya lasan ni wolii TB Joshua lọ ṣe ni tirẹ.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Wo nnkan tawọn eeyan miran n sọ.

Odumeje: Ǹkan mẹ́wàá ti o yẹ ki o mọ nípa Odumejeje

Chukwuemeka Ohanemera Odumejeje

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, Gbajúgbajà Olùṣọ́ tó ń jẹ́ 'Liquid metal'

Tí wọ́n ba ni ki awọn eniyan darukọ olusọaguntan ti o gbajugbaja ni Naijiria ni asiko yìí , ǹkan ti o ṣeeṣe ki wọ́n sọ náà ni Odumejeje.

Chukwuemeka Ohanemera ni olusọaguntan agba ni ilé ijọsin 'Mountain of Holy Ghost Intervention and Deliverance Ministry' ní ilú Onisha ipinlẹ Anambra.

Odumejeje ni ọpọ awon eniyan maa n pe, wọn si tun npee ni akọrin, ti àwọn eniyan si maa n gbọ orin rẹ jakejado orilede Naijiria. Awọn orukọ miran ti wọn tun maa n a pe ni

"Lion", "Liquid Metal", "Indaboski Pahose" ati orukọ míràn bẹẹ.

Odumejeje ati iyawo re

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àwọn nkan yìí ni ọpọ eniyan ko mọ nipa rẹ

  • Chukwuemeka Ohanemere ni orúkọ abisọ rẹ
  • O bẹrẹ lati ijọ Charismatic Movement, sugbọn ọpọ awọn ọrẹ rẹ si ma fi n ṣe yẹyẹ nigbati o ni oun fẹ da ijọ ti oun kalẹ
  • Ọpọ lo maa n rò pe ọmọ bibi ilú Anabra ni, sùgbọ́n ọmọ Orlu ni ipnlẹ Imo ni iya ati baba rẹ.
  • Ara ọtọ ni ọjọ ibi rẹ nitori pe wọn bii ni ọjọ kẹsan osu kẹsan (09/09)
  • Olulufẹ ere bọọlu ni Odumejeje bákan náà lo ni pe erongba oun ni lati di ọmọ agbabọọlu nigba to wa ni kekere.
  • O ti se ọmọ ẹkọsẹ ri lọdo baba kan to n ṣiṣẹ awọ
  • Ọmọ ọdun mọkandinlogun ni nigbati Ọlọrun ti fi han pe yoo jẹ woli ti ilu yoo mọka
  • O fi iṣẹ isowo silẹ lọdun 2000 láti fi araji sinu iṣẹ iranṣẹ.
  • Iya rẹ lo ya lowo to fi kọkọ bẹrẹ sọṣi nigba to da sọọsi silẹ
  • Odunmejeje ni ọmọ kẹta ninu mẹfa ti iya won bi, oun naa si ti bi ọmọ mẹrin lẹyin igbeyawo