Lagos Lockdown: Ìgbésẹ̀ ìjọba lórí Twitter tì mí lójú- Jimi Disu

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípìnlẹ̀ Eko tí bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fún ìgbésẹ̀ rẹ̀ bí ó ṣe gbé sorí àtẹ̀jísẹ twitter pé kí àwọn ènìyàn dìbò bóyá kí ijọba kéde ìgbélé míràn tàbí kí wọ́n ma kéde.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ìjọba ní lẹ́yìn ti àwọn dẹkùn ìgbélé fún ará ilú bí tan, o yáni lẹ́nu pé bi olúkúlùkù ṣe ń hùwà àìbìkítà si àwọn ǹkan ti ìjọba ni kí wọ́n ṣe tàbí kí wọ́n má ṣe kò dára tó, sùgbọ́n àwọ́n fẹ́ mọ ǹkan ti àrá ilú ń fẹ́ bí ọsl méji ìdẹ̀kùn igbẹ́le ṣe fẹ́ parí.
Kàkà kí àwọn ènìyàn sọ ǹkan ti wọ́n fẹ́ ki ìjọba ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ l'órí twitter ló ni kìí ṣe ibi tí àwọn ènìyàn ti ọ̀rọ̀ náà kan wà ní ìjọba gbé ọ̀rọ̀ lọ àti pé o jọ bí ẹni pé ìjọba kò mọ ìbi ti ọ̀rọ̀ kù sí mọ́.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Jimi Disu to jẹ ìlúmọ̀ọ́ká oníròyìn sàlàyé pé ìjọba to ba mọ ǹkan tó ń ṣe kò ni fi irú ọ̀rọ̀ bàntàbanta bẹ́ẹ̀ si ọwọ́ àrá ilú, ó ní ọ̀rọ̀ tó níṣe pẹ̀lú ètò ọrọ̀ ajé àti iléra ará ilú kìí ṣe ǹkan àmú ṣeré.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ó ní ìjọba ló ni ìpinu ti wọ́n fi n lọ ará ìlú, àti pé òun gẹ́gẹ́ bi ẹni kan ko fi ara mọ ìgbélé míràn nítori èyí ti wọ́n ṣe kẹyin kò so èso rere kankan.
Ìjọba kò là ṣe àyẹ̀wò ju ẹgbẹ̀rún márùn-rún lọ nínú iye mílílọ̀nù èèyàn to wà ní ìpínlẹ̀ Eko.
Disu ni ó yẹ kí ìjọba sàlàyé fún ará ilú pé àrùn yìí kìí ṣe ǹkan ti yóò lọ nísin yìí, kí wọ́n si maa tẹ̀lé ìlànà ìmọtótó tó yẹ.
O ní ǹkan ìtìjú ní láti rí irú ǹkan bẹ́ẹ̀ lórí Twitter.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ẹ̀wẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, kọmísọna ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Eko Gbenga Omotsho ní ìgbésẹ̀ yìí kìí ṣé ǹkan tó burú tàbi ti etí kò gbọ́ rí.
Kọmísọ́na sàlàyé pé, gbogbo ọ̀nà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko maa n gbà láti bá ará ilú sọ̀rọ̀, àwọn lọ́balọ́ba, àwọn asojú àgbègbè kọ̀ọ̀kàn ló wá ti ìjọba sì n bá wọ́n sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá nílò láti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ si àwọn ti kò láàfáni láti wà lórí àwọn ojú òpó ìkànsíraẹni.
Omotosho ní ǹkan ti ìjọba ń ṣe yìí kàn jẹ́ ọ̀nà láti fí gbogbo ǹkan to n lọ tó ará ilú léti ni.
O ní àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìn bọ̀ ìjọ̀ba náà ni yóò ṣe ǹkan ti yóò ṣàǹfàní fún gbogbo ènìyàn.
Wò ohun mẹ́ta tí a mọ̀ tí yóò mú ìjọba pàṣẹ kónílé-ó-gbélé lẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Èkó
Is there a lockdown extension in Lagos: Ìdí mẹ́ta tí ó fi ṣeéṣe kí ìjọba pàṣẹ kónílé-ó-gbélé lẹ́ẹ̀ejì ní ìpínlẹ̀ Èkó

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari
Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ẹgbẹrun mẹrin o le mọkandinniirinwo eeyan lo ti ni arun COVID-19 lorilẹede Naijiria, ẹgbẹrun kan o le ẹgbẹrin ati marundinlaadọta ninu awọn wọnyii lo wa lati ipinlẹ Eko.
Lati ọjọ aje ọjọ kẹrin oṣu karun ọdun 2020 ni iye awsn eeyan to n ni arun yii ni ipinlẹ Eko ati lorilẹede Naijiria ti n gbẹnu soke.
Lootọ nigba ti ijọba apapọ atawọn ijọba ipinlẹ si ipinlẹ lorilẹede Naijiria kede didẹwọ lori eto igbele, oniruuru eto ni wọn gbe kalẹ lati rii pe lasiko ti wọn dẹwọ igbele naa ajakalẹ naa ko gbẹnu soke.
Amọṣa ko jọ pe eto naa mulẹ rara.
Awọn eeyan ṣi n kaakiri laisi ibomu
Lara ofin ti ijọba ipinlẹ ati apapọ gbe kalẹ ni pe ibomu facemask di ọranyan fun gbogbo eeyan to ba fẹ jade kuro ninu ile wọn.
Amọṣa, awọn alaṣẹ igbimọ apapọ lori gbigbogun ti arun coronavirus ti ke gbajare sita pe awọn eeyan ko tẹle ofin yii.
Awọn eeyan ṣi n pejọpọ ni ipejọpọ ọlọpọ ero
Ni ọjọ akọkọ ti wsn dẹkun yii, fọfọfọ lawọn ero kun awọn banki atawọn ile itaja gbogbo kaakiri ilu Abuja ati Eko. Koda ko si ẹnikẹni to tẹle ọrọ ijinna sira ẹni lawọn ibudo ọlọpọ ero naa.
Eyi ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ni o n kọ oun lominu gidigidi.
Gomina Sanwo-Olu ṣalaye pe, o jẹ oun to ba oun ninu jẹ pe pẹlu ọpọ ilanilọyẹ, awọn ero ko dawọ kikun awọn banki atawọn ọja gbogbo lọpọ yanturu .
Awọn awakọ ero kii ye ko akokun ero
Lara awọn eto ti ijsba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lori eto irinna ni pe awọn awakọ ero to ba ṣiṣẹ gbọdọ mu ibomu lọkunkundun ati pe ida ọgọta lero ti wọn gbọdọ maa gbe.
Ni bi ṣe n sọrọ yii gomina Sanwo-Olu ni ko si titẹle aṣẹ yii latọdọ ọlọkọ ero leyi to mu ki oun tilẹ paṣẹ fawọn agbofinro lati maa fi wọn jofin.
Lagos Lockdown: Èrò àwọn èèyàn ṣọ̀tọ̀tọ̀ lẹ̀yìn tí ìjọba kéde pe ó ṣeṣe ki òfin kónílé-ó-gbélé mìí wàyé

Oríṣun àwòrán, Sanwo-olu/ Twitter
Awọn olùgbé ìpínlè Eko atawọn ọmọ Naijiria mìí ti bẹrẹ sí ń fi èròngbà wọn léde lẹyin ti ìjọba ìpínlẹ̀ náà ní o ṣeṣe ki òfin kónílé-ó-gbélé bẹrẹ lọtun tawọn èèyàn ba tẹsiwaju kikọ etí ikún sí alakalẹ ìjọba.Bi awọn kan n ṣe n sọ pé kò yẹ kó rí bẹ, láwọn mìí ní bo ṣe yẹ kó rí gán niyẹn.Otunba Olúwaṣeun Solomon ni "Mo gbagbọ pe ko tii yẹ kí wọn dẹ igbele nigba ti wọn ṣe bẹẹ, nitori awọn èèyàn kò ní tẹle ofin laisepe wọn kan an nípa fún wọn."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Ni ti @Ciefbucha, o ni "Mo kọkọ ro pe ìjọba ni ìṣòro wa nilẹ yi ni, ṣugbọn o ti hàn sí gbàgede pe awa ara ilu gan ni ìṣòro ara wa nitori a ko le tẹle ofin ti wọn là kalẹ fún ànfàní ara wa."
- Òfin lè má mọ ògùn ṣùgbọ́n èmí gbàgbọ́ pé ǹkan wà nídìí bí wọ́n ṣe pa ọmọ mi - Baba Favour
- Ìjọba yóò ṣe ìwádìí ohun tí kò jẹ́ kí ìpínlẹ̀ Kogi àti Cross River tíì ní coronavirus- Mínísítà
- Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà wọ́gilé ẹ̀wọ̀n Orji Uzor Kalu, pàṣẹ ìgbẹ́jọ́ tuntun
- Àwọn Dókítà fárígá ní ìpínlẹ̀ Ondo, wọ́n ní kí Gómìnà san owó oṣù mẹ́ta tó jẹ wọ́n!
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
Ni ṣe ni Roys Akhimie bu ẹnu àtẹ lu gomina, tó sì sọ pé ìpèsè tó yẹ kí ìjọba ṣe fún àwọn èèyàn ìlú ló jẹ oun logun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7
Orebanjo Temitope sọ pé ati joko sile kii ṣe ìṣòro, ṣugbọn àti jẹun ni wàhálà.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 8


Wo àwọn èèkàn ìlú Kano tó kú láàrín ọjọ́ mẹ́rin sí ara wọn
Deaths in Kano Today: Kí ló pa àwọn èèkàn ìlú Kano mọ́kànlá wọ̀nyí láàrín ọjọ́ mẹ́rin

Oríṣun àwòrán, AYAGI'S PROFILE
Lati nnkan bi ọjọ diẹ sẹyin bayii, ọpọ eekan ọmọ ipinlẹ Kano lo ti ba ajakalẹ iku ọwọọwọ to n waye bayi ni ipinlẹ naa lọ.
Awọn ọjọgbọn fasiti, ọmọwe ileewe giga gbogbo, awọn onimọ ẹsin islam atawọn oṣiṣẹ ni wọn ti ba ajalu yii lọ.
Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ko tii si ẹni lee sọ ni pato ohun gan to n ṣokunfa iku ọwọọwọ to n waye ni ipinlẹ Kano naa bi o tilẹ jẹ wi pe iku naa n ṣe kongẹ asiko ajakalẹ arun Coronavirus lorilẹede
Naijiria.

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- Ṣé òògùn Chloroquine lè dènà ààrùn Coronavirus bí?
- Coronavirus tún ti ṣe ọṣẹ́ lórí iṣẹ́ líla ojú ọ̀nà relùwe láti Eko sí Ibadan - Ìjọba àpapọ̀
- Àrùn Coronavirus fa'lẹ̀ya láwọn ìletò aláwọ̀dúdú ní Amẹ́ríkà

Ni ọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku, oniruuru iṣẹlẹ iku ojiji lo waye ni ipinlẹ naa ninu eyi ti awọn eekan ti a ka silẹ wọnyii pẹlu wa.
Ọjọgbọn Ibrahim Ayagi
Ni ọjọ Satide, ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2020 ni Ọjọgbọn Ayagi, jade laye. Awọn ẹbi rẹ kede pe aisan ti wọn ko lee sọ bo ṣe jẹ lo gba ẹmi lẹnu rẹni ọdun 1940 ni wọn bii ni ilu Kano to si kẹkọ gba imọ ọjọgbọn ninu imọ eto ọrọ aje.
Oun ni Oludasilẹ ileewe Hassan Ibrahim Gwarzo ni ilu Kano. Ọpọlọpọ ileeṣẹ lo ti ṣiṣẹ, koda kan ileeṣẹ iroyin BBC world service.
Ọjọgbọn Aliyu Umar Dikko (1953-2020)

Oríṣun àwòrán, dikko's family
Ọmọ ilu Kano ti a bi ni ọdun 1953 ni Ọjọgbọn Dikko.
Ni ọjọ Satide loun pẹlu jade laye lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.
Oun ni ẹni akọkọ ọmọ Ẹya Hausa ti yoo kawe gboye ọjọgbọn ninu imọ ijinlẹ nipa ẹya ara. O fi ọpọlọpọ igba ṣiṣẹ olukọ ni fasiti Bayero ni ilu Kano titi di ọjọ iku rẹ.
O fi igba kan jẹ aarẹ adari ẹka imọ iṣegun ni fasiti Maitama Sule ni ilu Kano ki o to jade laye.
Iyawo ati ọmọ meje pẹlu ọmọọmọ meje lo gbẹyin rẹ.
Ọjọgbọn Balarabe Maikaba
Ọjọgbọn Maikaba jade laye ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2020 lẹyin ti aisan iba daa wolẹ fun ọjọ diẹ, gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ ṣugbọn ni o ni aisan itọ ṣuga tẹlẹ.
Ijọba ibilẹ Fagge ni Ọjọgbọn Maikaba ti ṣẹ. O lọ sileewe alakọbẹrẹ ati girama nilu Kano ki o to lọ kẹkọ gboye ijinlẹ ni iṣẹ iroyin ni fasiti Bayero ni ilu Kano.

Oríṣun àwòrán, Maikaba facebook
O kawe ni fasiti ilu ibadan naa ki o to dori kọ iṣẹ iṣẹ olukọ imọ iroyin ni fasiti Bayero.
Ọmọ mẹrindinlogun ati iyawo mẹrin ni Ọjọgbọn naa fi silẹ saye lọ.
Ọmọwe Sabo Kurawa
Ọmọwe Sabo Kurawa naa jade laye ni ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn lẹyin aisan ọjọ pipẹ gẹgẹ bi awọn mọlẹbi rẹ ṣe sọ.
Ni ọdun 1949 ni wọn bi Ọmọwe Kurawa si kawe titi to fi gboye imọ ijinlẹ ninu imọ iṣe ati ironu ẹda, iyẹn Sociology ati Psychology

Oríṣun àwòrán, kurawa family
Igba meji ọtọọtọ lo ti di ipo igbakeji giwa fasiti Bayero mu lẹyin to bẹrẹ iṣẹ ni fasiti naa lọdun 1978.
Iyawo rẹ Ọjọgbọn Dijeh Kurawa toun pẹlu jẹ olukọ ni ẹka imọ nipa iṣiro owo ni fasiti Bayero atawọn ọmọ mẹfa lo fi silẹ saye lọ.
Ọmọwe Uba Adamu (1935-2020)

Oríṣun àwòrán, family
Olukọni ni Ọmọwe Muhammadu Uba Adamu lẹka imọ itan oṣelu ni ileeks gbogboniṣe poly ni ilu Kano ki o to fẹyiti lọdun 1995.
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ni iku muu lọ.
Awọn to sun mọọ ṣalaye pe ko fi igba kọọkan rin irinajo lẹnu lọwọlọwọ yii.
Ọmọwe Ghali Kabeer Umar
Ọga agba fasiti imọ ẹrọ Wudil Technical University to wa nipinlẹ Kano lo kede iku Ọmọwe Ghali Kabeerr Umar to wa lẹka ẹkọ imọ nipa aworan ile yiya.
Ko si alaye to kuna bi alara lori oloogbe naa.
Ustaz Dahiru Rabi'u (1948-2020)
O figba kan ri jẹ adajọ Agba ipinlẹ Kano. Onimọ nipa ẹsin Islam ni. Bi o tilẹ jẹ pe ko ni itan aarẹ kankan, awọn mọlẹbi rẹ sọ pe aisan iba lo paa.
Abdullahi Lawal

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ṣaaju iku rẹ, Abdullahi ni ọga agba ẹka ileefowopamọsi First Bank to wa ni ipinlẹ Kano.
Awọn kan n sọ ahesọ pe arun onigbameji ni awọn eeyan gbagbọ pe o ṣokunfa iku rẹ.
Awọn to sunmọ mọlẹbi rẹ ṣalaye fun BBC News pe ọjọ Satide ni wọn ti gbe edigbadigba lọ sileewosan aladani kanẸni aadọta ọdun ni Abdullahi Lawal nigba to jade laye ni ọjọ Aiku.
Musa Ahmad Tijjani
Oniroyin ni Oloogbe Musa Ahmad Tijjani to si ti fi igbakan ri jẹ olotu iwe iroyin Leadership Sunday ati Triumph ni Kano.
Ariwo iba ni wọn ni oloogbe naa pa eleyi to sọs di ero ileewosan fun ọsẹ kan gbako ki o to jade laye ni ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2020.
Sheikh Tijjani Tukur Yola

Gbajugbaja onimọ nipa ẹsin Islam ni Sheikh Tijjani to si da ileewe Tijjaniya silẹ.
Oun gan ni imaamu agba msṣalaṣi Murtal a ni ilu Kano.
Ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2020 lo jade laye.
Hajiya Halima Seth (1963-2020)

Oríṣun àwòrán, Instagram
Iyawo eekan onimọ nipa Islam, Sheikh Abdulwahab Abdullah ni Halima Shitu jẹ.
O jẹ ọkan lara awọn obinrin to nimọ ti wọn n danilẹkọ nipa Islam ni ilu Kano.
Agbegbe Yakasai ni wọn ti bii ni ọdun 1963 ki o to tẹle Sheikh Abdulwahab lọ tẹdo si Mẹdina lẹyin igbeyawo wọn.
Lasiko naa Sheikh Abdulwahab n kẹkọ nigba naa ni.
Nibẹ ni Hajiya Halima naa ti kẹkọ imọ nipa Qur'an ati Hadith
Awọn mọlẹbi rẹ ṣalaye fun BBC news pe lẹyin ọjọ mẹrin ti aisan ti daa wolẹ lo jade laye.
Ọjọ Aje lo ku to si fi ọmọ mẹfa silẹ saye lọ.
Kano Death: Àwọn Dókítà ní Kano ni irọ ni pé àwọn sá kúrò ní Kano nítorí ikú tó ń pa àwọn èèyàn
Alaga ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo ni ipinlẹ Kano ti ni ahesọ lasan ni iroyin ofege to gba igboro kan pe awọn dokita n sa kuro ni ipinlẹ Kano nitori arun to n fa iku ọwọọwọ.
Dokita Sanusi Mohammed Bala ni irọ ni iroyin yii.
Ṣaaju ni wọn ko ti le kọkọ fidi ohun to n fa ajakalẹ arun to n gbẹmi ọpọ eeyan ni Kano mulẹ.
Awọn alaisan kan tun bẹrẹ si nii sọo pe ko si awọn dokita nile iwosan mọ bii ti tẹlẹ.
Ogbeni Sani Adamu to jẹ alaisan kan ṣalaye fun akọroyin BBC pe nigba ti oun joko di aago kan lataarọ ti ko si dokita kankan to yọju si oun ni oun kuro nibẹ
Awọn ẹṣo Federal ministry of health naa tun fidiẹ mulẹ pe ko si oṣiṣẹ kankan nile iṣẹ naa.
Bẹẹ, awọn lo yẹ ki wọn ni imọ kikun lori iṣẹ awọn oṣiṣẹ eleto ilera bii dokita ati nọọsi.
Ṣugbọn dokita Bala ni irọ ni ati pe awọn dokita n ṣiṣẹ takun taklun bayii lati rii pe wọn n gbe igbese lati dẹkun itankalẹ arun coronavirus ni ipinlẹ Kano.
O ni awọn alaisan ti wọn n nio wọn ko ri dokita ko tẹlẹ igbesẹ to yẹ nile iwosan ti w'ọn lọ ki wọn to le ri dokita ni.
Iku ọwọọwọ ni Kano n kọ ọpọ lominu.
Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ni ijọba apapọ gan an lọwọ si bi wahala arun Coronavirus ṣe n gogo sii ni ipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Abdullahi Ganduje
Gomina Ganduje ni nṣe ni ikọ amuṣẹya ti ijọba apapọ gbe kalẹ lori gbigbogun ti arun Coronavirus lorilẹ-ede Naijiria, the presidential task force on covid-19 ,dẹyẹsi ipinlẹ Kano lasiko ti arun naa burẹkẹ si bayii.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC News, gomina Ganduje ni bi ọrọ ṣe n fojoojumọ buru sii ni ipinlẹ Kano
O ni ko ṣẹyin bi igbimọ amuṣẹya ti ijsba apapọ gbe kalẹ lori arun COVID-19 ṣe kuna lati mojuto ọrọ ipinlẹ Kano.
O ni oun fi ọrọ to awọn alaṣẹ ijọba apapọ titi kan igbakeji aarẹ leti pe ina wahala ajakalẹ arun Coronavirus n jo dorii koko ni ipinlẹ Kano ṣugbọn ko si ohunkohun ti ohun ri gbọ pada lori rẹ.
O ni iyalẹnu nla lo jẹ pewọn ni lati ti ibudo ayẹwo kan ṣoṣo to wa ni ipinlẹ naa fun ayẹwo arun Coronavirus fun ọjọ mẹfa gbako.
Amọṣa, igbimọ amuṣẹya lori gbigbogun ti arun coronavirus lorilẹ-ede Najiria, the presidential task force on covid-19 ni ko sohun to jọọ.
Ati pe akọṣẹmọṣẹ mẹtadinlogun ni wọn fi ranṣẹ si ipinlẹ Kano lati ṣe iranwọ lori gbigbogun ti itankalẹ arun naa.
Kano deaths: Èèyàn méjì míràn kú nítorí àrùn Coronavirus ní Kano

Oríṣun àwòrán, Dr. Ganduje OFR
Eeyan meji mii tun ti jade laye ni ipinlẹ Kano latari ajakalẹ arun Coronavirus.
Ileeṣẹ eto ilera nijọba ipinlẹ Kano lo kede eyi ni ọsan ọjọ Aje.
Gẹgẹbi ileeṣẹ eto ilera ṣe sọ, eeyan mẹtadinlọgọrin ni ayẹwo ti fihan pe o ni arun naa ti wọn ko si tii ni ẹnikẹni ti ara rẹ tii yaa ninu wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 9
Kano deaths: Kí ló ń fa ikú ọ̀wọọ̀wọ́ ní Kano?

Oríṣun àwòrán, kano state government
Ijọba ipinlẹ Kano ti gba lẹyin o rẹyin bayii pe lootọ ni ọpọlọpọ awọn eeyan n ku ni ipinlẹ naa.ni ọjọ Aiku ni ijọba ipinlẹ naa gbe atẹjade kan jade lori eyi.
Kọmiṣọna feto iroyin nibẹ, Muhammad Garba to fi atẹjade naa sita ṣalaye pe gomina Abdullahi Ganduje ti paṣẹ fun ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ilera nipinlẹ naa lati ṣewadii ohun gan to n ṣẹlẹ.
Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn ti n fi ẹhonu han lori ohun to n ṣẹlẹ yii paapaa ọgọrọ awọn eeyan to n ku iku ọwọọwọ nipinlẹ Kano.
Ijọba ipinlẹ Kano ni pẹlu iwadii ranpẹ ti awọn ti ṣe, ohun to n fa iku ọwọọwọ yii ni aisan iba, itọ ṣuga, ẹjẹ ruru ati yinrunyinrun ati pe kii ṣe coronavirus gẹgẹ bi awọn kan ṣe n pariwo kiri.
"A ti se gbogbo ẹnubode, titipa gbọingbọin ni ipinlẹ yii wa bayii, bẹẹ lawọn eeyan ipinlẹ wa naa n ṣe imọtoto boti tọ ati bo ṣe yẹ."

'Awọn eeyan n ku'
Eeyan mejila lo fo ṣanlẹ to ku lowurọ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2020 nikan eleyi si tun mu ki ohun tawọn eeyan nsọ lori pe boya arun coronavirus lo n ṣokunfa iku naa ga soke sii paapaa julọ pẹlu bi ko ṣe si ayẹwo ni ipinlẹ Kano fun ọjọ mẹta gbako bayii.

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- A fẹ́ lo ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tó ye àrùn Coronavirus láti fi ṣe ìwòsàn fún àwọn tó wà lórí àárẹ- UK
- Coronavirus: Kíni àwọn àmì tuntun tó n fihàn?
- Ọjoọ́ mélòó ni Coronavirus ń lò lára kí ènìyàn tó gba ìwòsàn?

Arabinrin kan, Salma Ahmed sọ ninu ohun agbasilẹ kan to fi sori ikanni Whatsapp eleyii to ti gbalegbako ni ipinlẹ naa pe awọn gbe ọmọ lọ sawọn ileewosan ko si si eyikeyi awọn ileewosan ti wọn de ni ipinlẹ naa to tẹwọn gba ọmọ naa fun itọju, ki wọn si to gbe ọms naa de ileewosan nla Aminu Kano, ọmọ naa ti ku.
Diẹ lara awọn eeyan to baa ileeṣẹ BBC News sọrọ nipa awọn mọlẹbi wọn to ku ṣalaye pe itọ ṣuga tabi aisan ọkan lo ja okun ẹmi wọn.
Ajọ ilera agbaye ti ṣekilọ ṣaaju asiko yii pe awọn to ba ni aisan kan lagọ ara ti wọn n wo wa ninu ewu gidigidi pẹlu arun Coronavirus yii-eyi tums si peo rọrun fun iku lati mu wọn nipasẹ arun COVID-19 yii
21k USD: Ọlọ́pàá ké sí bàbá tó na ọmọ rẹ̀ tó kùnà nínú ìdánwò, láti wá sọ ìdí tó fi tẹ ẹ̀tọ́ ọmọ náà lójú mọ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, others
Ọkùnrin kan, George Bester, lo tí faraya lórí bí ọmọkùnrin rẹ ṣe fi idi rẹmi nínú esi idanwo tó ṣe nile ẹ̀kọ́.
Bester, tíì ṣe ọga agba fún ileesẹ ibaraenisọrọ MTN ni ẹkun àríwá orílẹ̀ èdè Zambia, lo ń pariwo pe ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànlélógún dọla ($21,000), tíì ṣe mílíọ̀nù mẹ́jọ náírà (N8m) ni oun san bíi owó ilé ẹ̀kọ́ ọmọ náà àmọ́ tó lọ gba
odo wale.
Ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó wà ní orílẹ̀ èdè Zambia sì ni ọmọ náà ń lọ.

Oríṣun àwòrán, others
Fídíò bí Bester ṣe ń fà ìbínú yọ lórí ijakulẹ ọmọ rẹ ọhun, sì lo gba ojú òpó ìkan síra ẹni Twitter kan ni àárọ̀ Ọjọ́bọ, nibiti ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń sọ èrò wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 10
Ọkùnrin náà sì lo ń kó igbaju bo ọmọkùnrin rẹ tó kùnà nínú idanwo náà, ó ní kó naani owo ribiribi tí òun na lè lórí nílé ìwé.
Nínú esi idanwo ọmọdékùnrin náà lo tí jókòó ṣe idanwo fún isẹ mẹ́jọ àmọ́ to kùnà nínú isẹ mẹ́fà, tó sì yege pupọ nínú idanwo imọ nípa orin taa mọ si Music, bẹ́ẹ̀ lo tún yege díẹ̀ nínú idanwo Georgeraphy

Oríṣun àwòrán, others
Nínú fídíò náà sì ni ìyá ọmọ ọhun tí ń pariwo pé kí bàbà rẹ má gba ni igbaju mọ.Ní báyìí, Iroyin kan ni ẹka ileesẹ ọlọ́pàá tó wà fún ààbò àwọn ọmọdé ni orílẹ̀ èdè Zambia tí ransẹ pé George Bester láti wá sọ ìdí tó fi tẹ́ ẹtọ ọmọ rẹ mọ́lẹ̀.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 11
Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn tó dá sí ọ̀rọ̀ yìí lójú òpó Twitter lo ń kan saara si bàbá náà lórí bo se n bá ọmọ rẹ wí.
Lock down: Ṣé Irọ ni pé àwọn adigunjalà ń ṣọṣẹ ní ìpínlẹ Eko àti Ogun?

Lati opin ọsẹ to kọja to jẹ ayajọ isami ọdun ajinde Kristi ni iroyin kan gba oju opo ayelujara kan pe awọn adugunjale ti ya si igboro.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ wi pe awọn oni jagidijagan yii n ṣe ohun gbogbo ti wọn le ṣe lati jẹ ki awọn araalu gbagbọ ninu ọrọ ti wọn sọ.
Awọn araalu bẹrẹ si ni jo taya ọkọ ti wọn ni awọn agbegbe to wa ni ẹnu ibode ipinlẹ Eko ati Ogun, ti wọn si da awọn ẹgbẹ vigilante keekeeke silẹ lati le da aabo bo ara wọn ti awọn adigunjale ba de.
Fun ọpọlọpọ ọjọ, awọn ọdọ wọn yii, kekere ati agba pẹlu ọkunrin ko sun lalẹ
Ada ati ọkọ ni wọn mu dani ti wọn n kaakiri opopona adugbo wọn lati duro de awọn ole ti ko wa si agbeegbe wọn.
Iroyin ofege ti wọn gbo ni pe awọn ọdọ ti wọn to igba n kaakiri lati ja awọn eniyan lo le.

Oríṣun àwòrán, others
Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa sọ fun ileeṣẹ iroyin BBC ni ko si otitọ kankan ninu iroyin pe awọn adigunjale n ṣọṣẹ kaakiri,
Iroyin ofege to n kaakiri lori ẹrọ ayelujara lo jẹ ki awọn eniyan gbagbọ ninu iroyin ti kii se otitọ naa.

Ọjọ Aje, ọsẹ yii ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari kede pe wọn yoo fi ọsẹ meji kun ofin konile-o-gbele lati koju arun Coronavirus to n tan kalẹ lorilẹ-ede Naijiria.
Bawo ni iroyin pe awọn adigunjale n ja kaakiri ṣe bẹṛẹ?
Aworan ati fidio lo kọkọ jade lori ẹrọ ayelujara nibi ti wọn ti fi lede pẹlu #OgunUnrest ati #LagosUnrest lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter, amọ ko si agbegbe kankan ti iru rẹ ti ṣẹlẹ.
Awọn ara agbegbe Agbado, Sango ati Ijoko to wa ni ibode ipinlẹ Ogun ati Eko n sọ lori ẹrọ ayelujara pe awọn n gburo ibọn, ti awọn eniyan si n kọlu awọn eniyan ni inu ile.
Bakan naa ni Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ fun ileeṣẹ BBC pe awọn gba ipe to le ni igba lati ọdọ awọn araalu pe o le n ja, ti ko si si otitọ kankan ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, others
Se lootọ ni idigunjale n waye?
Agbẹnusọ fun Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Bala Elkana sọ wi pe ko si idigunjale ni ipinlẹ Eko ati Ogun bi awọn eniyan se n polongo rẹ.
Elkana fikun un pe lootọ ni awọn ti fi panpẹ ọba mu awọn eniyan ọgọrun un ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n ja laarin ara wọn.
O tun ṣalaye pe awọn ẹgbẹ okunkun yii lo n fi atẹjise yii sita lati fi da ipaya si ara awọn eniyan.
Ọpọlọpọ igba ni awọn ẹgbẹ okunkun ti ma n ja laarin ara wọn,
Ohun ti o si mu ki awọn eniyan bẹru wọn ni wi pe wọn ma n lo ọna abalaye lati mulẹ ati lati ṣe ohun ti ko tọ laarin ara wọn.
Tikútìyè lọ̀rọ̀ Coronavirus, àdúrà lọ̀rọ̀ gbà lásìkò yìí-Ààrẹ Buhari
Coronavirus pandemic: Ààrẹ Buhari ní àdúrà làsìkò yí gbà pẹ̀lú ìfaradà láti ṣẹ́gun Coronavirus, àrùn tikútìyè tó ń da àgbáyé láàmú
Aarẹ Buhari ki awọn ọmọ Nàijiria ku afarada bi gbogbo nnkan ṣe n lọ lásìkò Coronavirus yìí

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ke sawọn ọmọ orilẹede Naijiria pe ki wọn rọju mu gbogbo inira tabi irora ti igbesẹ gbogbo ti ijọba n gbe lati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus ba n mu ba wọn.
Ninu ọrọ ikini ku ọdun ajinde to fi ṣọwọ sawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, paapaajulọ awọn ọmọlẹyin Kirisiti lọrọ naa ti jade.
Aarẹ Buhari ṣalaye pe igbayegbadun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria kii ṣe oun to ṣee dunadura le lori ṣugbọn igbesẹ aabo ati alaafia araalu ni ijọba lẹkajẹka n le.
Aarẹ Buhari ni tiku tiye lọrọ Coronavirus, gbogbo eeyan orilẹ-ede Naijiria lo si gbọdọ farada awọn igbesẹ gbogbo lati da alaafia ati abo pada sorilẹ-ede Naijiria.
O wa ke sawọn ọmọlẹyin Kirisiti lati lo anfani ajọdun ajinde Jesu Kiriisiti lati fi wolẹ adura fun orilẹ-ede Naijiria ki orilẹ-ede yii lee la afonifoji to wa lọwọ yii kọja.
Bakan naa ni aarẹ ṣalaye pe ijọba ko ni tori ajakalẹ arun naa gboju kuro lori ilakaka rẹ lati koju ija kọ awọn ikọ agbesunmọmi to n ṣigun si orilẹ-ede Naijiria.



















