Coronavirus: Báyìí ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ńlá nlá ní Nàìjíríà ṣe ń bá ìgbà coronavirus yí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nṣe ni àwọn sọọsi nlá nlá wà ní òfìfo, tí àwọn ilẹkun wọn naa si wa ni titi pa lasiko yii.
Iru nkan bayii ko dabi pe o ṣẹlẹ ri, aarun coronavirus to n ba gbogbo aaye finra lo fa a.
Ero nipa iwa Abosi ati ọtẹỌkan lara awọn gbaju-gbaja ninu iwa yii ni TB Joshua, to sọ losu keji, odun pe ẹmi ọrun ru oun soke lati sọ aṣọtẹlẹ pe coronavirus yoo ko ẹru rẹ pada sibi to ti wa nigba ti yoo ba fi di ọjọ kẹtadinlogbọn, osu Kẹta.
Eyi jẹ ọjọ diẹ saaju ki ijọba o to kede aṣẹ konile-o-gbele ni Ipinleẹ Eko, Ogun, ati olu-ilu Naijiria, Abuja.

Oríṣun àwòrán, AFP
Joshua sọ pe 'Nigba ti yoo ba fi di ipari osu yii, boya a fẹ tabi a ko fẹ ẹ, koda ko si oogun oyinbo to wu ki wọn o ṣe, bi coronavirus se wá naa ni yoo se lọ'.Ọrọ yii mu ki awọn ọmọ ijọ rẹ sa a ni atẹwọ pe baba, ọrọ lẹ sọ.Ṣugbọn nigba ti ọjọ kẹtadinlogbọn, osu Kẹta kọja ti coronavirus ko ti i ko ẹrù rẹ pada sibi to ti wá, awọn eniyan fi pasitọ naa ṣe ẹléya.Ṣugbọn o, ọrọ naa ni Pasitọ Joshua tun fi gba ara rẹ silẹ.O ni "nkan ti mo sọ ni pato lọjọ yẹn ni pe aarun yẹn maa dawọ duro nibi to ti bẹrẹ.Ṣe ẹ dẹ mọ pe o ti dawọ duro niluu Wuhan lootọ."Wọn ti fi ẹsun kan awọn pasitọ miran pe wọn n pin ayederu iroyin kiri, eyi to n di akitiyan lati kapa aarun naa lọwọ.Ijọ Christ Embassy, to jẹ ti gbaju-gbaja pasitọ, Chris Oyakhilome, lo fa awuyewuye to mi ìlú julọ.Eyi ko ṣẹyin bi Oyakhilome ṣe sọ ninu fidio kan to kari ori ayelujara pe coronavirus ni nkan ṣe pẹlu idasilẹ irinsẹ ayelujara 5G, ati wi pe ara imọ lati da ilana igbe-aye tuntun 'new world order' silẹ ni.Awọn onimọ sayẹnsi ti sọ pe irọ ni iru iroyin naa.Wọn sọ pe "ọrọ omugọ lasan ni sisọ pe ayelujara 5G ni nkan ṣe pẹlu COVID-19.
Adura Gbigba lori ayelujaraFun awọn Kristẹni kan, paapa awọn to n lọ si awọn ile ijọsin bi i Anglican ati ijọ Aguda, wọn ni isẹ to pọ lati ṣe ki awọn pasitọ igbalode ma ba a gbá wọn.

Paapa awọn to n gbá awọn Kristẹni ti ko dakan mọ."Obinrin kan, Blessing Ugonna sọ fun akọroyin BBC nilu Eko pe" asiko niyi fun awọn to maa n ta omi iyanu, ororo ati awọn nkan miran fun wa lati jẹwọ agbara wọn". Itankalẹ coronavirus ti mu ki ọpọlọpọ ninu awọn sọọsi nlanla naa ko tun eero wọn pa.Kiise pe wọn n ṣe isin adura lori ayelujara nikan, wọn tun n fun ijọba ati awọn ọmọ ijọ kọọkan ni owo.Awọn kan sọ pe wọn ṣe eyi lati da omi siwaju ki wọn o ba a le tẹ ilẹ tutu ti coronavirus ba tán nilẹ ni.


Pasitọ Enoch Adeboye - olori ijọ Irapada Kristi, to fẹ ẹ ni sọọsi ni gbogbo adugbo ni Guusu Naijiria ti fun ijọba ipinlẹ Eko ni ẹgbẹrun lọna igba ibọwọ, ẹgbẹrun mẹjọ sanitiser, ati ẹgbẹrun mẹjọ iboju.Bakan naa ni Wooli Chukwuemeka Odumeje, ti ẹnu ti kun lori ayelujara nitori fidio kan to fihan bo ṣe n jijakadi pẹlu ọmọ ijọ rẹ kan to sọ pe o ni ẹmi okunkun ninu - naa ti gba oriyin lori Twitter fun bose fun awọn ti ebi le pa lasiko igbele ọsẹ meji.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Paroparo ni awọn ojupopo da ni ọsẹ mimọ
Lai fi gbogbo nkan to n ṣẹlẹ ṣe, ongbẹ sọọsi si n gbẹ ọpọlọpọ Kristẹni - ọjọ isinmi to kọja dun wọn pupọ nitori o jẹ ayajọ ọjọ Isinmi Ọpẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Tẹle, nise ni awọn ojupopo maa n kun fọfọ nilu Eko nitori bi awọn Kristẹni se maa n se iwọde pẹlu ìmọ̀ ọpẹ lọwọ lati fi sami bi Jesu se gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù saaju ki wọn o to kan mọ agbelebu.Paroparo ni awọn ojupopo dá lọdun yìí - to si ṣe e ṣe ki wọn o tun ribẹ ni ọjọ Ajinde lopin ọsẹ yii.
Sugbọn mo se alabapade awọn obinrin mẹta ati ọkunrin kan, wọn n bọ lati ijọsin ti wọn lọ ọ ṣe nile ẹnikan.Nigba ti mo beere idi ti wọn ko fi tẹle ofin pe ki olukuluku gba adura nile rẹ, ọkan lara wọn dahun pe "Bibeli gan an sọ pe nibi ti eniyan meji tabi mẹta ba pe jọ si, oun wa pẹlu wọn. Bibeli ko sọ pe ẹnikan."
Awọn afadura jagun
Mo tun gbera, o di ijọ Mountain of Fire and Miracles Ministry, MFM to wa ni ipinlẹ Ogun.
Gbajugbaja ni ijọ yii jẹ ninu ka gba adura to ni ina ninu .

Awọn aṣọbode sọ fun mi pe ijọsin ko waye.Mo ba beere pe ṣe ati isin ori ayelujara?Ọkan lara wọn ba tun dahun pe, "bẹẹni o, isin ko waye lori ayelujara naa".Bawo wa a ni awọn eniyan ṣe wa n di odi igbagbọ mú? Mo tun beere bẹ ẹ.Lo ba ki ọwọ bọ apo , o si mu iwe pelebe kan jade pe "nkan ti wọn yoo maa ka niyi ti ofin konile o gbele yoo fi kasẹ nilẹ - ko to o kuro lọdọ mi lati fi 'isan ti geeti gbau.Iwe to fun mi jẹ alawẹ ọgọ́ta, ti wọn si pe akọle rẹ ni Ipagọ adura fun ọgbọn ọjọ.Ṣugbọn ko ni i ya mi l'ẹnu ti awọn ọmọ ijọ naa kan ba pari rẹ laarin ọjọ mẹrinla ti igbele yoo fi wa.












