Coronavirus tips: Ìdí nìyí tí ààrùn coronavirus ṣe n ṣekú pa àwọn tó pa

Yara itọju alarun coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn onimọ nípa ètò ìlera sọ pé kò rújú rárá- bí o bá ṣe ń dàgbà sì í, ni ó ṣe ní ewu fún ọ sí láti ní ààrùn Coronavirus.

Ṣùgbọ́n, àjọ elétò ìlera ní àgbáyé (WHO) ti bẹ àwọn ọmọdé láti má rí ara wọn bí ẹni tí kò lè ní aarun náà.

Dókítà Rosena Allin-khan sọ pé aarun náà kì ṣe fún àwọn àgbàlagbà nìkan, tàbí ẹni tí ó ti ní àìsàn lára tẹ́lẹ̀.

Ó sọ èyí lẹ́yìn ti ìròyìn jáde pé ọmọ ọdún méjìdínlógún kan tó ti ní àìsàn lára tẹ́lẹ̀ kú nítorí Coronavirus ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Òun sì ni ẹni tí ó kéré jùlọ ti aarun náà tí pá ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Dókítà Allin-khan so pé òun ti ṣe itoju àwọn ọ̀dọ́ tí kò ní ààrùn kankan lára tẹ́lẹ̀ ṣúgbọ́n wọ́n wà níbi tí wọn tí n du ẹ̀mí wọn.

Afikun nipa aarun Coronavirus
Coronavirus

Ki wá ní è àwọn ewu bí òjò orí bá ṣe ń gòkè sì?

O ti hàn gbangba pé àwọn arúgbó lọ fara kasa nínú aarun yìí julo.

Àwọn aṣèwádìí ni Imperial College ni London tí wá isopo to wá láàrín bí ó bá ṣe dàgbà sì àti ìdí ti oo fi dé ilé ìwòsàn tí ó bá ní aarun Coronavirus.

Ìwádìí nàá fihàn pé àwọn tó dàgbà ló wọ́pọ̀ jùlọ tí yóò dé ilé ìwòsàn nítorí wọn nílò ìtọ́jú tó péye.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Ǹjẹ́ fífi omi àti iyọ̀ yọnu leè dènà àrùn Coronavirus?

Ìwádìí fi hàn nínú àwọn tó ni, ní China àti Italy, àwọn orílẹ̀-èdè méjì tí aarun náà bá fà julọ.

Bẹ́ ẹ̀ sì ni tó bá jẹ́ ti kí a gbani wọlé sí ẹ̀ka ìtọ́jú tó lágbára jùlọ, ìdá ọgọ́rùn nínú àwọn tó kú ti lé ní ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta.

Bí ààrùn náà ṣe ń kan ọjọ́ orí.

Ní Italy, ida 0. 4% ni àwọn tó ti pe ogójì ọdún tó ti kú , tí ìdà 19% sì jẹ́ àwọn tó ti lé ní ọgọ́rin ọdún.

Nígbà tí ìdà 0.7% jẹ́ àwọn tó ti pé ogójì ọdún ti kú ní America.

Oludari ilé iṣẹ́ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn ní America, Anthony Fauci sọ pé iye ènìyàn tí coronavirus ti pa níbẹ̀ jẹ́ nkan tó n bánilọ́kàn jẹ́, tó sì jẹ́ àwọn àgbàlagbà tó ti ní àìsàn tí wọ́n ń tọ́jú tẹ́lẹ̀.

Àkọlé fídíò, Sogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Ṣùgbọ́n, ó sọ pé Coronavirus kìí se ìṣirò Maasi.

Ajo WHO náà sọ pé bótilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí wà pé àwọn tó ti pé ọgọ́ta ọdún ló ti kú ju àwọn ọmọdé lọ, àwọn ọmọdé naa le kú.

Banner

Ẹni tó ti ní àìsàn lára tẹ́lẹ̀

Àwọn àìsàn tó ti wà nínú àgọ́ ara tẹ́lẹ̀ náà wà lára nkan tó ń sọ ẹni tí yóò kù ú tàbí yè.

Fún àpẹẹrẹ, ẹni tó bá ní ààsàn bí ikọ́'fe (Asthma), bóya ọmọdé tàbí àgbàlagbà. Bákan nàá ni àwọn tó bá ní àìsàn ọlọ́jọ́ pípí lára.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí ọjọ́ orí wọn kéré le má fi àmì hàn, wọ́n le pín kiri láí mọ̀.