Coronavirus: Ó ṣe é ṣe kí o ti ní coronavirus kí ó má mọ̀ nítorí pé ó kò rí àpẹẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onimọ sayẹnsi ti sọ pe ọjọ maarun lo ṣaba maa n gba awọn eniyan lati fi apẹẹrẹ aarun coronavirus han.
Aarun Covid-19, to le fa iba, ikọ ati eemi ti ko ja geere, ti n tan kaakiri agbaye, o si ti kọlu ẹgbẹrun lọna mẹrindinlaadọfa eniyan.
Awọn onimọ iṣegun oyinbo lati ilẹ America ṣe agbeyẹwo awọn to ni aarun naa ni China, ati awọn orilẹ-ede miran lati le mọ si nipa aarun naa.
Ọpọ awọn to fi apẹẹrẹ rẹ han maa n ni laarin ọjọ maarun.
Ẹni ti ko ba fi apẹẹrẹ kankan han ti aarun naa fi lo ọjọ mejila lara a wọn, ṣi le ko ran ẹlomiran.
Awọn oluwadii gba awọn eniyan yii nimọran pe - boya wọn fi apẹẹrẹ han tabi rara - lati fi ara wọn si iyasọtọ fun ọjọ mẹrinla lati dena kiko aarun naa ran awọn miran.
Ti wọn ba tẹle awọn ilana naa - ti wọn ti n ṣamulo ni UK ati US - wọn sọ pe eniyan kan pere ninu ọgọrun eniyan ti wọn ba fi si iyasọtọ fun ọjọ mẹẹdogun, ni yoo pada ri apẹẹrẹ ti wọn ba fi silẹ.
Olori awọn oluwadi lati John Hopkins Bloomberg School of Public Health, Ọjọgbọn Justin Lessler, sọ pe ọpọlọpọ nkan lo ṣi wa lati kọ nipa aarun naa.
Iye eniyan ti yoo fi apẹẹrẹ han ko ti jẹ mi mọ - ayẹwo naa ko tfi eyi han.
Awọn onimọ gbagbọ pe ọpọ eniyan to ba ni aarun naa yoo ri apẹẹrẹ diẹ. Awọn kan ko ni i ni apẹẹrẹ kankan - wọn ni aarun naa, ṣugbọn ko ni han jade lara wọn.
Ṣugbọn, aarun naa le lagbara pupọ, to si le 'sekupa awọn kan - paapa awọn arugbo to ba ni awọn aisan kan ti wọn n tọju tẹlẹ.
Bakan naa ni onimọ miran, Ọjọgbọn Jonathan Ball, sọ pe "Ko fi bẹ ẹ si ẹri pe awọn ti ko fi apẹẹrẹ han le ko ran ẹlomiran lasiko ti apẹẹrl aarun naa ko ti i jade lara wọn".
Igbagbọ wa pe ti awọn eniyan ba fi apẹẹrẹ bi i ikọ ati iba han ni wọn le ko ran ẹlomiran.

Ọna pataki lati daabo bo ara rẹ ni:

- Yago fun ti wọn ba n ṣaisan
- Ṣọra fun fifi ọwọ kan oju, imu ati ẹnu rẹ lai fọ ọwọ
- Lo beba fẹlẹfẹlẹ tiṣu lati fi bo ẹnu rẹ ti o ba hukọ, tabi imu ti o ba sin. Lẹyin naa ki o ju u sinu ile idalẹ si, ki o si fọwọ rẹ.
- Si ri i daju pe o n fọ ọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ ni gbogbo igba.













