Chloroquine for coronavirus: Àjọ NAFDAC fọwọ́ sí pípo ògùn chloroquine fún àyẹ̀wò ìtọ́jú coronavirus ní Nàìjíríà

Chloroquine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n mojuto ṣiṣe, lilo ati tita ogun oyinbo ni Naijiria, NAFDAC, ti fun ileeṣẹ apoogun oyinbo kan ni aṣẹ lati ṣe ogun Chloroquine fun itọju coronavirus.

Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan ti ọga agba ajọ naa, Ọjọgbọn Christianah Adeyeye fi sita.

Adeyeye sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ayẹwo ti awọn onimọ iṣegun oyinbo ṣe lawọn ileewosan kan ni China, ti esi ayẹwo wọn si fihan pe Chloroquine le kapa otutu aya ti aarun Coronavirus ba fa, ti eyi si le ke ẹmi aarun naa kuru.

O sọ pe lootọ ni ajọ naa ti fi ofin de lilo chloroquine fun itọju aisan iba ni Naijiria, ṣugbọn wọn ti n ṣe agbeyẹwo rẹ pada lati fi koju aarun tuntun, coronavirus.

Àkọlé fídíò, Sogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Nafdac sọ pe wọn yoo dan ogun chloroquine naa wo lara awọn eniyan to ba ni aarun naa lati le mọ boya yoo ṣiṣẹ fun.

Adeyeye tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe awọn oluwadii ni orilẹ-ede France ati America ti gbiyanju ogun naa fun itọju coronavirus, ti wọn si sọ pe o ṣiṣẹ.

"Ipinlẹ Eko yoo bẹrẹ si ni dan chloroquine wo lati mọ bi yoo ṣe ṣiṣẹ si."

Ṣugbọn ṣa, ajọ NAFDAC gba awọn ara ilu ni imọran pe ki wọn o ma lo ogun chloroquine lai gba imọran lọwọ dokita wọn, nitori aṣilo rẹ le fa inu rirun, ki oju o ma a wo baibia, ori fifọ, ati ara yiyun.

Aṣẹ yii ko tumọ si pe wọn ti bẹrẹ si ni i lo chloroquine fun itọju coronavirus, ṣugbọn wọn ti ṣe ọpọlọpọ ogun naa pamọ lati lo, ti awọn ọpọ eeyan ba ko aarun naa.

Afikun nipa aarun Coronavirus

Nítorí Coronavirus, àjọ Olympics lágbayé kéde ọjọ́ tuntun fún ìdíje Tokyo 2020

Idije ere idaraya Tokyo Olympic games yoo bẹrẹ ni ọjọ kẹtalelogun oṣu keje ọdun 2021 bayii yoo si pari ni ọjs kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun kan naa.

Ajọ ere idaraya olympics lagbaye, IOC lo gbe ikede yii jade lẹyin ipade igbimọ iṣakoso rẹ to waye loni ọjọ Aje, ọgbọn ọjọ oṣu kẹta ọdun 2020.

Wọn sun idije agbaye naa to yẹ ko waye lọdun yii tẹlẹ siwaju nitori ajakalẹ arun Coronavirus to n da agbaye laamu lọwọlọwọ.

Orukọ idije naa ko ni yipada kuro ni Tokyo 2020 to n jẹ tẹlẹ.

Ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun yii lo yẹ ki idije paralympics to wa fawọn akanda ẹda naa bẹrẹ tẹlẹ, ohun naa yoo wa bẹrẹ ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹjọ si ọjọ karun oṣu kẹsan ọdun 2021.

Aarẹ ajọ IOC lagbaye, Thomas Bach ṣalaye pe, "Ọmọ eniyan n la afonifoji dudu kọja lọwọ bayii, idije olympics yii si lee jẹ imọlẹ ti yoo tan lẹyin okunkun biribiri naa"