Nigeria kidnap: Àwọn jàndùkú jí agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà méjì gbé lópòpónà Owo sí Benin

Dayo Ojo

Oríṣun àwòrán, Eniymba FC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn janduku ti ji agbabọọlu ọmọ Naijiria meji, Dayo Ojo ati Benjamin Iluyomade gbe.

Ojo to ti gba bọọlu ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles n rinrin ajo pẹlu Iluyomade to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Abia Comets lati ilu Akurẹ ki wọn to ko sọwọ awọn ajinigbe lọna ilu Benin.

Akẹgbẹ Ojo ti wọn jọ n gba bọọlu fun Enyimba, Emmanuel James naa wa ninu ọkọ naa ṣugbọn oun mori bọ ni tiẹ.

Ojo ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Sunshine ilu Akure fun igba pipẹ ko to darapọ mọ Enyimba lọdun 2019.

Ojo tun ṣoju Naijiria ninu idije awọn ọjẹwẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun lọdun 2010.

Laipẹ yii ni ajọ LMC so idije liigi Naijiria NPFL rọ nitori ajakalẹ arun coronavirus.

Ìbànújẹ́ ńlá ni ikú agbábọ́ọ̀lù Rangers, Ifeanyi George jẹ́ fún wa- Mínísítà àti NFF

Iku agbabọọlu ikọ Rangers International ti ilu Enugu Ifeanyi George ṣe ni laanu gan na, bayii ni minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ, Sunday Dare ṣe n kẹdun

Ifeanyi di oloogbe lẹni ọdun mẹrindinlọgbọn pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ meji, Emmanuel Ogbu ati Eteka Gabrielinu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lanaa ọjọ Aiku.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Iroyin ti a gbọ ni pe ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn wa ninu rẹ lo lọ fori sọ ọkọ nla akẹru kan nibi ti o duro si .

Lopopona Agbor ni ipinlẹ Edo ni ijamba ọkọ ọhun ti ṣẹlẹ nigba ti George ati awọn akẹgbẹ rẹ n rinrin ajo ni opopona ilu Onitsha si Eko.

Alukoro ẹgbẹ agbabọọlu Rangers ṣalaye pe awọn agbabọọlu naa rinrin ajo lọ si ilu Eko lẹyin ti idije liigi Naijiria(NPFL) ti di siso rọ ki ijamba naa to ṣẹlẹ.

Ifeanyi George

Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF

Ajọ ẹṣọ oju popo FRSC sọ pe awọn mẹtẹẹta lo ja laisi lojuna ti ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ tan.

Minisita ni o ṣeni laanu pe pe awọn mejeeji ṣagbako iku ojiji lai le jẹ ohun ti wọn fẹ jẹ laye.

Minisita gbadura si Eleduwa pe ko tu awọn ẹbi awọn agbabọọlu mejeeji ninu, o ni oun naa kẹdun awọn agbabọọlu mejeeji.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF sọ loju opo Twitter rẹ pe ibanujẹ nla ni iku awọn agbabọọlu mejeeji jẹ.

Ifeanyi George

Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF

NFF kẹdun pẹlu ẹbi awọn oloogbe naa ati ẹgbẹ agbabọọlu Rangers Intl, ajọ naa gbadura pe ki Eleduwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.